Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 29:1-35 BYB2014 - Bible AI

1Jákọ́bù sì tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìn-àjò rẹ̀, ó sì dé ilẹ̀ àwọn ará ìlà oòrùn.

2Ó sì rí kànga kan ní pápá, agbo àgùntàn mẹ́ta sì dúró láti mu omi ní ibi kànga náà, nítorí pé láti-inú kànga náà ni wọ́n ti ń fi omi fún agbo àgùntàn. Òkúta tí a gbé dí ẹnu kànga náà sì tóbi gidigidi.

3Nígbà tí gbogbo agbo ẹran bá péjọ pọ̀ sí ibẹ̀ tán ni àwọn darandaran yóò tó yí òkúta náà kúrò, tí wọn yóò sì fún àwọn ẹran náà ní omi, tí wọ́n bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, wọn yóò tún yí òkúta náà padà sí ẹnu kànga náà.

4Jákọ́bù béèrè lọ́wọ́ àwọn darandaran náà pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi níbo ni ẹ̀yin ti wá?” Àwọn náà sì dáhùn pé, “Láti Áránì ni,”

5Ó sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ Lábánì ọmọ-ọmọ Náhórì?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa mọ̀ ọ́n.”

6Jákọ́bù béèrè pé, “Ṣe àlàáfíà ni ó wà?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni. Wò ó, Rákélì ọmọ rẹ̀ ni ó ń bọ̀ yìí pẹ̀lú agbo àgùntàn.”

7Ó sì wí pé, “Kíyèsi, ilẹ̀ ò tí ì sú, kò tì í tó àkókò fún àwọn ohun ọ̀sìn láti wọ̀. Ẹ fún àwọn ẹran wọ̀nyí ní omi, kí ẹ ba à le tètè dà wọ́n padà láti jẹun.”

8Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa kì í yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga láti pọn omi fún àwọn ẹran títí gbogbo àwọn darandaran àti àwọn ẹran yóò fi péjọ tán.”

9Bí wọ́n sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Rákélì dé pẹ̀lú agbo àgùntàn baba rẹ̀, nítorí darandaran ni òun náà.

10Nígbà tí Jákọ́bù rí Rákélì ọmọbìnrin Lábánì tí í ṣe ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, pẹ̀lú àgùntàn Lábánì, Jákọ́bù súnmọ́ kànga náà, ó sì yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀, ó sì fún àwọn ẹran arákùnrin ìyá rẹ̀ Lábánì ní omi.

11Jákọ́bù sì fẹnu ko Rákélì ní ẹnu. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún.

12Jákọ́bù sì wí fún Rákélì pé ìbátan baba rẹ̀ ni òun, àti pé, òun jẹ́ ọmọ Rèbékà. Rákélì sì sáré lọ sọ fún baba rẹ̀.

13Ní keté tí Lábánì gbúròó Jákọ́bù ọmọ arábìnrin rẹ̀, ó jáde lọ pàdé Jákọ́bù, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì mú un lọ sí ilé. Nigbà náà ni Jákọ́bù ròyìn ohun gbogbo fún un.

14Lábánì sì wí pé, “Ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ ara mi ni ìwọ jẹ́.”

14Lẹ́yìn tí Jákọ́bù sì wà pẹ̀lú rẹ̀ fún odidi oṣù kan,

15Lábánì wí fún Jákọ́bù pé “Bí a tilẹ̀ jẹ́ ìbátan, kò yẹ kí o máa ṣiṣẹ́ fún mi lásán láìgba ohun kankan. Sọ ohun tì ìwọ fẹ́ gbà fún iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún mi!”

16Wàyí o, Lábánì ní ọmọbìnrin méjì, orúkọ èyí ẹgbọ́n ń jẹ́ Líà, orúkọ àbúrò sì ń jẹ́ Rákélì.

17Líà kò ní ẹwà púpọ̀, ṣùgbọ́n Rákélì ní ẹwà gidigidi. Ojú rẹ̀ sì fanimọ́ra.

18Jákọ́bù sì fẹ́ràn Rákélì, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò ṣiṣẹ́ sìn ọ fún ọdún méje, bí ìwọ yóò bá fún mi ní Rákélì ọmọ rẹ ní aya.”

19Lábánì sì dáhùn wí pé, “Ó kúkú sàn kí ń fi fún ọ, ju kí ń fi fún ẹlòmíràn lọ, nítorí wà ní ọ̀dọ̀ mi.”

20Jákọ́bù sì ṣiṣẹ́ sin Lábánì fún ọdun méje láti fẹ́ Rákélì. Àwọn ọdún wọ̀nyí sì dà bí ọjọ́ díẹ̀ lára rẹ̀, nítorí ó fẹ́ràn rẹ̀.

21Jákọ́bù sì wí fún Lábánì pé, “Mo ti parí àsìkò tí a jọ ṣe àdéhùn rẹ̀, nítorí náà fún mi ní aya mi, kí òun lè ṣe aya fún mi.”

22Lábánì sì pe gbogbo ènìyàn ibẹ̀ jọ, ó sì ṣe àṣè ìyàwó fún wọ́n.

23Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru, Lábánì mú Líà tọ Jákọ́bù lọ. Jákọ́bù sì bá a lòpọ̀.

24Lábánì sì fi Ṣílípà ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Líà gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́.

25Sì kíyèsi, nígbà ti ilẹ̀ mọ́, Jákọ́bù rí i pé Líà ni! Ó sì wí fún Lábánì pé, “Èwo ni iwọ́ ṣe sí mi yìí? Ṣe bí nítorí Rákélì ni mo ṣe ṣiṣẹ́ sìn ọ, èéṣe tí ìwọ́ tàn mi?”

26Lábánì sì dáhùn pé, “Kò bá àṣà wa mu láti fi àbúrò fún ọkọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

27Mú sùúrù parí ọ̀sẹ̀ ìgbéyàwó yìí ná, nígbà náà ni èmi yóò fi àbúrò rẹ̀ fún ọ pẹ̀lú, bí ìwọ ó bá ṣiṣẹ́ sìn mi fún ọdún méje mìíràn.”

28Jákọ́bù sì gbà láti sin Lábánì fún ọdún méje mìíràn. Lábánì sì fi Rákélì ọmọ rẹ̀ fún un bí aya.

29Lábánì sì fi Bílíhà ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Rákélì bí ìránṣẹ́.

30Jákọ́bù sì bá Rákélì náà lòpọ̀. Ó sì fẹ́ràn Rákélì ju Líà lọ, ó sì ṣiṣẹ́ sin Lábánì fún ọdún méje mìíràn.

31Nígbà tí Ọlọ́run sì ri pé, Jákọ́bù kò fẹ́ràn Líà, ó sí i ni inú ṣùgbọ́n Rákélì yàgàn.

32Líà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Rúbẹ́nì, nítorí ó wí pé, “Nítorí Ọlọ́run ti mọ ìpọ́njú mi, dájúdájú, ọkọ mi yóò fẹ́ràn mi báyìí.”

33Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Símónì, wí pé “Nítorí tí OLÚWA ti gbọ́ pé a kò fẹ́ràn mi, ó sì fi èyí fún mi pẹ̀lú.”

34Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì wí pé, “Nigbà yìí ni ọkọ mi yóò fara mọ́ mi, nítorí tí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún un,” nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní Léfì.

35Ó sì tún lóyún, ó sì tún jẹ́ pé ọmọkùnrin ni ó bí, ó sì wí pé, “Nígbà yìí ni èmi yóò yin OLÚWA” Ó sì pe orukọ rẹ̀ ní Júdà. Ó sì dáwọ́ ọmọ bíbí dúró.

>