Ìwé Kíróníkà Kìn-ín-ní 16:1-43 BYB2014 - Bible AI

1Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wá sínú àgọ́ ti Dáfídì ti pàṣẹ fún un, wọ́n sì gbé ọrẹ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀ kalẹ̀ níwájú Ọlọ́run.

2Lẹ́yìn ọrẹ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, ó bùkún àwọn ènìyàn ní orúkọ OLÚWA.

3Nígbà náà ó fún olúkúlùkù ọkùnrin àti obìnrin ọmọ Ísírẹ́lí ní ìṣù àkàrà kan, àkàrà dídùn ti àkókò kan àti àkàrà dídùn ti èṣo àjàrà kan.

4Ó yan díẹ̀ lára àwọn ará Léfì láti máa jọ́sìn níwájú àpótí ẹ̀rí OLÚWA, àti láti ṣe ìrántí àti dúpẹ́ àti láti yin OLÚWA, Ọlọ́run Ísírélì.

5Ásáfù jẹ́ olóyè Ṣémírámótì, Jéhíelì, Mátítíyà, Élíábìlì, Bénáyà, Obedi-Édómù àti Jélíélì, Àwọn ni yóò lu lẹ́rì àti dùùrù háàpù. Ásáfù ni yóò lu símíbálì kíkan.

6Àti Bénáià àti Jahaṣíélì àwọn àlùfáà ni yóò fọn ipè dédé níwájú àpótí ẹ̀rí méjẹ̀mú ti Ọlọ́run.

7Ní ọjọ́ náà Dáfídì kọ́kọ́ fi lé Ásáfù àti àwon ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ orin Dáfídì ti ọpẹ́ sí OLÚWA:

8ⓐ Ẹ fi ọpẹ́ fún OLÚWA, ẹ pe orúkọ Rẹ̀, ẹ fi iṣẹ́ Rẹ̀ hàn nínú àwọn ènìyàn fún ohun tí ó ṣe

9Ẹ kọrin síi, ẹ kọrin ìyìn, síi, Ẹ sọ ti gbogbo iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀

10Ìyìn nínú orúkọ Rẹ̀ mímọ́; jẹ kí ọkàn àwọn tí ó yin OLÚWA kí ó yọ̀.

11Ẹ wá OLÚWA àti agbára Rẹ̀; O wá ojú Rẹ̀ nígbà gbogbo.

12Rántí àwọn ìyanu tí Ó ti ṣe, isẹ́ ìyanu Rẹ̀ àti ídájọ́ tí Ó ti sọ.

13A! èyin ìran ọmọ Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ Rẹ̀, àwon ọmọ Jákọ́bù, ẹ̀yin tí ó ti yàn.

13

14Òun ni OLÚWA Ọlọ́run wa; ìdájọ́ Rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.

15Ó ránti májẹ̀mú rẹ́ títí láé, ọ̀rọ̀ tí Ó pa láṣẹ fún ẹgbẹ̀rún ìran,

16Májẹ̀mu tí ó dá pẹ̀lú Ábúráhámù, ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Ísákì.

17Ó ṣe ìdánilójú u Rẹ̀ fún Jákọ́bù gẹ́gẹ́ bí òfin, sí Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú láéláé.

18“Sí ọ, ni Èmi yóò fún ní ilẹ̀ Kénánì. Gẹ́gẹ́ bí àyè tí ìwọ yóò jogún.”

18

19Nígbà tí wọn kéré ní iye, wọ́n kéré gidigidi, wọ́n sì jẹ́ àlejò níbẹ̀,

20wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀ èdè sí orílẹ̀-èdè láti ìjọba kan sí èkejì.

21Kò gba ọkùnrin kankan láyè láti pọ́n wọn lójú; nítorí ti wọn, ó bá àwọn ọba wí.

22“Má ṣe fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi; Má ṣe pa àwọn wòlíì mi lára.”

22

23ⓑ Kọrin sí OLÚWA gbogbo ayé; ẹ máa fi ìgbàlà Rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́.

24Kéde ìgbàlà à Rẹ̀ láàárin àwọn orílẹ̀-èdè, ohun ìyàlẹ́nu tí ó se láàrin gbogbo ènìyàn.

25Nítorí títóbi ni OLÚWA òun sì ni ìyìn yẹ Jùlọ; òun ni kí a bẹ̀rù ju gbogbo àwon Ọlọ́run lọ.

26Nítorí gbogbo àwọn Ọlọ́run orílẹ̀ èdè jẹ́ àwọn òrìsà, ṣùgbọ́n OLÚWA dá àwọn ọ̀run.

27Dídán àti ọlá-ńlá ni ó wà ní wájú Rẹ̀; agbára àti ayọ̀ ni ó wà ní ibi ibùgbé Rẹ̀.

28Fifún OLÚWA, ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ fi ògo àti ipá fún OLÚWA,

29fún OLÚWA ní ìyìn nítorí orúkọ Rẹ̀. Gbé ọrẹ kí ẹ sì wá ṣíwájú Rẹ̀; Sìn OLÚWA nínú inú dídùn ìwà mímọ́ Rẹ̀.

30Wárìrì níwájú Rẹ̀, gbogbo ayé! Ayé sì fi ìdímúlẹ̀; a kò sì le è síi.

31Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀ Jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn; Jẹ́ kí wọn kí ó sọ láàárin àwọn orílẹ̀ èdè, pé “OLÚWA jọba!”

32Jẹ́ kí ọ̀run kí ó tún dún padà, ati gbogbo ohun tí ó wà nínú Rẹ̀; Jẹ́ kí àwọn pápá kí ó hó fún ayọ̀, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú Rẹ̀!

33Nígbà náà ni igi ti ọ̀dàn yóò kọrin, Wọn yóò kọrin fún ayọ̀ níwájú OLÚWA, Nítorí tí ó wá láti sèdájọ́ ayé.

33

34ⓒ Fi ọpẹ fún OLÚWA, nítórí tí ó dára; ìfẹ́ ẹ Rẹ̀ dúró títí láé.

35ⓓ Sunkún jáde, “Gbà wá, Ọlọ́run Olùgbàlà a wa; kówajọ kí o sì gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀ èdè, kí àwa kí ó lè fí ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí àwa kí ó lè yọ̀ nínú ìyìn Rẹ̀.”

36Olùbùkún ni OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, láé àti láéláé.

36Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn ènìyàn wí pé “Àmín” wọ́n sì Yin OLÚWA.

37Dáfídì fi Áṣáfù àti àwọn ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀ sílẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú OLÚWA láti jísẹ́ níbẹ̀ déédé, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe gbà.

38Ó fí Óbédì-Edomù àti méjìdín láàdọ́rin (68) ẹlẹgbẹ́ ẹ Rẹ̀ làti siṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú wọn. Óbédí-Édómú ọmọ Jédútúnì àti Hósà pẹ̀lú jẹ́ olútọ́jú ẹnu-ọ́nà.

39Dáfídì fi Ṣádókù àlùfáà àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀ níwájú Àgọ́ OLÚWA ní ibi gíga ní Gíbíónì.

40Láti gbé pẹpẹ ọrẹ sísun déédé, àárọ̀ àti Ìrọ̀lẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú òfin OLÚWA, tí ó ti fún Ísírẹ́lì.

41Pẹ̀lú wọn ni Hémánì àti Jédútúnì àti ìyókù tí a mú àti yàn nípaṣẹ̀ orúkọ láti fi ọpẹ́ fún OLÚWA Nítorí tí ìfẹ́ Rẹ̀ dúró títí láéláé

42Hémánì àti Jédútúnì ni wọ́n dúró fún fifọn ìpè àti Ṣíḿibálì àti fún títa ohun èlò yòókù fún orin yíyàsọ́tọ̀. Àwọn ọmọ Jédútúnì wà ní ipò dídúró ní ẹnu-ọ̀nà.

43Nígbà náà gbogbo àwọn ènìyàn kúrò, olúkúlùkù sí ilé láti lọ bùkún ìdílé Rẹ̀

/article>