1
2Ó sì fi ogun sínú gbogbo ìlú olódi Júdà ó sì kó ẹgbẹ́ ológun ní Júdà àti nínú ìlú Éfúráímù tí baba rẹ̀ ti gbà.
3OLÚWA sì wà pẹ̀lú Jéhóṣáfátì nítorí, ní ọdún àkọ́kọ́ rẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà ti baba rẹ̀ Dáfídì ti rìn, kò sì fi ọ̀ràn lọ Báálímù.
4Sùgbọ́n ó wá Ọlọ́run baba rẹ̀ kiri ó sì tẹ̀lẹ́ àṣẹ rẹ̀ ju iṣẹ́ Ísírẹ́lì.
5OLÚWA sì fi ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ àkóso rẹ̀, gbogbo Júdà sì mú ẹ̀bùn wá fún Jehóṣáfátì, Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ní ọrọ̀ àti ọlá lọ́pọ̀lọpọ̀.
6Ọkàn rẹ̀ sì gbé sokè si ọ̀nà OLÚWA, pẹ̀lúpẹ̀lù, ó sì mú ibi gíga wọn àti òrìṣà kúrò ní Júdà.
7Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ Bẹni-Háílì, Obádíà Sekaríà, Nètaníélì Míkíà láti máa kọ́ ni nínú ìlú Júdà.
8Wọ́n sì ní díẹ̀ lára àwọn ọmọ Léfì, àní Ṣémáyà, Netaníà, Sebadíà, Ásáélì, Ṣémírámótì, Jéónátanì, Àdóníjà, Tóbíyà àti Tobi-Àdóníjà àti àwọn àlùfáà Élíṣámà àti Jéhórámù.
9Wọ́n ń kọ́ ni ní agbégbé Júdà, wọ́n mú ìwé òfin OLÚWA dání, wọ́n sì rìn yíká gbogbo àwọn ìlú Júdà wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.
10Ìbẹ̀rù OLÚWA bà lórí gbogbo ìjọba ilẹ̀ tí ó yí Júdà ká, débi pé wọn kò bá Jéhóṣáfátì jagun.
11Lára àwọn ará Fílístínì, mú ẹ̀bùn fàdákà gẹ́gẹ́ bí owó ọba wá fún Jéhóṣáfátì, àwọn ará Árábíà sì mú ọ̀wọ́ ẹran wá fún-un, ẹgbàrin ó dín ọ̀dúnrún àgbò àti ẹgbarìndín ní ọ̀ọ́dúnrún òbúkọ.
12Jéhóṣáfátì sì ń di alágbára nínú agbára síi, ó sì kọ́ ilé olódi àti ilé ìsúra púpọ̀ ní Júdà
13Ó sì ní ìṣúra ní ìlu Júdà. Ó sì tún ní àwọn alágbára jagunjagun akọni ọkùnrin ní Jérúsálẹ́mù.
14Iye wọn gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn nì wọ̀nyí:
15
16
17
18
19Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ń dúró níwáju ọba, ní àyíká àwọn ẹni tí ó fi sínú ìlú olódi ní àyíká gbogbo Júdà.