Ìwé Kíróníkà Kejì 15:1-19 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Ásáríyà ọmọ Ódédì.

2Ó jáde lọ bá Ásà, ó sì wí fún un pé, “Tẹ́tí si mi Ásà, àti gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì. OLÚWA wà pẹ̀lú rẹ, nígbà tí ìwọ bá wà pẹ̀lú rẹ̀. Ti ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i ní ẹ̀bá rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ silẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

3Fún ọjọ́ pípẹ́ ni Ísírẹ́lì ti wà láì sin Ọlọ́run òtitọ́, àti láìní àlùfáà ti ń kọ́ ni, àti láì ní òfin.

4Ṣùgbọ́n nínú ìpọ́njú wọn, wọ́n yí padà si OLÚWA Ọlọ́run Isírẹ̀lì, wọ́n sì wa kiri. Wọ́n sì ri i ní ẹ̀gbẹ́ wọn.

5Ní ọjọ́ wọ̀nnì ó léwu kí ènìyàn máa rìn ìrìnàjò kiri, nítorí tí gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà wà nínú làálàá ńlá

6Orílẹ̀-èdè kan ń run èkejì àti ìlu kan sí òmíràn nítorí OLÚWA ń yọ wọ́n lẹ́nu pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ìpọ́njú.

7Ṣùgbọ́n fun ìwọ, jẹ́ alágbára, kí ó má sì se sú ọ. Nítorí tí a ó fi èrè sí iṣẹ́ ẹ̀ rẹ”

8Nígbà tí Ásà gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí àti àsọtẹ́lẹ̀ Ásáríyà ọmọ Ódédì wòlíì, ó mú àyà rẹ̀ le. Ó gbé àwọn òrìsà ìkóríra kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti kúrò nínú àwọn ìlú tí ó ti fi agbára mú ní ori òkè Éfúráímù. Ó tún pẹpẹ OLÚWA ṣe tí ó wà ní iwájú Pórífíkò ti ilé OLÚWA

9Nígbà naà, ó pe gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì jọ àti àwọn ènìyàn láti Éfúráímù, Mánásè àti Síméónì tí ó ti ṣe àtìpó ní àárin wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Ísírẹ́lì nigbà tí wọ́n rí i wí pé OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀

10Wọ́n péjọ sí Jérúsálẹ́mù ní oṣù kẹta ọdún kẹẹ̀dógún ti ìjọba Ásà.

11Ní àkókò yìí, wọ́n rúbọ sí OLÚWA ọgọ́rùnún méje akọ màlúù àti ẹgbẹ̀rún ḿéje (7,000) àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ láti ibi ìkogun tí wọ́n ti kó padà.

12Wọ́n sì tún dá májẹ̀mú láti wá OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba wọn tinútinú wọn àti tọkàntọkàn wọn.

13Pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wá OLÚWA Ọlọ́run Isirẹ́lì, pípa ni á ó paá láti ẹni kékeré dé orí ẹni ńlá àti ọkùnrin àti obìnrin.

14Wọ́n sì búra ní ohùn rara fún OLÚWA àti pẹ̀lú ìhó nla àti pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú fèrè.

15Gbogbo Júdà yọ̀ nípa ìbúra náà nítorí wọ́n ti búra tinútinú wọn wọ́n sì fi gbogbo ìfẹ́ inú wọn wá a, wọ́n sì rí i, OLÚWA sì fún wọn ní ìsinmi yí káàkiri

16ⓐ Ọba Ásà rọ ìyá ńlá rẹ̀ Mákà lóyè láti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyá ọba nítorí tí ó ti ṣe òpó Áṣérà tí ń lé ni sá. Ásà gé òpó náà lulẹ̀, wòó, ó sì jóo ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì.

17Ṣùgbọ́n a kò mú àwọn ibi gíga náà kúrò ní Ísírẹ́lì; síbẹ̀síbẹ̀ ọkàn Ásà wà ní pípé ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo.

18Ó sì mú àwọn ohun mímọ́ náà ti baba rẹ̀ àti àwọn ohun mímọ́ ti òun tìkára rẹ̀ tirẹ̀ wá sínú ilé Ọlọ́run, wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò náà.

19Kò sí ogun mọ́ títí fún ọdún márùndínlógójì ti ìjọba Ásà.

cle>