Ìwé Kíróníkà Kìn-ín-ní 3:1-24 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Dáfídì tí a bí fún un ní Hébírónì: Àkọ́bí sì ni Ámínónì ọmọ Áhínóámù ti Jésírẹ́lì; èkejì sì ni Dáníẹ́lì ọmọ Ábígáílì ará Kárímélì;

2Ẹ̀kẹta sì ni Ábúsálómù ọmọ Mákà ọmọbìnrin ti Táímáì ọba Gésúrì;

2ẹ̀kẹrin sì ni Àdóníjà ọmọ Hágítì;

3Ẹ̀kárùnún ni Ṣéfátíyà ọmọ Ábítalì;

3àti ẹ̀kẹfà, Ítíréàmù, láti ọ̀dọ̀ ìyàwó Rẹ̀ Égílà.

4ⓑ Ẹ̀kẹfà ni a bí fún Dáfídì ni Hébúrónì, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.

4Dáfídì sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́talélọ́gbọ̀n (33).

5Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un:

5Ṣámúyà, Ṣóbábù, Náhátì àti Sólómónì. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bátíṣébà ọmọbìnrin Ámíélì.

6Íbíhárì sì wà pẹ̀lú, Élíṣúà, Élífélétì,

7Nógà, Néfégì, Táfíà,

8Élísámù, Élíádà àti Élífétélì mẹ́sàn án ni wọ́n.

9Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dáfídì yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àlè bí fún un. Támárì sì ni arábìnrin wọn.

9

10Ọmọ Sólómónì ni Réhóbóhámù, Ásà ọmọ Rẹ̀, Jéhósáfátì ọmọ Rẹ̀,

10Ábíjà ọmọ Rẹ̀,

11Jéhórámù ọmọ Rẹ̀, Jóásì ọmọ Rẹ̀,

11Áhásáyà ọmọ Rẹ̀,

12Ámásáyà ọmọ Rẹ̀, Jótamù ọmọ Rẹ̀,

12Ásáríyà ọmọ Rẹ̀,

13Áhásì ọmọ Rẹ̀, Mánásè ọmọ Rẹ̀,

13Hesekíáyà ọmọ Rẹ̀,

14Ámónì ọmọ Rẹ̀,

14Jósíà ọmọ Rẹ̀.

15Àwọn ọmọ Jósíà: èkejì ọmọ Rẹ̀ ni Jéhóíákímù, ẹ̀kẹta ọmọ Rẹ̀ ni Ṣédékíà, ẹ̀kẹ́rin ọmọ Rẹ̀ ni Ṣálúmù.

15Àkọ́bí ọmọ Rẹ̀ ni Jóhánánì,

16Àwọn ìran ọmọ Jéhóíákímù: àti Ṣedékíà.

16Jékóníà ọmọ Rẹ̀,

17Àwọn ọmọ Jéhóíákímù tí a mú ní ìgbékùn:

17Ṣálátíélì ọmọ Rẹ̀ ọkùnrin,

18Málíkírámù, Pédáíyà, Ṣénásárì, Jékámíà, Hósámà àti Nédábíà.

18

19Àwọn ọmọ Pédáíyà: Àwọn ọmọ Ṣérúbábélì: Mésúlámù àti Hánáníyà, Ṣélómítì ni arábìnrin wọn.

19Ṣérúbábélì àti Ṣíméhì.

20Àwọn márùnún mìíràn sì tún wà:

20Hásúbà, Óhéhì, Bérékíà, Hasádíà àti Jusabi-Hésédì.

21Àwọn ọmọ Hánáníyà:

21Pélátíà àti Jeṣáíà, àti àwọn ọmọ Réfáíà, ti Árínánì, ti Ọbadíà àti ti ṣékáníà.

22Àwọn ọmọ Ṣékáníà: Hátúsì, Ígéálì, Báríà, Néáríà àti Ṣáfátì, mẹ́fà ni gbogbo wọn.

22Ṣémáíà àti àwọn ọmọ Rẹ̀:

23Àwọn ọmọ Néáríà:

23Élíóéníà; Hísíkíà àti Ásírí kámù, mẹ́ta ni gbogbo wọn.

24Àwọn ọmọ Élíóéníà:

24Hódáíà, Élíásíbù, Pétéláéà, Ákúbù, Jóhánánì, Déláyà àti Ánánì, méje sì ni gbogbo wọn.

article>