1Nígbà tí odindi ọdún méjì sì ti kọjá, Fáráò lá àlá: ó rí ara rẹ̀ tó dúró ní etí odò Náílì.
2Nígbà náà ni màlúù méje jáde láti inú odò, wọ́n dára láti wò, wọ́n sì sanra, wọ́n sì ń jẹ koríko.
3Lẹ́yìn àwọn wọ̀nyí, ni àwọn màlúù méje mìíràn tí kò lẹ́wà tí ó sì rù jáde wá láti inú odò Náílì, wọ́n sì dúró ti àwọn méje tí ó sanra tí ó wà ní bèbè odò náà.
4Àwọn màlúù tí ó rù, tí kò sì lẹ́wà sì gbé àwọn tí ó lẹ́wà tí ó sanra jẹ. Nígbà náà ni Fáráò jí.
5Ó sì tún padà sùn, ó sì lá àlá mìíràn: ó rí siírì ọkà méje tí ó kún, ó yó'mọ, ó sì dára, ó sì jáde lára igi ọkà kan ṣoṣo.
6Lẹ́yìn wọn ni síírí ọkà méje mìíràn yọ, wọn kò yó'mọ, afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù.
7Àwọn sìírì ọkà méje tí kò yó'mọ (ọmọ rẹ̀ kò tóbi) wọ̀nyí sì gbé àwọn tí ó yó'mọ (ọmọ rẹ̀ tóbi) mì. Nígbà náà ni Fáráò jí lójú oorun, ó sì rí i pé àlá ni.
8
9Nígbà náà ni olórí agbọ́tí wí fún Fáráò pé, “Lónìí ni mo rántí àìṣedéédé mi.
10Nígbà kan tí Fáráò bínú sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì fi èmi àti olórí alásè sínú ẹ̀wọn ní ilé olórí ẹ̀sọ́.
11Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lá àlá, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀.
12Ọmọkùnrin ará Hébérù kan tí ó jẹ́ ìránṣẹ́ olórí ẹ̀sọ́ wà níbẹ̀ pẹ̀lú wa. A ṣọ́ àwọn àlá wa fún un, ó sì túmọ̀ wọn fún wa, ó sọ ìtúmọ̀ àlá ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un.
13Bí ó sì ti túmọ̀ àlá wọ̀nyí náà ni ohun gbogbo rí. A dá mi padà sí ipò mi, a sì ṣo ọkùnrin keji kọ́ sórí òpó.”
14Nítorí náà Fáráò ránṣẹ́ pe Jósẹ́fù, wọn sì mu un wá kíákíá láti inú ìhámọ́. Nígbà tí ó fá irun rẹ̀, s tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá ṣíwájú Fáráò.
15Fáráò wí fún Jósẹ́fù, “Mo lá àlá kan, kò sì sí ẹni tí o le è túmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ nípa rẹ pé bí o bá ti gbọ́ àlá, o le è túmọ̀ rẹ̀”
16Jóṣẹ́fù dáhùn pé, “kì í ṣe agbára mi, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ni yóò fún Fáráò ní ìtúmọ̀ àlá náà.”
17Nígbà náà ni Fáráò wí fún Jóṣẹ́fu pé, “Ní inú àlá mi, mo dúró ni etí bèbè odò Náílì,
18sì kíyèsí i, màlúù méje tí ó sanra tí o sì lẹ́wà jáde wá, wọ́n sì ń jẹ koríko ní tòsí ibẹ̀.
19Lẹ́yìn wọn, màlúù méje mìíràn jáde wá, wọ́n rù hángógo, wọn kò sì lẹ́wà tóbẹ́ẹ̀ tí n kò tíì rí irú màlúù tí ó ṣe àìlẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ rí ní ilẹ̀ Éjíbítì.
20Àwọn màlúù tí ó rù tí kò sì lẹ́wà sì jẹ àwọn màlúù tí ó sanra tí ó kọ́ jáde nínú odò.
21Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ́ wọ́n tan, kò sì ẹni tí ó le mọ̀ pé wọ́n jẹ ohunkóhun, nítorí wọn kò sanra sí i, wọn sì búrẹ́wà ṣíbẹ̀. Nígbà náà ni mo jí lójú oorun mi.”
22“Ní ojú àlá mi, mo tún rí ṣiiri ọkà méje tí ó yó ọmọ tí ó sì dára, wọ́n jáde láti ara igi ọkà kan.
23Lẹ́yìn wọn, àwọn méje mìíràn yọ jáde, tí kò yó ọmọ bẹ́ẹ̀ ni afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù tán.
24Àwọn siiri ọkà méje tí kò yó mọ sì gbé àwọn méje tí ó dára wọ̀nyí mì. Mo ṣọ àlá yìí fún àwọn onídán àn mi, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó le è túmọ̀ rẹ̀ fún mi.”
25Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún Fáráò, “Ìtúmọ̀ kan náà ni àwọn àlá méjèèjì ní. Ọlọ́run fi ohun tí ó fẹ́ ṣe hàn fún Fáráò.
26Àwọn màlúù méje ti ó dára jẹ́ ọdún méje, ṣiiri ọkà méje tí ó dára náà sì jẹ́ ọdún méje: ọ̀kan ṣoṣo ni wọn, àlá kan náà ni.
27Àwọn màlúù méje tí kò sanra, tí kò sì rẹwà tí ó jáde gbẹ̀yìn jẹ́ ọdún méje, bẹ́ẹ̀ náà ni siiri ọkà méje tí kò dára, tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrun ti rẹ̀ dànù tan: Wọn jẹ́ ọdún méje tí ìyàn yóò fi mú.
28“Bí mo ti wí fún Fáráò ní ìṣáájú náà ni: Ọlọ́run fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ han Fáráò.
29Ọdún méje tí oúnjẹ yóò pọ yanturu ń bọ̀ wà ní Éjíbítì.
30Ṣùgbọ́n ọdún méje mìíràn tí ìyàn yóò mú yóò tẹ̀lé e, nígbà náà ni a ó tilẹ̀ gbàgbé pé ọdún méje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà yanturu tilẹ̀ ti wà rí, ìyàn yóò sì run gbogbo ilẹ̀ náà,
31A kò ní rántí àsìkò ọ̀pọ̀ oúnjẹ yanturu náà mọ́ nítorí pé ìyàn tí yóò tẹ̀lé e yóò pọ̀ púpọ̀.
32Ìdí tí Ọlọ́run fi fi àlá náà han fún Fáráò ní ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni pé, Ọlọ́run ti pinnu pé yóò sẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ dandan, àti pé kò ni pẹ́ tí Ọlọ́run yóò fi ṣe é.
33“Ìmọ̀ràn mi ni wí pé, jẹ́ kí Fáráò wá ọlọgbọ́n ènìyàn kan ní ilẹ̀ Éjíbítì, kí ó sì fi ṣe alákòóṣo iṣẹ́ àgbẹ̀ ilẹ̀ Éjíbítì.
34Kí Fáráò sì yan àwọn alábojútó láti máa gba idá márùn-ún ìkórè oko ilẹ̀ Éjíbítì ní àsìkò ọdún méje ọ̀pọ̀.
35Kí wọn kó gbogbo oúnjẹ ilẹ̀ náà ni àwọn ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, kí wọn sì kó àwọn ọkà tí wọn jẹ sẹ́kù pamọ́ lábẹ́ aṣẹ Fáráò. Kí a kó wọn pamọ́ ni àwọn ìlú fún jíjẹ.
36Kí wọn kó oúnjẹ náà pamọ́ fún orílẹ̀ èdè yìí, kí a baà le lò ó ni ọdún méje tí ìyàn yóò fi jà ní ilẹ̀ Éjíbítì, kí ìyàn náà má ba à pa orílẹ̀ èdè yìí run.”
37Èrò náà sì dára lójú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀.
38Fáráò sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ a le rí ẹnikẹ́ni bi ọkùnrin yìí, nínú ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé?”
39Nígbà náà ni Fáráò wí fún Jósẹ́fù, “Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti fi gbogbo èyí hàn ọ, kò sí ẹni náà tí ó gbọ́n tí ó sì mọ̀ràn bí i tìrẹ ní ilẹ̀ Éjíbítì yìí,
40ìwọ yóò ṣe àkóso ààfin mi gbogbo àwọn ènìyàn gbọdọ̀ tẹríba fún àṣẹ ẹ̀ rẹ. Ìtẹ́ mi nìkan ni èmi yóò fi jù ọ́ lọ.”
41Fáráò wí fún Jósẹ́fù pé, “Mo fi ọ́ ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.”
42
43Ó sì mú un kí ó gun kẹ̀kẹ́ ẹsin bí igbàkejì ara rẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń pariwo níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà.” Báyìí ni ó sì fi ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.
44Nígbà náà ni Fáráò wí fún Jóṣẹ́fù pé, “Èmi ni Fáráò. Ṣùgbọ́n láì sí àṣẹ rẹ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun ní ilẹ̀ Éjíbítì.”
45Fáráò sì sọ Jósẹ́fù ní orúkọ yìí: Ṣefunati-Páníà èyí tí ó túmọ̀ sí, (ẹni tí ó ni agbára ikú àti ìyè ní ìkáwọ́ bí òrìṣà), Ó sì fun un ní Áṣénátì ọmọ Pótífẹ́rà, alábojútó òrìṣà Ónì, gẹ́gẹ́ bí aya. Jósẹ́fù sì rin gbogbo ilẹ̀ náà já.
46Ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni Jósẹ́fù nígbà tí ó wọ iṣẹ́ Fáráò ọba Éjíbítì. Jósẹ́fù sì jáde kúrò níwájú Fáráò, ó sì ṣe ìbẹ̀wò káàkiri gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì
47Ní ọdún méje ọ̀pọ̀, ilẹ̀ náà ṣo èso lọ́pọ̀lọpọ̀.
48Jóṣẹ́fù kó gbogbo oúnjẹ tí a pèṣè ni ilẹ̀ Éjíbítì ní ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, ó sì pa wọ́n mọ́ sí àwọn ìlú. Ní ìlú kọ̀ọ̀kan ni ó kó gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbìn ní àyíká ìlú wọn sí.
49Jósẹ́fù pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà mọ́ bí i yanrìn òkun; ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kò ṣe àkọsílẹ̀ mọ́ nítorí, ó tayọ kíkà.
50Kí ó tó di pé ọdún ìyàn dé, Áṣénátì ọmọ Pótífẹ́rà alábojútó Ónì bí ọmọkùnrin méjì fún Jósẹ́fù.
51Jósẹ́fù sọ orúkọ àkọ́bí rẹ̀ ni Mánásè, ó sì wí pé, “Nítorí tí Ọlọ́run ti mú mi gbàgbé gbogbo ìdààmú mi àti gbogbo ilé baba mi.”
52Ó sì sọ orúkọ èkejì ní Éfúráímù, ó sì wí pé, “Nítorí pé Ọlọ́run fún mi ní ọmọ ní ilẹ̀ ìpọ́njú mi”
53Ọdún méje ọ̀pọ̀ oúnjẹ sì wá sí òpin ní ilẹ̀ Éjíbítì,
54
55
56Nígbà tí ìyàn sì ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà, Jósẹ́fù sí inú àká, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọkà fún àwọn ènìyàn, nítorí ìyàn náà mú gan-an ní gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.
57Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè sì ń wá láti ra oúnjẹ lọ́wọ́ Jósẹ́fù, nítorí ìyàn náà pọ̀ gidigidi káàkiri gbogbo ayé.