Ìwé Kíróníkà Kìn-ín-ní 7:1-40 BYB2014 - Bible AI

1Àwọn ọmọ Ísákárì: Tólà, Púà, Jáṣúbù àti Ṣímírónì, Mẹ́rin ni gbogbo Rẹ̀.

2Àwọn ọmọ Tólà:

2Húsì, Réfáíáhì, Jéríélì, Jámáì, Jíbísámù àti Ṣámúẹ́lì Olórí àwọn ìdílé wọn. Ní àkókò ìjọba, Dáfídì, àwọn ìran ọmọ Tólà tò lẹ́sẹsẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin alágbára ní ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé ẹgbẹ̀ta (22,600).

3Àwọn ọmọ, Húṣì: Àwọn ọmọ Ísíráhíà: Míkáélì Ọbádáyà, Jóẹ́lì àti Ísíhíáhì. Gbogbo àwọn máràrùn sì jẹ́ olóyè.

3Ísíráhíà.

4Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n ní ọkùnrin ẹgbàá mérìndínlógójì tí ó ti ṣe tan fún ogun, nítorí wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ àti ìyàwó

4

5Àwọn ìbátan tí ó jẹ́ alágbára akọni àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ti àwọn ìdílé Ísákárì, bí a ti tò ó lẹ́sẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlàádórin ni gbogbo Rẹ̀.

5

6Àwọn ọmọ mẹ́ta Bẹ́ńjámínì:

6Bélà, Békérì àti Jédíáélì.

7Àwọn ọmọ Bélà:

7Éṣíbónì, Húṣì, Ísíélì, Jérómótì àti Írì, àwọn máràrùnún. Awọn ni olórí ilé baba ńlá wọn, akọni alágbára ènìyàn. A sì ka iye wọn nípa ìran wọn sí ẹgbàámọ́kànlá-ó-lé-mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ènìyàn (22,034)

8Àwọn ọmọ Békérì:

8Ṣémíráhì, Jóáṣì, Élíásérì, Élíóénáì, omírì, Jeremótù Ábíjà, Ánátótì àti Álémétì Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ọmọ Békérì

9Ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn tí a kọ lẹ́sẹsẹ jẹ́ ti àwọn olórí ìdílé àti ẹgbẹ̀rún-ní ọ̀nà ogún-ó-lé nígba (20,200) Ọkùnrin alágbára

9

10Ọmọ Jédíáélì: Àwọn ọmọ Bílíhánì: Jéúṣì Bẹ́ńjámínì, Éhúdì, Kénánà Ṣétanì, Tárí-Ṣíṣì àti Áhísáhárì.

10Bílíhánì.

11Gbogbo àwọn ọmọ Jédíádì jẹ́ olórí ìdátan Àwọn ẹgbẹ̀rúnmẹ́tadínlógún-ó-lé-nígba akọni ọkùnrin ni ó ti ṣetan láti jáde lọ sí ogun.

11

12Àwọn ará Ṣúpímè àti Húpímù jẹ́ àwọn atẹ̀lé fún Írì, àwọn ìran ọmọ Áhérì.

12

13Àwọn ọmọ Náfítalì:

13Jáhíṣíẹ́lì, Gúnì, Jésérì àti Ṣílémù—ọmọ Rẹ̀ nípa Bílíhà.

14Àwọn ìran ọmọ Mánásè:

14Ásíríélì jẹ́ ìran ọmọ Rẹ̀ nípa sẹ̀ àlè Rẹ̀ ará Árámù ó bí Mákírì baba Gílíádì.

15Mákírì sì mú ìyàwó láti àárin àwọn ará Hípímù àti Ṣúpímù. Orúkọ arábìnrin Rẹ̀ a má a jẹ́ Máákà.

15Orúkọ ìran ọmọ mìíràn a má a jẹ́ Ṣélóféhádì, tí ó ní àwọn ọmọbìnrin nìkan ṣoṣo.

16Máákà, ìyàwó Mákírì bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ orúkọ Rẹ̀ ní Pérésì. Ó sì pe arákùnrin Rẹ̀ ní Ṣéréṣì, àwọn ọmọ Rẹ̀ sì ní Úlámù àti Rákémù.

16

17Ọmọ Úlámù: Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gílíádì ọmọ Mákírì, ọmọ Mánásè.

17Bédánì.

18Arábìnrin Rẹ̀. Hámólékétì bí Ṣíhódì, Ábíésérì àti Máhíláhì.

18

19Àwọn ọmọ Ṣémídà sì jẹ́:

19Áhíánì, Ṣékémù, Líkì àti Áníámù.

20Àwọn ìran ọmọ Éfíráímù: Táhátì ọmọ Rẹ̀, Éléádáhì ọmọ Rẹ̀.

20Ṣútéláhì, Bérédì ọmọkùnrin Rẹ̀,

21Táhátì ọmọ Rẹ̀ Ṣábádì ọmọ, Rẹ̀, Éṣérì àti Éléádì ni a pá nípaṣẹ̀ àwọn ọkùnrin bíbí ìbílẹ̀ Gátì Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ fi agbára mú ohun ọ̀sìn wọn

21àti Ṣútéláhì ọmọ Rẹ̀.

22Éfíráímù baba wọn sọ̀fọ̀ fún wọn ní ọjọ́ púpọ̀, àwọn ìbátan Rẹ̀ wá láti tù ú nínú.

23Nígbà náà, ó sùn pẹ̀lú, ìyàwó Rẹ̀, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ ọ́ ní Béríà nítorí òfò ti wà nínú ìdílé náà.

24Ọmọbìnrin Rẹ̀ sì jẹ́ Ṣárà, ẹni tí ó kọ́ ìsàlẹ̀ àti òkè Bétí-Hórónì àti Úṣénì sérà pẹ̀lú.

25Réfà jẹ́ ọmọ Rẹ̀, Rẹ́sẹ́fì ọmọ Rẹ̀, Télà ọmọ Rẹ̀, Táhánì ọmọ Rẹ̀,

26Ládánì ọmọ Rẹ̀ Ámíhúdì ọmọ Rẹ̀,

26Élíṣámà ọmọ Rẹ̀,

27Núnì ọmọ Rẹ̀

27àti Jóṣúà ọmọ Rẹ̀.

28Ilẹ̀ wọn àti ìfìdíkalẹ̀ wọn ni Bétélì àti àwọn ìletò tí ó yíká, Náránì lọ sí ìhà ìlà oòrùn, Géṣérì àti àwọn ìletò Rẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn àti Ṣékémù àti àwọn ìletò Rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Áyáhì àti àwọn ìletò.

29Lẹ́gbẹ̀ ìpínlẹ̀ ti Mánásè ni Bétí ṣánì, Tánákì, Mógídò àti Dórì lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìletò Rẹ̀. Àwọn ìran ọmọ Jóṣẹ́fù ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé nínú ìlú wọ̀nyí.

30Àwọn ọmọ Ásérì: Ímíná, Ísúa, Ísúáì àti Béríá. Arábìnrin wọn sì jẹ́ Ṣérà.

31Àwọn ọmọ Béríá:

31Hébérì àti Málíkíélì, tí ó jẹ́ baba Bírísáítì.

32Hébérì jẹ́ baba Jáfílétì, Ṣómérì àti Hótamì àti ti arábìnrin wọn Ṣúà.

32

33Àwọn ọmọ Jáfílétì: Wọ̀n yí ni àwọn ọmọ Jáfílétì.

33Pásákì, Bímíhátì àti Ásífátì.

34Àwọn ọmọ Ṣómérì:

34Áhì, Rógà, Jáhúbà àti Árámù.

35Àwọn ọmọ arákùnrin Rẹ̀ Hélémù

35Ṣófà, Ímínà, Ṣélésì àti Ámálì.

36Àwọn ọmọ Ṣófáhì:

36Ṣúà, Háníférì, Ṣúálì, Bérì Ímírà.

37Béṣérì Hódì, Ṣámà, Ṣílísà, Ítíránì àti Bérà.

37

38Àwọn ọmọ Jétérì:

38Jéfúnè Písífà àti Árà.

39Àwọn ọmọ Úlà:

39Árà Háníélì àti Résíà.

40Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ìran ọmọ Áṣérì olórí ìdílé, àwọn okùnrin tí a yàn àwọn ògbóyà jagunjagun àti àwọn adarí tí ó dúró sinsin. Iye àwọn ọkùnrin tí ó setan fún ogun, gẹ́gẹ́ bí à ti se kọ ọ́ lẹ́sẹsẹ nínú ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.

article>