Ìwé Kíróníkà Kìn-ín-ní 2:1-55 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Réúbẹ́nì, Símónì, Léfì, Júdà, Ísákárì, Ṣébúlúnì,

2Dánì, Jóṣẹ́fù, Bẹ́ńjámínì; Náfítanì, Gádì: àti Áṣérì.

2

3ⓑ Àwọn ọmọ Júdà:

3Érì, Ónánì àti Ṣélà, àwọn mẹ́tẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kénánì, ọmọbìnrin Súà Érì àkọ́bí Júdà, ó sì burú ní ojú OLÚWA; Bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA sì pa á.

4Támárì, aya ọmọbìnrin Júdà, ó sì bí Fárésì àti Ṣérà sì ní ọmọ márùn ún ní àpapọ̀

4

5ⓒ Àwọn ọmọ Fárésì:

5Hésírónì àti Hámúlù.

6Àwọn ọmọ Ṣérà:

6Ṣímírì, Étanì, Hémánì, Kálíkólì àti Darà, gbogbo wọn jẹ́ márùn ún.

7Àwọn ọmọ Kárímì:

7Ákárì, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Ísírẹ́lì nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀.

8Àwọn ọmọ Étanì:

8Áṣáríyà

9Àwọn ọmọ tí a bí fún Hésírónì ni:

9Jéráhímélì, Rámù àti Kélẹ́bù.

10Rámù sì ni baba

10Ámínádábù, àti Ámínádábù baba Náṣónì olórí àwọn ènìyàn Júdà.

11Náṣónì sì ni baba Sálímà, Sálímà ni baba Bóásì,

12Bóásì baba Óbédì àti Óbédì baba Jésè.

12

13Jésè sì ni Baba

13Élíábù àkọ́bí Rẹ̀; ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kẹjì sì ni Ábínádábù, ẹlẹ́ẹ̀kẹta ni Ṣíméà,

14Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin Nàtaníẹ́lì, ẹlẹ́ẹ̀káàrùn-ún Rádáì,

15ẹlẹ́ẹ̀kẹfà Ósémù àti ẹlẹ́ẹ̀keje Dáfídì.

16Àwọn arábìnrin wọn ni Ṣérúà àti Ábígáílì. Àwọn ọmọ mẹ́ta Ṣérúà ni Ábíṣáì, Jóábù àti Ásáélì.

17Ábígáílì ni ìyá Ámásà, ẹni tí baba Rẹ̀ sì jẹ́ Jétérì ará Íṣímáẹ́lì.

17

18Kélẹ́bù ọmọ Hésírónì ní ọmọ láti ọ̀dọ̀ ìyàwó Rẹ̀ Ásúbà (láti ọ̀dọ̀ Jéríótù). Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Rẹ̀: Jéṣérì, Ṣóbábù àti Árídónì.

19Nígbà tí Ásúbà sì kú, Kélẹ́bù sì fẹ́ Éfúrátì ní aya, ẹni tí ó bí Húrì fún un.

20Húrì ni baba Úrù, Úrù sì jẹ́ baba Bésálélì.

20

21Nígbà tí ó yá, Hésírónì sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Mákírì baba Gílíádì (ó sì ti fẹ́ ní aya láti ìgbà tí ó ti wà ní ẹni ọgọ́ta ọdún) ó sì bí Ṣégúbù.

22Ṣégúbù sì jẹ́ bàbá Jáírì, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìlú mẹ́talélógún ní ilẹ̀ Gílíádì.

23(Ṣùgbọ́n Gésúrì àti Árámù sì fi agbára gba Hafoti Jáírì, àti Kénátì pẹ̀lú gbogbo agbégbé Rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.) Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Mákírì Baba Gílíádì.

23

24Lẹ́yìn tí Hésírónì sì kú ni Kélẹ́bù Éfúrátà, Ábíà ìyàwó Rẹ̀ ti Hésírónì sì bí Áṣúrì baba Tẹ́kóà fún un

24

25Ọmọ Jéráhímélì àkọ́bí Hésírónì:

25Rámà ọmọ àkọ́bí Rẹ̀ Búnà, Órénì, óṣémù àti Áhíjà.

26Jéráhímélì ní ìyàwó mìíràn, ẹni tí orúkọ Rẹ̀ ń jẹ́ Átarà; ó sì jẹ́ ìyá fún Ónámù.

26

27Àwọn ọmọ Rámà àkọ́bí Jéráhímélì:

27Másì, Jámínì àti Ékérì.

28Àwọn ọmọ Ónámù: Àwọn ọmọ Ṣámáì: Nádábù àti Ábísúrì.

28Ṣámáì àti Jádà.

29Orúkọ ìyàwó Ábísúrì ni Ábíháílì ẹni tí ó bí Áhíbánì àti Mólídì.

29

30Àwọn ọmọ Nádábù

30Ṣélédì àti Ápáímù. Ṣélédì sì kú láìsí ọmọ.

31Àwọn ọmọ Ápáímù: Ṣésánì sì jẹ́ baba fún Áhíláì.

31Isì, ẹnití ó jẹ́ baba fún Ṣésánì.

32Àwọn ọmọ Jádà, arákùnrin Ṣámáì:

32Jétérì àti Jónátanì. Jétérì sì kú láìní ọmọ.

33Àwọn ọmọ Jónátanì: Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Jéráhímẹ́lì.

33Pélétì àti Ṣásà.

34Ṣésánì kò sì ní ọmọkùnrin àwọn ọmọbìnrin nìkan ni ó ní.

34Ó sì ní ìránṣẹ́ ará Éjíbítì tí orúkọ Rẹ̀ ń jẹ́ Járíhà.

35Ṣẹ́sánì sì fi ọmọ obìnrin Rẹ̀ ní aya fún ìránṣẹ́ Rẹ̀ Járíhà, ó sì bí ọmọ fún tí orúkọ Rẹ̀ jẹ́ Átaì.

35

36Átaì sì jẹ́ baba fún Nátanì,

36Nátanì sì jẹ́ baba fún Ṣábádì,

37Ṣábádì ni baba Éfúlálì,

37Éfúlálì jẹ́ baba Óbédì,

38Óbédì sì ni baba Jéhù,

38Jéhù ni baba Ásáríyà,

39Ásáríyà sì ni baba Hélésì,

39Hélésì ni baba Éléáṣáì,

40Éléáṣáì ni baba Ṣísámálì,

40Ṣísámálì ni baba Ṣálúmù,

41Ṣálúmù sì ni baba Élísámà.

41

42Àwọn ọmọ Kálébù arákùnrin Jérámélì:

42Méṣà àkọ́bí Rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Ṣífì àti àwọn ọmọ Rẹ̀ Méréṣà, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Hébúrónì.

43Àwọn ọmọ Hébúrónì:

43Kórà, Tápúà, Rékémù, àti Ṣémà.

44Ṣémà ni baba Ráhámú Ráhámù sì jẹ́ baba fún Jóríkéámù. Rékémù sì ni baba Ṣémáì.

45Àwọn ọmọ Ṣémáì ni Máónì, Máónì sì ni baba Bétí-Ṣúri.

45

46Éfà Obìnrin Kélẹ́bù sì ni ìyá Hárà nì, Mósà àti Gásésì, Háránì sì ni baba Gásésì.

46

47Àwọn ọmọ Jádáì:

47Régémù, Jótamù, Gésánì, Pétélì, Éfà àti Ṣáfù.

48Mákà obìnrin Kélẹ́bù sì ni ìyá Ṣébérì àti Tíránà.

49Ó sì bí Ṣáfà baba Mákíbénà, Ṣéfà baba Mákíbénà àti baba Gíbéà: ọmọbìnrin Kélẹ́bù sì ni Ákíṣà.

50Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Kélẹ́bù. Ṣóbálì baba Kiriati-Jéárímù.

50Àwọn ọmọ Húrì, àkọ́bí Éfúrátà:

51Ṣálímà baba Bétíléhẹ́mù àti Háréfù baba Bẹti-Gádérì.

51

52Àwọn ọmọ Ṣóbálì baba Kíríátì-Jéárímù ni:

52Háróè, ìdajì àwọn ará Mánáhítì.

53Àti ìdílé Kíríátì-Jéárímù: àti àwọn ara Ítírì, àti àwọn ará Pútì, àti àwọn ará Ṣúmátì àti àwọn ará Mísíhí-ráì: láti ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn ọmọ ará Sórátì àti àwọn ará Ésítaólì ti wá.

53

54Àwọn ọmọ Ṣálímà:

54Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, àti àwọn ará Nétófátì, Atírótì Bẹti-Jóábù, ìdajì àwọn ará Mánátì, àti Ṣórì,

55Àti àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé, ẹni tí ń gbé ní Jábésì: àti àwọn ọmọ Tírátì àti àwọn ará Ṣíméátì àti àwọn ará Ṣúkátì. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ará Kénì, ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Hámátì, baba ilé Kélẹ́bù.

article>