Ìwé Kíróníkà Kìn-ín-ní 11:1-47 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Gbogbo àwọn Ísírẹ́lì kó ara wọn jọ pọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì wọ́n sì wí pé, “Àwa ni ẹran ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ.

2Ní àtijọ́, kódà nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù jẹ ọba, ìwọ ni ẹni tí ó darí Ísírẹ́lì ní ojú ogun wọn. OLÚWA Ọlọ́run rẹ sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ yóò sì jẹ́ olùsọ́ àgùntàn fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, ìwọ yóò sì jẹ́ olórí fún wọn.’ ”

3Nígbà tí gbogbo àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì tí wọ́n ti wá sọ́dọ̀ ọba Dáfídì ni Hébúrónì. Ó sì ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn ní Hébúrónì níwájú OLÚWA, wọ́n sì fi àmìn òróró yan Dáfídì ọba lórí Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti ṣèlérí láti ọ̀dọ̀ Ṣámúẹ́lì.

4ⓑ Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde lọ sí Jérúsálẹ́mù (tí se Jébúsì) Àwọn ara Jébúsì ẹni tí ń gbé níbẹ̀.

5Wí fún Dáfídì pé, ìwọ kò sì gbọdọ̀ rí nínú ibẹ̀. Bí ó ti lẹ̀jẹ́ wí pé, Dáfídì kọ lu odi alágbára ti Ṣíónì, ìlú ńlá Dáfídì.

6Dáfídì ti wí pé Ẹnikẹ́ni tí ó bá darí àti kọlu àwọn ará Jébúsì ni yóò di olórí balógun, Jóábù ọmọ Sérúíà lọ sókè lákòókọ́, bẹ́ẹ̀ ni ó sì gba olórí.

7Dáfídì sì mú lọ sókè ibùgbé nínú odi alágbára, bẹ́ẹ̀ ní a sì ń pè é ni ìlú Dáfídì.

8Ó sì kọ́ àwọn ìlú náà yíkákiri Rẹ̀, láti ọ̀dọ̀ àwọn alátìlẹ́yìn ibi ìtẹ́jú ilẹ̀ si àyíká ògiri. Nígbà tí Jóábù sì pa ìyókù àwọn ìlú náà run.

9Nígbà náà Dáfídì sì jẹ́ alágbára kún alágbára nítorí pé OLÚWA àwọn ọmọ ogun wà pẹ̀lú Rẹ̀.

10ⓒ Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè alágbára ọkùnrin Dáfídì, àwọn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì fún ìjọba Rẹ̀ ní àtìlẹ́yìn tó lágbára láti mú un tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sèlérí:

11èyí sì ni iye àwọn alágbára ọkùnrin Dáfídì:

11Jásóbéámù ọmọ Hákúmónì, òun sì ni olórí nínú àwọn ìjòyè, ó sì gbé ọ̀kọ̀ Rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa ní ogun ẹ̀ẹ̀kan.

12Lẹ́yìn Rẹ̀ sì ni Élíásárì ọmọ Dódáì àwọn ará Áhóhì, ọ̀kan lára àwọn mẹ́ta ọkùnrin alágbára.

13Ó sì wà pẹ̀lú Dáfídì ní Pásídámímù nígbà tí àwọn ará Fílístínì kó ara wọn jọ láti jagun, níbi tí ilẹ̀ kan wà tí ó kún fún ọkà báálì. Àwọn ènìyàn sì sálọ kúrò níwájú Fílístínì.

14Ṣùgbọ́n wọ́n mú ìdúró wọn ní àárin pápá náà. Wọ́n sì gbà a wọ́n sì gún àwọn ará Fílístínì mọ́lẹ̀, OLÚWA sì mú ìgbàlà ńlá fún wọn.

15Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n (30) ìjòyè sọ̀kalẹ̀ tọ́ Dáfídì wá lọ sí orí àpáta nínú ìhò Ádúlámù; Nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ Fílístínì sì dúró ní àfonífojì ní orí òkè Réfáímù.

16Ní àsìkò náà Dáfídì sì wà nínú ibi gíga àti àwọn ará Fílístínì modi sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

17Dáfídì sí pòǹgbẹ fún omi ó sì wí pé, Áà, ẹnìkan yóò ha buomi láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu bodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù fún un mu?

18Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mẹ́ta náà sì là láti ogun ará Fílístínì, ó sì fa omi jáde láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu bodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ó sì gbé padà tọ Dáfídì wá. Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti mu ú: dípò, ó sì tú jáde níwájú OLÚWA.

19“Kí Ọlọ́run dẹ́kun kí èmi ó má ṣe se èyí!” ó wí pé. “Se kí èmi kí ó mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yí ẹnití ó fi ẹ̀mí Rẹ̀ wéwu?” Nítorí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti mú padà wá, Dáfídì kò ní mu ú.

19Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn akọni mẹ́ta ọkùnrin náà ṣe ohun ìyanu ńlá.

20Ábíṣáì arákùnrin Jóábù ìjòyè àwọn mẹ́ta. Ó sì gbé ọ̀kọ̀ Rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀dúnrún àwọn ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn mẹ́ta.

21Ó sì gba ìlọ́po ọlá lórí àwọn mẹ́tẹ̀ta ó sì di olórí wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ka kún ara wọn.

22Bẹ́náyà ọmọ Jéhóíádà ó sì jẹ́ akọni oníjà láti Kábísélì, ẹni tí ó se iṣẹ́ agbára ńlá. Ó sì pa méjì nínú àwọn ọkùnrin tí ó dára jù, ó sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ihò lákókò sno ó sì pa kìnnìún kan

23Ó sì pa ara Éjíbítì ẹni tí ó ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ méje àti ààbọ̀ ṣùgbọ́n àwọn ará Éjíbítì wọn ní ọ̀kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdubú igi àwunṣọ àti ọ̀pá ní ọwọ́ Rẹ̀, Bénáyà sọ̀kalẹ̀ lórí Rẹ̀ pẹ̀lú kùmọ̀. Ó sì gba ọ̀kọ̀ náà láti ọwọ́ ará Éjíbítì ó sì pa á pẹ̀lú ọ̀kọ̀ Rẹ̀.

24Nǹkan wọ̀nyí sì ní ìwà akin. Bénáìá ọmọ Jéhóíádà; ohun náà pẹ̀lú sì di ọlálá gẹ́gẹ́ bí àwọn akọni ọkùnrin mẹ́ta.

25Ó sì ní ọlá púpọ̀ ju àwọn ọgbọ̀n (30) lọ, ṣùgbọ́n a kò káà láàrin àwọn mẹ́tẹ̀ta. Dáfídì sì fi sí ìkáwọ́ àwọn ẹ̀sọ́.

26Àwọn akọni ọkùnrin náà nìyí: Ásáhélì arákùnrin Jóábù, Élíhánánì ọmọ Dódò láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,

27Ṣámótù ará Hárórì,

27Hélésì ará Pélónì

28Írà ọmọ Íkéṣì láti Tékóà,

28Ábíésérì láti Ánátótì,

29Ṣíbékíà ará Húṣátì,

29láti ará Áhóhì

30Máháráì ará Nétófà,

30Hélédì ọmọ Báánà ará Nétófà,

31Ítaì ọmọ Ríbáì láti Gíbéà ní Bẹ́ńjámínì,

31Bẹ́náyà ará Pírátónì,

32Húráì láti odò Gáṣì,

32Ábíélì ará Áríbátì,

33Ásímáfétì ará Báhárúmù

33Élíábà ará Ṣáíbónì

34Àwọn ọmọ Háṣémù ará Gísónì

34Jónátanì ọmọ ṣágè ará Hárárì.

35Áhíámù ọmọ sákárì ará Hárárì,

35Élífálì ọmọ Úrì

36Héférì ará Mékérátì,

36Áhíjà ará Pélónì,

37Hésírónì ará Kárímélì

37Náráì ọmọ Ésíbáì,

38Jóẹ́lì arákùnrin Nátanì

38Míbárì ọmọ Hágárì,

39Ṣélékì ará Ámónì,

39Náháráì ará Bérótì ẹni tí ó jẹ́ áru ìhámọ́ra Jóábù ọmọ Ṣérúyà.

40Írà ará Ítírì,

40Gárébù ará Ítírì,

41Húríyà ará Hítì

41Ṣábádì ọmọ Áháláyì.

42Ádínà ọmọ Ṣísà ará Réúbẹ́nì, ẹni tí ó jẹ́ ìjòyè ará Réubẹ́nì, àti pẹ̀lú ọgbọ́n Rẹ̀.

42

43Hánánì ọmọ Mákà.

43Jóṣáfátì ará Mítínì.

44Úsíà ará Ásílérátì,

44Ṣámà àti Jégiẹ́lì àwọn ọmọ Hótanì ará Áróérì,

45Jédíáélì ọmọ Ṣímírì,

45àti arákùnrin Jóhà ará Tísì

46Élíélì ará Máháfì Ítímáì ará Móábù,

46Jéríbáì àti Jóṣáfíà àwọn ọmọ Élánámì,

47Élíélì, Óbédì àti Jásídì ará Mésóbà.

/article>