Ìwé Kíróníkà Kìn-ín-ní 24:1-31 BYB2014 - Bible AI

1Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Árónì: Àwọn ọmọ Árónì ni Nádábù, Ábíhù, Élíásérì àti Ítamárì.

2Ṣùgbọ́n Nádábù àti Ábíhù kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; Bẹ́ẹ̀ ni Élíásérì àti Ítamárì sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

3Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ṣádókì ọmọ Élíásérì àti Áhímélékì ọmọ Ítamárì, Dáfídì sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn.

4A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Élíásérì ju lára àwọn ọmọ Ítamárì lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rindínlógún (16) olórí láti ìdílé ọmọ Élíásérì ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Ítamárì.

5Wọ́n sì pín wọn lótìítọ́ nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olorí ilé Ọlọ́run wà láàrin àwọn ọmọ méjèèjì Élíásérì àti Ìtamárì.

6Ṣémáíà ọmọ Nétanélì, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Léfì sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Ṣádókù Àlùfáà, Áhímélékì ọmọ Ábíátarì àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Éléásári àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Ítamárì.

7Ìpín èkíní jáde sí Jéhóíáríbù, èkejì sí Jédáià,

8Ẹlẹ́kẹta sì ni Hárímù,

8ẹ̀kẹ́rin sì ní Ṣéórímù,

9Ẹ̀karùn-ún sì ni Maíkíyà,

9ẹlẹkẹ́fà sì ni Míjámínì,

10Ẹ̀kẹ́je sì ni Hakósì,

10ẹlẹ́kẹ́jọ sí ni Ábíjà,

11Ẹkẹ́sàn sì ni Jésúà,

11ẹ̀kẹ́wà sì ni Ṣékáníà,

12Ẹ̀kọ́kànlá sì ni Élíásíbù,

12ẹlẹ́kẹjìlá sì ni Jákímù,

13Ẹ̀kẹtàlá sì ni Húpà,

13ẹlẹ́kẹrìnlá sì ni Jéṣébéábù,

14Ẹkẹdógun sì ni Bílígà,

14ẹ̀kẹ́rìndílogún sì ni Ímerì

15Ẹ̀kẹtàdílógún sì ni Héṣírì,

15ekejìdílógún sì ni Háfísesì,

16Ẹ̀kọkàndílógún sì ni Pétalà,

16ogún sì ni Jéhésékélì,

17Ẹ̀kọ́kànlélógún sì ni Jákínì,

17ẹ̀kẹ́rìnlélogún sì ni Gámúlì,

18Ẹ̀kẹtàlélógún sì ni Déláyà,

18ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Másíà.

19Àwọn wọ̀nyí ni a yàn fún iṣẹ́ ìsìn nígbà tí wọ́n wọ ilé OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti àṣẹ tí a ti fi fún wọn láti ọwọ́ baba ńlá wọn Árónì gẹ́gẹ́ bí OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí pàṣẹ fun wọn.

20Ìyòókù àwọn ọmọ Léfì: láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámúríamù: Ṣúbáelì; láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣúbáélì; Jédeíà.

21Àti gẹ́gẹ́ bí Réhábíà, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Réhábíà:

21Íṣíà sì ni alákọ́kọ́.

22Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Iṣárì: Ṣélómótì;

22láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣélomótì: Jáhátì.

23Àwọn ọmọ Hebúrónì: Jéríyà alákọ́kọ́, Ámáríyà elẹ́kẹjì, Jáhásélì ẹlẹ́kẹta àti Jékáméámù ẹlẹ́kẹrin.

23

24Àwọn ọmọ Húsíélì: Mikà;

24nínú àwọn ọmọ Míkà: Ṣámírù.

25Àwọn arákùnrin Míkà: Íṣíà;

25nínú àwọn ọmọ Íṣíà: Ṣekaríyà.

26Àwọn ọmọ Mérarì: Málì àti Múṣì.

26Àwọn ọmọ Jásíà: Bẹ́nò.

27Àwọn ọmọ Mérárì:

27Lati Jasíà: Bẹ́nò, Ṣóhámù, Ṣákúrì àti Íbírì.

28Láti Málì: Élíásérì, ẹni tí kò ni àwọn ọmọ.

28

29Láti Kíṣì: Àwọn ọmọ Kíṣì:

29Jérámélì.

30Àti àwọn ọmọ Muṣì: Málì, Édérì àti Jérímotì.

30Èyí ni àwọn ọmọ Léfì, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

31Wọ́n sì ṣé kèké gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Árónì ṣe ṣẹ́, níwáju ọba Dáfídì àti Ṣádókì, Áhímélékì, àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì. Àwọn ìdilé àgbààgbà arákùnrin wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lórí àwọn arakùnrin wọn kéékèèkéé.

/article>