Ìwé Kíróníkà Kìn-ín-ní 6:1-81 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Àwọn ọmọ Léfì: Gérísónì, Kóhátì àti Mérárì.

2Àwọn ọmọ Kóhátì:

2Ámírámù, Ísárì, Hébírónì, àti Húsíélì.

3Àwọn ọmọ Ámírámù: Àwọn ọmọkùnrin Árónì: Nádábù, Ábíhù, Élíásérì àti Ítamárì.

3Árónì, Mósè àti Míríámù.

4Élíásérì jẹ́ baba Fínéhásì,

4Fínéhásì baba Ábísúà

5Ábísúà baba Búkì,

5Búkì baba Húṣì,

6Húsì baba Ṣéráhíà,

6Ṣéráhíà baba Méráíótì,

7Méráíótì baba Ámáríyà,

7Ámáríyà baba Áhítúbì

8Álítúbù bàbá Ṣádókù,

8Ṣádókù baba Áhímásì,

9Áhímásì baba Áṣáríyà,

9Ásáríyà baba Jóhánánì,

10Jóhánánì baba Áṣáríyà (Òhun ni ó sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà nínú ilé OLÚWA tí Sólómónì kọ́ sí Jérúsálẹ́mù),

10

11Áṣáríyà baba Ámáríyà

11Ámáríyà baba Áhítúbì

12Áhítúbì baba Ṣádókù.

12Ṣádókù baba Ṣálúmù,

13Ṣálúmù baba Hílíkíyà,

13Hílíkíyà baba Áṣáríyà,

14Áṣáríyà baba Ṣéráíà,

14pẹ̀lú Ṣéráíà baba Jéhósádákì

15A kó Jéhósádákì lẹ́rú nígbà tí OLÚWA lé Júdà àti Jérúsálẹ́mù kúrò ní ìlú nípaṣẹ̀ Nebukadinésárì.

15

16Àwọn ọmọ Léfì:

16Gérísónì, kóhátì àti Mérárì.

17Wọ̀nyí ni àwọn orúkọ àwọn ọmọ Géríṣónì:

17Líbínì àti Ṣíméhì.

18Àwọn ọmọ Kéhátì:

18Ámírámù, Íṣárì, Hébírónì àti Húsíélì.

19Àwọn ọmọ Mérárì: Wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ará Léfì tí a kọ ní ṣíṣẹ̀ ń tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí baba wọn:

19Máhílì àti Múṣì.

20Ti Gérísómù: Ọmọkùnrin Rẹ̀, Ṣímà ọmọkùnrin Rẹ̀,

20Líbínì ọmọkùnrin Rẹ̀, Jéhátì

21Jóáhì ọmọkùnrin Rẹ̀, àti Jéátéráì ọmọkùnrin Rẹ̀.

21Idò ọmọkùnrin Rẹ̀, Ṣéráhì ọmọkùnrin Rẹ̀

22Àwọn ìran ọmọ Kóhátì: Ásírì ọmọkùnrin Rẹ̀.

22Ámínádábù ọmọkùnrin Rẹ̀, Kóráhì ọmọkùnrin Rẹ̀,

23Élikánà ọmọkùnrin Rẹ̀, Ásírì ọmọkùnrin Rẹ̀.

23Ébíásáfí ọmọkùnrin Rẹ̀,

24Táhátì ọmọkùnrin Rẹ̀, Úríélì ọmọkùnrin Rẹ̀,

24Úsíáhì ọmọkùnrin Rẹ̀ àti Ṣọ́ọ̀lù ọmọkùnrin Rẹ̀.

25Àwọn ìran ọmọ Élíkánáhì:

25Ámásáyì, Áhímótì

26Élíkáná ọmọ Rẹ̀, Ṣófáì ọmọ Rẹ̀

26Náhátì ọmọ Rẹ̀,

27Élíábù ọmọ Rẹ̀, àti Ṣámúẹ́lì ọmọ Rẹ̀.

27Jéríhámù ọmọ Rẹ̀, Élíkáná ọmọ Rẹ̀

28Àwọn ọmọ Ṣámúẹ́lì: àti Ábíjà ọmọẹlẹ́ẹ̀kejì.

28Jóẹ́lì àkọ́bí

29Àwọn ìran ọmọ Mérárì: Ṣíméhì ọmọ Rẹ̀, Úṣáhì ọmọ Rẹ̀.

29Máhílì, Líbínì ọmọ Rẹ̀.

30Ṣíméà, ọmọ Rẹ̀ Hágíáhì ọmọ Rẹ̀

30àti Ásáíáhì ọmọ Rẹ̀.

31Èyí ní àwọn ọkùnrin Dáfídì tí a fi sí ìdí orin nínú ilé OLÚWA lẹ́yìn tí àpótí ẹ̀rí ti wá láti sínmìn níbẹ̀.

32Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin ńiwájú Àgọ́ ìpàdé títí tí Ṣólómónì fi kọ́ ilé OLÚWA ní Jérúsálẹ́mù. Wọ́n se iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.

33Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn: Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kóhátítè: Hémánì olùkọrin, ọmọ Jóẹ́lì, ọmọ Ṣámúẹ́lì,

34Ọmọ Élíkánáhì ọmọ Jéróhámù,

34ọmọ Élíéli, ọmọ Tóhà

35Ọmọ Ṣúfì, ọmọ Élíkáná,

35ọmọ Máhátì, ọmọ Ámásáyì,

36Ọmọ Élíkánà, ọmọ Jóẹ́lì,

36ọmọ Ásárááhì, ọmọ Ṣéfáníáhì

37Ọmọ Táhátì, ọmọ Áṣírì,

37ọmọ Ébíásáfì ọmọ Kóráhì,

38ọmọ Íṣíhárì, ọmọ Kóhátì

38ọmọ Léfì, ọmọ Ísírẹ́lì;

39Hémánì sì darapọ̀ mọ́ Ásátì, ẹni tí Ó sìn ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀:

39Ásátì ọmọ bérékíáhì, ọmọ Ṣíméà,

40Ọmọ Míkáélì, ọmọ Bááséíáhì,

40ọmọ Málíkíjáhì

41Ọmọ Étínì,

41ọmọ Ṣéráhì, ọmọ Ádáyà,

42Ọmọ Étanì, ọmọ Ṣímáhì,

42ọmọ Ṣíméhì,

43Ọmọ Jáhátì,

43ọmọ Gérísíónì, ọmọ Léfì;

44láti ìbákẹ́gbẹ́ wọn, àwọn ará Mérárì wà ní ọwọ́ òsì Rẹ̀: ọmọ Málúkì,

44Étanì ọmọ Kísì, ọmọ Ábídì,

45Ọmọ Háṣábíáhì

45ọmọ Ámásáyà, ọmọ Hítíkíáhì,

46Ọmọ Ámíṣì ọmọ Bánì,

46ọmọ Ṣémérì,

47Ọmọ Máhílì, ọmọ Léfì.

47ọmọ Múṣì, ọmọ Mérárì,

48Àwọn Léfì ẹgbẹ́ wọn ni wọn yan àwọn iṣẹ́ yókù ti Àgọ́ fún, èyí tí í ṣe ilé Ọlọ́run.

49Ṣùgbọ́n Árónì àti àwọn ìran ọmọ Rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ọrẹ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a se ní ibi mímọ́ jùlọ. Ṣíṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti paláṣẹ.

50Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Árónì: Élíásérì ọmọ Rẹ̀. Fínéhásì ọmọ Rẹ̀, Ábísúà ọmọ Rẹ̀,

51Búkì ọmọ Rẹ̀,

51Húṣì ọmọ Rẹ̀. Ṣéráhíà ọmọ Rẹ̀,

52Méráíótì ọmọ Rẹ̀, Ámáríyà ọmọ Rẹ̀,

52Áhítúbì ọmọ Rẹ̀,

53Ṣádókù ọmọ Rẹ̀

53àti Áhímásì ọmọ Rẹ̀.

54ⓑ Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbégbé wọn (tí a fi lé àwọn ìran ọmọ Árónì lọ́wọ́ tí ó wá láti ẹ̀yà Kóhátítè, nítorí kèké alákọ́kọ́ jẹ́ ti wọn):

55A fún wọn ní Hébírónì ní Júdà pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ Rẹ̀.

56Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún kelẹ́bù ọmọ Jéfúnénì.

57Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Árónì ni a fún ní Hébírónì (ìlú ti ààbò), àti Líbínà, Játírì, Éṣitémóà,

58Hílénì Débírì,

59Áṣánì, Júlà àti Bétí-Ṣéméṣì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ Rẹ̀.

60Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Béńjámínì, a fún wọn ní Gíbíónì, Gébà, Álémétì àti Ánátótì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

60Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrin àwọn ẹ̀yà kóháhítè jẹ́ mẹ́talá ní gbogbo Rẹ̀.

61Ìyòókù àwọn ìran ọmọ Kóháhítì ní a pín ìlú mẹ́wá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè.

62Àwọn ìran ọmọ Géríṣómù, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Íṣákárì, Áṣérì àti Náfítalì, àti láti apá ẹ̀yà Mánásè tí ó wà ní Básánì.

63Àwọn ìran ọmọ Mérárì, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Gádì àti Ṣébúlúní.

64Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún àwọn ará Léfì ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

65Láti ẹ̀yà Júdà, Síméónì àti Bẹ́ńjámínì ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún.

66Lára àwọn ìdílé Kóhátì ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Éfúráímù gẹ́gẹ́ bí ìlú agbégbé wọn.

67Ní òkè orílẹ̀ èdè Éfíráímù, a fún wọn ní Ṣékémù (Ìlú ńlá ti ààbò), àti Géṣérì

68Jókíméámù, Bétì-Hórónì.

69Áíjálónì àti Gátì Rímónì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

70Pẹ̀lú láti apá ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún Ádérì àti Bíléámù lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn, fún ìyókù àwọn ìdílé Kóhátítè.

71Àwọn ará Géríṣónítè gbà nǹkan wọ̀nyí: Láti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Mánásè wọ́n gba Gólánì ní Básánì àti pẹ̀lú Áṣítarótì, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù wọn;

72Láti ẹ̀yà Ísákárì

72wọ́n gba Kádéṣì, Dábérátì

73Rámótì àti Ánénù, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn;

73

74Láti ẹ̀yà Áṣérì

74wọ́n gba Máṣálì Ábídónì,

75Húkokì àti Réhóbù lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn;

75

76Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Náfítalì

76wọ́n gba Kédésì ní Gálílì, Hámoníà Kíríátaímù, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

77Àwọn ará Mérárì (ìyókù àwọn ará Léfì) gbà nǹkan wọ̀nyí: wọ́n gba Jókíneámù, Kárítahì, Rímónò àti Tábórì, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn;

77Láti ẹ̀yà Sébúlúnì

78Láti ẹ̀yà Rúbẹ́nì rékọjá Jódánì ìlà oòrùn Jẹ́ríkò

78wọ́n gba Bésérì nínú ihà Jáhíṣáhì,

79Kédémótì àti Méfátù, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko, tútù wọn;

79

80Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gádì

80wọ́n gba Rámóà ní Gílíádì Máhánáímù,

81Hésíbónì àti Jáṣérì lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.

article>