1
2Àwọn ará kùnrin Jéhóramù ọmọ Jéhóṣáfatì jẹ́ Áṣáríyà, Jèhíeli, Ṣekárià. Ásáríyàhù, Míkáélí àti Ṣefátíá. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jéhóṣafátì ọba Ìsírẹlì.
3Baba wọn ti fún wọn ní ẹ̀bun púpọ̀ ti fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò iyebíye pẹ̀lú àwọn ìlú ààbò ní Júdà, Ṣùgbọ́n, ó ti gbé ìjọba fún Jéhóramù nítori òun ni àkọ́bí ọmọkùnrin.
4Nígbà tí Jéhórámù fi ara rẹ̀ lélẹ̀ gidigidi lórí ìjọba baba a rẹ̀, ó pa gbogbo àwọn arákùrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìrin ọba Ìsirẹ́lì.
5
6Ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìdílé Áhábù ti ṣe, nítorí ó fẹ́ ọmọbìrin Áhábù. Ó ṣe búburú lójú OLÚWA.
7Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nítorí tí májẹ̀mú tí OLÚWA ti dá fún Dáfídì kì í ṣe ífẹ́ OLÚWA láti pa ìdílé Dáfídì run ó ti ṣe ìlérí láti tọ́jú fìtílà kan fún un àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ títí láé.
8Ní àkókò Jéhórámù, Édómù ṣọ̀tẹ̀ sí Júdà, wọ́n sì gbé ọba tiwọn kalẹ̀.
9Bẹ́ẹ̀ ni, Jéhórámù lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́. Àwọn ará Édómù yí i ká àti àwọn alákóso àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó dìde ní òru ó sì sẹ́gun wọn ní òru.
10Títí di ọjọ́ òní ni Édómù ti wà ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Júdà.
11Òun pẹ̀lú ti kọ́ àwọn ibi gíga lórí àwọn òkè Júdà. Ó sì ti fà á kí àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù ó se àgbérè pẹ̀lú ara wọn. Ó sì ti jẹ́ kí wọn ó ṣáko lọ.
12Jóhórámì gba ìwé láti ọwọ́ Èlíjà wòlíì, tí ó wí pé:
13Ṣùgbọ́n ìwọ ti rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì, ìwọ sì ti tọ́ Júdà àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì láti ṣe àgbèrè sí ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti ṣe. Ìwọ sì ti pa àwọn arákùnrin rẹ, ẹ̀yà ara ilé bàbá à rẹ, àwọn ọkùnrin tí ó dára jù ọ́ lọ.
14Bẹ́ẹ̀ ni nísinsìn yìí, Ọlọ́run ti fẹ́rẹ́ lu àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìyàwó rẹ àti gbogbo ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn ńlá.
15Ìwọ tìkalára yóò ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú Àìsàn lílọ́ra ti ìfun, títí tí àìsàn náà yóò fi jẹ́ kí àwọn ìfun rẹ jáde sí ìta.’ ”
16OLÚWA ru ìbínú àwọn, ará Fílístínì àti àwọn Árábù tí wọ́n ń gbé ní Ẹ̀bá àwọn ará Kúsì.
17Wọ́n dojú ìjà kọ Júdà, wọ́n gbàá, wọ́n sì kó gbogbo ọrọ̀ tí a rí ní ilé ọba pẹ̀lú, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin kankan kò kù sílẹ̀ fún un bí kò ṣe Áhásáyà, tí ó kéré jùlọ.
18Lẹ́yìn gbogbo èyí, OLÚWA jẹ Jéhórámù níyà pẹ̀lú àrùn tí kò ṣeé wò sàn ti ìfun.
19Ní àkókò kan ní ìparí ọdún kejì, àwọn ìfun rẹ̀ jáde nítorí àrùn náà ó sì kú nínu ìrora ńlá. Àwọn Ènìyàn rẹ̀ kò dá iná láti fi bọlá fún un, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe fún àwọn baba a rẹ̀.
20