1Pẹ̀lúpẹ̀lú Dáfídì àti àwọn olórí àwọn ọmọ ogun, ó sì yà díẹ̀ sọ́tọ̀ lára àwọn ọmọ Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì fún ìsìn àsọtẹ́lè, pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin àti kínbálì. Èyí sì ní àwọn iye àwọn ọkùnrin ẹni tí ó ṣe oníṣẹ́ ìsìn yìí:
2Nínú àwọn ọmọ Ásáfù: Ṣákúrì, Jóṣẹ́fù Nétanáíà àti Ásárélà, àwọn ọmọ Ásáfù ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó Ásáfù, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀ lábẹ́ ìbojútó ọba.
3Gẹ́gẹ́ bí ti Jédútúnì, nínú àwọn ọmọkùnrin Rẹ̀: Gédálià, Ṣérì, Jéṣáíà, Ṣíméhì Háṣábíà àti Mátítíyà, mẹ́fà nínú gbogbo wọn, lábẹ́ ìbojútó baba wọn Jédútúnì, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀, ẹni tí ó lo dùùrù láti dúpẹ́ àti lati yin OLÚWA:
4Gẹ́gẹ́ bí ti Hémánì, nínú àwọn ọmọ Rẹ̀: Búkíà, Mátaníyà, Usíélì, Ṣúbáélì àti Jérímótì; Hánáníyà, Hánánì, Élíátà, Gídáítì àti Rámámútì Ésérì; Jósíbékáṣà, Málótì, Hótírì àti Máhásíótì.
5Gbogbo àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Hémánì àti wòlíì ọba. Wọ́n sì fi wọ́n fún nípa ìlérí Ọlọ́run láti máa gbé ìwo sókè. Ọlọ́run sì fún Hémánì ní ọmọkùnrin mẹ́rìnlá àti àwọn ọmọbìnrin mẹ́ta.
6Gbogbo àwọn ọkùnrin yìí ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó àwọn bàba wọn fún ohun èlò orin ilé OLÚWA, pẹ̀lú Kínbálì, Písálítérì àti dùùrù, fún Ìsìn ilé Olúwa. Ásáfù, Jédútúnì, ọba.
7Àwọn ìdilé wọn pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó mòye àti àwọn tí a kọ́ ní ohun èlò orin fún OLÚWA, iye wọn sì jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́jọ (288).
8Kékeré àti àgbà bákan náà, olùkọ́ àti gẹ́gẹ́ bí ti ọmọléèwé, pin dànù fún isẹ́ wọn.
9Isẹ́kèké èkíni èyí tí ó jẹ́ ti Ásáfù, jáde sí Joṣéfù, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti ìdílé Rẹ̀ jẹ́, — méjìlá ekejì sì ni Gédálíà, òun àti àwọn ìdílé Rẹ̀ àti àwọn ọmọ Rẹ̀, — méjìlá
10ẹlẹ́kẹ́ta sí Sákúrù, àwon ọmọ Rẹ̀ àti àwon ìdílé, — méjìlà
11ẹlẹ́kẹrin sí Ísírì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti àwon ìdílé Rẹ̀ jẹ́, — méjìlá
12ẹlẹ́karùnún sí Nàtania, àwon ọmọ Rẹ̀ àti àwon ìdílé rè jẹ́, — méjìlá
13ẹlẹ́kẹfà sí Búkíà, àwon ọmọ Rẹ̀ àti àwọn ìdílé Rẹ̀ jẹ́, — méjìlá
14ẹlẹ́keje sí Jésárélà, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti Àwọn ìdílé Rẹ̀ jẹ́, — méjìlá
15ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ sí Jéṣáíáyà, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti àwọn ìdílé Rẹ̀ jẹ́, — méjìlá
16ẹlẹ́ẹ̀kẹ́sàn-án sí Mátaníáyà, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti àwon ìdílé Rẹ̀ jẹ́, — méjìlá
17ẹlẹ́ẹ̀kẹ́wàá sí Síméì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti àwon ìdílé Rẹ̀ jẹ́, — méjìlá
18ẹlẹ́ẹ̀kọkànlá sí Ásárélì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti àwọn ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, — méjìlá
19ẹlẹ́ẹ̀kẹjìlá sí Hásábíà, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, — méjìlá
20ẹlẹ́ẹ̀kẹtàlá sí Ṣúbáélì, àwọn ọmọ Rẹ̀ Àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, — méjìlá
21ẹlẹ́ẹ̀kẹrìlá sí Mátítaíà, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, — méjìlá
22ẹlẹ́ẹ̀kẹdógún sí Jérímótì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, — méjìlá
23ẹlẹ́ẹ̀kẹrìndílógún sí Hananáì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, — méjìlá
24ẹlẹ́ẹ̀kẹtàdílógún sí Jóṣíbákásà, àwọn ọmọ Rẹ̀ sì jẹ́, — méjìlá
25ẹlẹ́ẹ̀kejìdílógún sí Hánánì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, — méjìlá
26ẹlẹ́ẹ̀kọkàndílógún sí Míólítì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, — méjìlá
27ogún sí Élíátà, awọn ọmọ Rẹ̀ àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, — méjìlá
28ẹlẹ́ẹ̀kọkànlélógún sí Hótírì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti àwọn ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, — méjìlá
29ẹlẹ́ẹ̀kejìlélógún sí Gídálì, àwọn ọmọ Rẹ̀ àti àwọn ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, — méjìlá
30ẹlẹ́kẹtalélógún sí Máhásíotì, àwọn ọmọ rẹ àti ìdílé Rẹ̀ sì jẹ́, — méjìlá
31ẹlẹ́ẹ̀kẹ́rìnlélógún sí Rómátì-Ésérì, àwọn ọmọ Rẹ̀, àti àwọn ìdílé Rẹ̀, sì jẹ́, — méjìlá