Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 9:1-29 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Ọlọ́run sì súre fún Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀ wí pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì pọ̀ ní iye, kí ẹ sì kún aye.

2Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀; àti gbogbo ẹja òkun; a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.

3Gbogbo ohun tó wà láàyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún-ún yín bí mo ṣe fi ewéko fún un yín, náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín.

4ⓑ “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

5A ó jẹ ẹnikẹ́ni tó bá ta ẹ̀jẹ̀ (gba ẹ̀mí) ènìyàn sílẹ̀ níyà. Ikú ni yóò jẹ́ ìjìyà ìpànìyàn, ìbá à ṣe láti ọwọ́ ẹranko tàbí ènìyàn.

6ⓒ “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀ láti ọwọ́ ènìyàn ni a ó gbà ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀. Nítorí ní àwòrán Ọlọ́run ni Ọlọ́run dá ènìyàn.

7ⓓ Ṣùgbọ́n ní tiyín, ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ máa gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀, kí ẹ sì pọ̀ sí i lórí rẹ̀.”

8Ọlọ́run sì wí fún Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé:

9“Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín àti pẹ̀lú àwọn ìran yín tí ń bọ̀ lẹ́yìn.

10Àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, ìbáà ṣe ẹja, ẹran ọ̀sìn, ẹranko igbó, gbogbo ohun tí ó jáde kúrò nínú ọkọ̀ pẹ̀lú yín, àní gbogbo ẹ̀dá alààyè ní ayé.

11Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín, láéláé, Èmi kì yóò fi ìkún omi pa ayé run kúrò mọ láéláé, a kì yóò fi omi pa ayé run.”

12Ọlọ́run sì wí pé, “Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ń dá yìí láàrin èmi àti ẹ̀yin àti ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, májẹ̀mú àtìrandíran tó ń bọ̀:

13Mo ti fi òṣùmàrè sí ojú ọ̀run, yóò sì jẹ́ àmì májẹ̀mú láàrin èmi àti ayé.

14Nígbàkúgbà tí mo bá mú kí òjò sú, tí òṣùmàrè bá farahàn ní ojú ọ̀run.

15Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi, tí ó wà láàrin èmi àti ẹ̀yin àti gbogbo ẹ̀dá alààyè, kì yóò sì tún sí ìkún omi mọ́ láti pa gbogbo ẹ̀dá run.

16Nígbàkígbà tí òsùmàrè bá yọ ní ojú ọ̀run, èmi yóò rí i, èmi yóò sì rántí májẹ̀mú ayérayé tí ń bẹ láàrin Ọlọ́run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń bẹ ní ayé.”

17Ọlọ́run sì wí fún Nóà pé, “Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ láàrin èmi àti gbogbo alààyè ní ayé.”

18Àwọn ọmọ Nóà tí ó jáde nínú ọkọ̀ ni Ṣémù, Ámù àti Jáfétì. (Ámù ni bàba Kénánì).

19Nípaṣẹ̀ àwọn ọmọ Nóà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni gbogbo ènìyàn ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ ayé.

20Nóà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀, ó sì gbin ọgbà àjàrà.

21Ó mu àmupara nínú ọtí wáìnì àjàrà rẹ̀, ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò, ó sì sùn nínú àgọ́ rẹ̀.

22Ámù tí í ṣe baba Kénání sì rí baba rẹ̀ ní ìhòòhò bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ méjèèjì ní ìta.

23Ṣùgbọ́n Ṣémù àti Jáfétì mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòòhò baba wọn. Wọ́n kọjú ṣẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòòhò baba wọn.

24Nígbà tí ọtí dá kúrò ní ojú Nóà, tí ó sì mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ àti ohun tí Ámù ọmọ rẹ̀ ṣe sí i.

25Ó wí pé:

25“Ègún ni fún Kénánì. Ìránṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ni yóò máa ṣe fún àwọn arákùnrin rẹ̀.”

26Ó sì tún wí pé; “Olùbùkún ni OLÚWA, Ọlọ́run Ṣémù Kénánì yóò máa ṣe ẹrú fún Ṣémù.

27Ọlọ́run yóò mú Jáfétì gbilẹ̀, Jáfétì yóò máa gbé ní àgọ́ Ṣémù Kénánì yóò sì jẹ́ ẹrú fún-un.”

28Nóà wà láàyè fún irínwó-ọdún-ó-dín-àádọ́ta (350) lẹ́yìn ìkún omi.

29Àpapọ̀ ọjọ́ ayé Nóà jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dín-ní-àádọ́ta ọdún, (950) ó sì kú.