Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 7:1-24 BYB2014 - Bible AI

1Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Nóà pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ, nítorí ìwọ nìkan ni mo rí bí olódodo nínú ìran yìí.

2Mú méjeméje nínú àwọn ẹran tí ó mọ́, akọ àti abo, mú méjìméjì takọ tabo nínú àwọn ẹran aláìmọ́.

3Sì mú méjeméje pẹ̀lú nínú onírúurú ẹyẹ takọ tabo ni kí o mú wọn, wọlé sínú ọkọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí á baà lè pa wọ́n mọ́ láàyè ní gbogbo ayé.

4Nítorí ní ọjọ́ méje sí ìhín, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi yóò sì pa gbogbo ohun alààyè tí mo ti dá run, kúrò lórí ilẹ̀.”

5Nóà sì ṣe ohun gbogbo tí Ọlọ́run pàṣẹ fún un.

6Nóà jẹ́ ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún nígbà tí ìkún omi dé sórí ilẹ̀.

7ⓐ Nóà àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì wọ inú ọkọ láti ṣá àsálà fún ìkún omi.

8Méjìméjì ni àwọn ẹran tí ó jẹ́ mímọ́ àti aláìmọ́, ti ẹyẹ àti ti gbogbo àwọn ẹ̀dá afàyàfà,

9akọ àti abo ni wọ́n wọlé pẹ̀lú Nóà sínú ọkọ̀ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Nóà.

10Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi sì dé sí ayé.

11ⓑ Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kéjì, tí Nóà pé ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún, ni gbogbo ìṣun ibú ya, fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì sí sílẹ̀.

12Òjò àrọ̀ìrọ̀dá sì rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.

13Ní ọjọ́ tí ìkún omi yóò bẹ̀rẹ̀ gan-an ni Nóà àti Ṣémù, Ámù àti Jáfétì pẹ̀lú aya Nóà àti aya àwọn ọmọ rẹ̀ wọ inú ọkọ̀.

14Wọn mú ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn ní onírúurú wọn, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ẹyẹ àti àwọn ohun abìyẹ́ ni onírúurú wọn.

15Méjìméjì ni gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè nínú wọlé pẹ̀lú Nóà sínú ọkọ̀.

16Gbogbo wọn wọlé ní takọ tabo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Nóà, OLÚWA sì tì wọn mọ́ inú ọkọ̀.

17Òjò náà sì rọ̀ ní àrọ̀ìrọ̀dá fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ọkọ̀ náà sì ń léfòó lórí omi, kúrò lórí ilẹ̀ bí omi náà ti ń pọ̀ sí i.

18Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkọ̀ náà sì ń léfòó lójú omi.

19Omi náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó bo gbogbo àwọn òkè gíga tí ó wà lábẹ́ ọ̀run.

20Omi náà kún bo àwọn òkè, bí ìwọ̀n mítà bí i méje.

21Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ parun: ẹyẹ, ohun ọ̀sìn, ẹranko igbó, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ènìyàn.

22Gbogbo ohun tí ó wà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ tó ní èémí ìyè ní ihò imú wọn ni ó kú.

23Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ni a parẹ́: ènìyàn àti ẹranko, àwọn ohun tí ń rìn nílẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run pátapáta ló ṣègbé. Nóà àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ni ó ṣẹ́kù.

24Omi náà sì bo ilẹ̀ fún àádọ́jọ ọjọ́ (150).