1
2Nígbà náà Dáfídì wí pé, Kò sí ẹnìkan àyàfi àwọn ọmọ Léfì ni ó lè gbé Àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, nítorí OLÚWA yàn wọ́n láti gbé àpóti ẹ̀rí OLÚWA àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú Rẹ̀ títí láé.
3Dáfídì kó gbogbo àwon ọmọ Ísírélì jọ ní Jérúsálẹ́mù láti gbé àpótí ẹ̀rí OLÚWA wá sí ibi tí ó ti pèṣè sílẹ̀ fún un.
4Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Árónì àti àwọn ọmọ Léfì tí Dáfídì pèjọ papọ̀:
5
6
7
8
9
10
11Dáfídì sì ránṣẹ́ pe Ṣádókù, Ábíátarì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, àti Úríélì, Ásáíà. Jóẹ́lì, Ṣémáíà, Élíélì àti Ámínádábù tí wọ́n jẹ́ Léfì.
12Ó sì fí fún wọn pé, Ẹ̀yin ni olórí àwọn ìdílé Léfì; ẹ̀yin àti àwọn Léfì ènìyàn yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ lè gbé àpótí-ẹ̀rí OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, lọ sí ibi tí mó ti pèsè sílẹ̀ fún un.
13Nítorí tí ẹ̀yin ọmọ Léfì kò gbe gòkè wá ní ìgbà àkọ́kọ́ ti OLÚWA Ọlọ́run wa ya ìbínú Rẹ̀ lù wá. Àwa kò sì ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Rẹ̀ nípa bí a ti ń ṣe é gẹ́gẹ́ bí ọ́nà tí a là sílẹ̀.
14Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé àpótí-ẹ̀rí OLÚWA gòkè wá, Ọlọ́run Ísírélì.
15Nígbà náà ni àwọn Léfì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run pẹ̀lú ọ̀pá ní èjìká wọn. Gẹ́gẹ́ bí Mósè ti paá láṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLÚWA.
16Dáfídì sọ fún àwọn olórí àwọn Léfì láti yan àwọn arákùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí akọrin láti kọ orin ayọ̀, pẹ̀lú àwọn ohun-èlò orin pisalitérì, dùùrù, àti Ṣíḿbálì.
17Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Léfì yan Hámánì ọmọ Jóẹ́lì; àti nínú àwọn arákùnrin Rẹ̀, Ásáfù ọmọ Bérékíà, àti nínú àwọn ọmọ Mérárì arákùnrin wọn, Étanì ọmọ Kúṣáíà;
18àti pẹ̀lú wọn àwọn arákùnrin wọn tí a yàn bí olùrànlọ́wọ́ wọn: Ṣekaríyà, Jásíélì; Ṣémírámótì, Jéhíélì, Únì, Élíféléhù, Míkíméíà, àti àwọn asọ́bodè Obedi-Edomu àti Jélíélì.
19Àwọn akọrin sì ni Hémánì, Ásáfù, àti Étanì ti àwọn ti kíḿbálì idẹ tí ń dún kíkan;
20Ṣekaríyà, Ásíélì, Ṣémírámótì, Jẹ́híélì, Únínì, Élíábù, Máséíà àti Beniáyà àwọn tí ó gbọdọ̀ ta láétírì gẹ́gẹ́ bí
21Àti Mátítíyà, Élíféléhù, Míkínéyà, Obedi-Édómù, Jélíélì àti Ásásíyà ni ó ní láti ta ohun èlò olóhùn goro, láti darí gẹ́gẹ́ bí
22Kénáníyá orin àwọn ará Léfì ni ó wà ní ìkáwọ́ orin èyí sì ni ojúṣe nítorí ó mòye nípa Rẹ̀.
23Bérékíà àti Ékáníyà ni kí ó wà gẹ́gẹ́ bí olùsọ́nà fún àpótí ẹ̀rí.
24Ṣébéáníá, Jóṣáfátì, Nétanélì, Ámásáyì, Ṣekaríyà, Beniáyà àti Élíásérì ní àwọn àlùfáà, ti o ń fún ìpè níwájú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. Obedi-Édómù àti Jéhíyà ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ olùsọ́nà fún àpótí ẹ̀rí.
25Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ láti gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú OLÚWA láti ilé Obedi-Édómù, pẹ̀lú inú dídùn.
26Nítori Ọlọ́run tì ràn wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Léfì énì tí ó gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú OLÚWA, akọ màlúù méje pẹ̀lú àgbò méje láti fi sé ìrúbọ.
27Nísinsìn yìí Dáfídì sì wọ aṣọ ìgúnwà ọ̀gbọ̀ dáradára, gẹ́gẹ́ bí akọrin, àti Kenaníyà, ẹnití ó wà ní ìkáwó orin kíkọ àwọn akọrin. Dáfídì sì wọ aṣọ ìgúnwà fun fun.
28Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Ísírẹ́lì gbé àpótí ẹ̀rí àti májẹ̀mú OLÚWA gòkè wá pẹ̀lú ariwo, pèlú àyíká ìhó ayọ̀ àti láti fọn fèrè ti ìpè, àti kíḿbálì, àti láti ta písálítérì; àti dùùrù olóhun goro.
29Bí àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú OLÚWA ti ń wọ ìlú ńlá Dáfídì, Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù ń wò láti ojú fèrèsé nígbà tí ó sì rí ọba Dáfídì ń jó, ó sì ń ṣe àjọyọ̀, ó sì kẹ́gàn Rẹ̀ ní ọkàn Rẹ̀.