1Bẹ́ńjámínì jẹ́ bàbá Bélà àkọ́bí Rẹ̀, Áṣíbélì ọmọkùnrin ni ẹ̀ẹ̀kejì, Áhárá ẹ̀ẹ̀kẹ́ta,
2Nóhà ẹ̀ẹ̀kẹrin àti Ráfà ẹ̀ẹ̀karùnún.
3Ádárì, Gérà, Ábíhúdì,
4Ábísúà, Námánì, Áhóà,
5Gérà, Ṣéfúfánì àti Húrámù.
5
6Wọ̀nyí ni àwọn ìran ọmọ Éhúdì, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé tí ó ń gbé ní Gébà tí a sì lé kúrò lọ sí Mánáhátì:
6
7Námánì Áhíjà àti Gérà, tí ó lé wọn kúrò ní ìlú, àti tí ó sì jẹ́ baba Úṣà àti Áhíhúdù.
7
8A bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣáháráímù ní Móábù lẹ́yìn tí ó ti kọ àwọn ìyàwó Rẹ̀ sílẹ̀, Húṣímù àti Báárà.
9Nípaṣẹ̀ ìyàwó Rẹ̀ Hódéṣì ó ní Jóbábù ṣíbíà, Méṣà, Málíkámà,
10Jéúṣì Ṣákíà àti Mírímà. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Rẹ̀, olórí àwọn ìdílé.
11Nípaṣẹ̀ Húṣímù ó ní Ábítúbù àti Élípálì.
12Ébérì, Míṣámì, Ṣémédù (ẹni tí ó kọ́ Ónò àti Lódì pẹ̀lú àwọn ìletò àyíká Rẹ̀.)
13Pẹ̀lú Béríà àti Ṣémà, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé ti àwọn tí ó ń gbé ní Áíjálónì àti àwọn tí ó lé àwọn olùgbé Gátì kúrò.
13
14Áhíò, Ṣásákì Jérémílò,
15Ṣébádíà, Árádì, Édérì
16Míkáélì Íṣífà àti Jóhà jẹ́ àwọn ọmọ Béríà.
16
17Ṣébàdíáhì, Mésúlámù Hésékì, Hébérì
18Íṣíméráì, Íṣílíáhì àti Jóbábì jẹ́ àwọn ọmọ Élípálì.
18
19Jákímì, Ṣíkírì, Ṣábídì,
20Élíénáì Ṣílétaì Élíélì,
21Ádáyà, Béráíáhì àti Ṣímírátì jẹ́ àwọn ọmọ, Ṣíméhì.
21
22Íṣípánì Ébérì, Élíélì,
23Ábídónì, Ṣíkírì, Hánánì,
24Hánáníyà, Élámù, Ánítótíjáhì,
25Ífédíà Pénúélì jẹ́ àwọn ọmọ Ṣásákì.
25
26Ṣámíséráì, Ṣéháríà, Átalíà
27Járéṣíà Élíjà àti Ṣíkírì jẹ́ àwọn ọmọ Jéróhámù.
27
28Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn ìdílé, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ó lẹ́sẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù.
28
29Jélíélì, baba a Gíbíónì ń gbé ní Gíbíónì.
29Ìyáwó o Rẹ̀ a má jẹ́ Mákà,
30Àkọ́bí Rẹ̀ a sì má a jẹ́ Ábídónì wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Ṣúrì, Kíṣì, Báláhì, Nérì, Nádábù,
31Gédórì Áhíò, Ṣékérì
32Pẹ̀lú Míkílótì, tí ó jẹ́ bàbá Ṣíméà. Wọ́n ń gbé lébá ìbátan wọn ní Jérúsálẹ́mù.
32
33Mérì jẹ́ baba Kíṣì, Kíṣì baba Ṣọ́ọ̀lù àti Ṣọ́ọ̀lù baba Jónátanì, Málìkíṣúà, Ábínádábù àti Ésíbálì.
34Méríbáì tí ó jẹ́ baba Míkà.
35Àwọn ọmọ Míkà:
35Pítónì, Mélékì, Táréà, àti Áhásì.
36Áhásì jẹ́ bàbá a Jéhóádá, Jéhóádá jẹ́ baba a Álémétì Áṣíméfétì àti Ṣímírì, Ṣímírì sì jẹ́ baba a Móṣà.
37Móṣà jẹ́ baba a Bínéà; Ráfà sì jẹ́ ọmọ Rẹ̀, Éléásà ọmọ Rẹ̀ àti Áṣélì ọmọ Rẹ̀.
37
38Áṣélì ní ọmọ mẹ́fà pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn:
38Áṣíríkámù, Bókérù, Íṣímáélì, Ṣéáríà, Ọbádáyà àti Hánánì. Gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Áṣélì.
39Àwọn ọmọ arákùnrin Rẹ̀ Éṣékì:
39Úlámù àkọ́bí Rẹ̀, Jéúṣì ọmọkùnrin ẹ̀ẹ̀kejì àti Élífélétì ẹ̀ẹ̀kẹ́ta.
40Àwọn ọmọ Úlámù jẹ́ ògboyà jagunjagun tí ó lè gbá orin mú. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin àti ọmọ ọmọkùnrin márùndínlọ́gọ́jọ ní gbogbo Rẹ̀.
40Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ìran ọmọ Bẹ́ńjámínì.