1
2Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yí wá sí ọ̀dọ̀ Ṣémáíà ènìyàn Ọlọ́run:
3“Wí fún Rehóbóámù ọmọ Sólómónì ọba Júdà, sí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì,
4‘Èyí ní ohun tí OLÚWA wí. Ẹ má ṣe gòkè lọ lati lọ jà pẹ̀lú arákùnrin yín, ẹ lọ sílé, gbogbo yín, nítorí ti ìṣe mi nìyí.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì padà sẹ́yìn láti yan lọ dojúkọ Jéróbóámù.
5Réhóbóámù ń gbe ní Jérúsálẹ́mù ó sì kọ́ àwọn ìlú fún ààbò ní Júdà.
6Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Étamì, Tẹ́kóà,
7Beti-Súrì, sókò, Ádúlámù
8Gátì, Maréṣálù Ṣífì,
9Ádóráímù, Lákíṣì, Áṣékà
10Ṣórà, Áíjálónì, àti Hébírónì. Wọ̀nyí ni àwọn ìlu ìdábòbò ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì.
11Ó sì mú àwọn ìlú olódi lágbára, ó sì fi àwọn balógun sínú wọn àti àkójọ oúnjẹ, àti òróró àti ọtí wáìnì.
12Àti ní olúkúlùkù ìlú ni ó fi àsà àti ọ̀kọ̀ sí, ó sì mú wọn lágbára gidigidi, ó sì ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì lábẹ́ rẹ̀.
13Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì, láti gbogbo ẹ̀yà wọn jákè jádò Ísírẹ́lì wà ní ẹ̀bá rẹ̀.
14Àwọn ará Léfì fi ìgbéríko sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Júdà àti Jérúsálẹ́mù nítorí Jéróbóamù àti àwọn ọmọ rẹ̀, ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà OLÚWA.
15Ó sì yan àwọn àlùfáà tirẹ̀ fún àwọn Ibi gíga àti fún ewúrẹ́ àti àwọn òrìṣà ti a gbẹ́ tí o ti ṣẹ̀.
16Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí wọ́n fi ọkàn wọn fún wíwá OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tẹ̀lé àwọn ará Léfì lọ sí Jérúsálẹ́mù láti lọ rúbọ sí OLÚWA Ọlọ́run bàbá a wọn.
17Ó fún ìjọba Júdà ní agbára, ó sì ti Réhóbóámù ọmọ Sólómónì lẹ́yìn fún ọdún mẹ́ta nítorí ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi rìn ní ọ̀nà ti Dáfídì àti Sólómónì ní àkókò yí.
18Réhóbóámù fẹ́ Máhálátì tí ó jẹ́ ọmọbìnrin ọmọkùnrin Dáfídì Jérímótì àti ti Ábíháílì, ọmọbìnrin ọmọkùnrin ti Jésè Élíábì.
19Ó bí àwọn ọmọ fún un: Jéúṣì, Ṣémáríà àti Ṣáhámì.
20Nígbà náà ó fẹ́ Mákà ọmọbìnrin Ábúsálómù, tí ó bí Ábíjà fún Átáì, Ṣíṣà àti Ṣélómítì.
21Réhóbóámù fẹ́ràn Mákà ọmọbìnrin Ábúsálómù ju èyí kejì nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ àti àwọn àlè rẹ̀ lọ. Ní gbogbo rẹ̀, ó ní ìyàwó méjìdínlógún àti ọgọ́ta àlè ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n àti ọgọ́ta ọmọbìnrin.
22Réhóbóámù yan Ábíjà ọmọ Mákà láti jẹ́ olóyè ọmọ aládé láàárin àwọn arákùnrin rẹ̀, kí ó ba à lè ṣe é ní ọba.
23Ó hùwà ọlọ́gbọ́n, nípa fí fọ́nká díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ jákè jádò ká àwọn agbégbé Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti sí gbogbo àwọn ìlú ńlá aláàbò. Ó fún wọn ní ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n fẹ́, ó sì gba ọ̀pọ̀ ìyàwó fún wọn.