Ìwé Kíróníkà Kìn-ín-ní 23:1-32 BYB2014 - Bible AI

1Nígbà tí Dáfídì sì dàgbà tí ó sì kún fún ọjọ́, ó sì fi Sólómónì ọmọ Rẹ̀ jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì.

2Ó sì kó gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, àti gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì.

3Àwọn ọmọ Lefì lati ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n kà àpapọ̀ iye àwọn ọkùnrin wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún (38,000)

4Dáfídì sì wí pe, Níti èyí, ẹgbàáméjìlá (24,000) ni kí wọn jẹ́ alábojútó iṣẹ́ ilé fún OLÚWA àti ẹgbàáta (6,000) ni kí ó ṣe olórí àti onídàájọ́.

5Ẹgbàájì (4,000) ni kí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà àti ẹgbàajì (4,000) ni kí o sì jẹ́ ẹni ti yóò máa yin OLÚWA pẹ̀lú ohun èlò orin, mo ti se èyí fún ìdí pàtàkì yìí.

6Dáfídì sì pín àwọn ọmọ Léfì sí ẹgbẹgbẹ́ láàrin àwọn ọmọ Léfì Gérísónì, Kóhátì àti Mérárì.

7Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gérísónì: Ládánì àti Ṣíméhì.

8Àwọn ọmọ Ládánì

8Jéhíélì ẹni àkọ́kọ́, Ṣétanì àti Jóẹ́lì ẹ̀kẹ́ta ní gbogbo wọn.

9Àwọn ọmọ Ṣímè: Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Ládánì.

9Ṣélómótì, Hásíélì àti Háránì mẹ́ta ní gbogbo wọn.

10Àti ọmọ Ṣímélì: Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ṣíméhì mẹ́rin ni gbogbo wọn.

10Jáhátì, Ṣísà, Jéúsì àti Béríà.

11Jáhátì sì ni alákọ́kọ́ Ṣísà sì ni ẹlẹ́kejì, ṣùgbọ́n Jéúsì àti Béríà kò ní àwọn ọmọ púpọ̀; Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ka ara wọn sí ìdílé kan pẹ̀lú ìfilé lọ́wọ́ kan.

12Àwọn ọmọ kóhátì: Ámírámù, Ísárì, Hébúrónì àti Usíélì mẹ́rin ni gbogbo wọn.

13ⓐ Àwọn ọmọ Ámírámù. Árónì àti Móṣè.

13A sì ya Árónì sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ Rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rúbọ sísun níwájú OLÚWA, láti máa ṣe òjísẹ́ níwájú Rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ Rẹ̀ títí láéláé.

14Àwọn ọmọ Mósè ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí apákan ẹ̀yà Léfì.

14

15Àwọn ọmọ Mósè;

15Gérísónì àti Élíásérì.

16Àwọn ọmọ Gérísónì

16Ṣúbáélì sì ni alákọ́kọ́.

17Àwọn ọmọ Élíásérì: Élíásérì kò sì tún ní ọmọ mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Réhábíà wọ́n sì pọ̀ níye.

17Réhábíà sì ni ẹni àkọ́kọ́.

18Àwọn ọmọ Ísárì:

18Ṣélómítì sì ni ẹni àkọ́kọ́.

19Àwọn ọmọ Hérónì:

19Jéríyà sì ni ẹni àkọ́kọ́, Ámáríyà sì ni ẹni ẹ̀ẹ̀kejì, Jáhásíélì sì ni ẹ̀ẹ̀kẹta àti Jékáméámù ẹ̀ẹ̀kẹrin.

20Àwọn ọmọ Húsíélì:

20Míkà ni àkọ́kọ́ àti Íṣíà ẹ̀ẹ̀kejì.

21Àwọn ọmọ Mérárì: Máhílì àti Músì. Àwọn ọmọ Máhílì: Élíásárì àti Kísì.

22Élíásérì sì kú pẹ̀lú Àìní àwọn ọmọkùnrin: Ó ní ọmọbìnrin nìkan. Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n, àwọn ọmọ Kísì, sì fẹ́ wọn.

22

23Àwọn ọmọ Músì:

23Málì, Édérì àti Jérímótì mẹ́ta ni gbogbo wọn.

24Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Léfì bí ìdílé wọn. Olórí ìdílé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ orúkọ wọn, ó sì kà wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, wí pé, àwọn òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú ilé OLÚWA

25Nítorí pé Dáfídì ti sọ pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti fi ìsinmi fún àwọn ènìyàn tí ó kù tí sì ń gbé Jérúsálẹ́mù títí láéláé.

26Àwọn ọmọ Léfì kò sì tún ru àgọ́ tàbí ọ̀kankan lára àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò níbi ìsìn Rẹ̀.

27Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dáfídì sí, àwọn ọmọ Léfì, wọ́n sì kà wọ́n, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ọmọ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.

28Iṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì ni láti ran àwọn ọmọ Árónì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé OLÚWA: láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tìí ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé OLÚWA.

29Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ ọrẹ, àti aláìwú pẹ̀tẹ̀, àti fún dídùn àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òṣùnwọ̀n.

30Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin OLÚWA. Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àsálẹ́.

31Ní gbàkúgbà ẹbọ ọrẹ sísun ni wọ́n fi fún OLÚWA ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì tí a paláṣẹ. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú OLÚWA lójojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti paláṣẹ fún wọn.

32Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Léfì gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún ibi mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Árónì fún ìsìn ilé OLÚWA.

/article>