1
2Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLÚWA, ṣùgbọ́n kì í ṣe tọkàntọkàn.
3Lẹ́yìn tí ìjọba ti wà ní ìdarí rẹ̀, ó pa àwọn onísẹ́ tí ó pa baba rẹ̀ ọba.
4Síbẹ̀ kò pa àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n ó ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ nínú òfin nínú ìwé Mósè, níbi tí OLÚWA ti paláṣẹ pé: “A kò gbọdọ̀ pa àwọn baba fún àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn ọmọ fún baba wọn; Olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”
5Ámásíà, pe gbogbo àwọn ènìyàn Júdà pọ̀, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn sí àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọrọrún fún gbogbo Júdà àti Bẹńjámínì, ó sì gbá iye wọn láti ẹni ogún ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ jọ, ó sì ríi pé ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dógún (300,000) àwọn ọkùnrin ni ó ti múra fún ìsìn ogun, tí ó lè gbá ọ̀kọ̀ àti àpáta mú.
6Ó sì yá (100,000) ọ̀kẹ́ márùn-ún àwọn ọkùnrin oníjà láti Ísírẹ́lì fún ọgọ́rùn-ún mẹ́wàá àwọn talẹ́ntì fàdákà.
7Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ ọ́ wá ó sì wí pé, “Ọba, àwọn ọ̀wọ́-ogun láti Ísírẹ́lì kò gbọdọ̀ yan pẹ̀lú rẹ, nítorí tí OLÚWA kò wà pẹ̀lú Ísírẹ́lì kì í ṣe pẹ̀lú ẹnìkankan láti Éfíráímù.
8Àní, tí ẹ bá lọ jà pẹ̀lú ìmúláyàle ní ojú ogun, Ọlọ́run yóò bì ọ́ subú níwájú àwọn ọ̀tá, nítorí OLÚWA ní agbára láti ràn ọ́ lọ́wọ́ àti láti bì ọ́ ṣubú.”
9Ámásíà sì bi ènìyàn Ọlọ́run pé, “Ọgọ́rùnún tálẹ́ntì tí mo ti san fún àwọn ọ̀wọ́-ogun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kọ́?”
10Bẹ́ẹ̀ ni Ámásíà, tú àwọn ọwọ́ ogun tí ó ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Éfíráimù ká. Ó sì rán wọn lọ lé. Wọ́n kún fún ìbínú pẹ̀lú Júdà, wọ́n sì padà lọlé pẹ̀lu ìbínú ńlá.
11
12Àwọn ọkùnrin Júdà pẹ̀lú fi agbára mú àwọn ọkùnrin ẹgbẹ̀rún mẹ́wá láàyè. Wọ́n mú wọn lọ sí orí òkè bèbè òkúta, wọ́n jù wọ́n sílẹ̀, kí gbogbo wọn sì fọ́ sí wẹ́wẹ́.
13Ní báyìí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí Ámásíà ti rán lọ padà, tí wọn kò nípa nínú ogun gbógun sí àwọn ìlú Júdà láti Saaríà sí Bẹti-Hórónì. Wọ́n pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta nínú wọn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ìkógun ńlá.
14Nígbà tí Ámásíà padà ní ibi pípa àwọn ará Édómù, ó mú àwọn Ọlọ́run àwọn ènìyàn Séírì padà wá. Ó gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àwọn Ọlọ́run tirẹ̀. Ó tẹríba fún wọn, ó sì rúbọ fún wọn.
15Ìbínú OLÚWA ru sí Ámásíà, ó sì rán wòlíì kan sí i, tí ó wí pé, “kí ni ó dé tí ìwọ fi ń bèrè lọ́wọ́ àwọn Ọlọ́run àwọn ènìyàn yìí, tí wọn kò le gba àwọn ènìyàn ti wọn kúrò lọ́wọ́ rẹ?”
16Bí ó ti n sọ̀rọ̀, ọba wí fún un pé, “Ṣé a yàn ọ́ ní olùgbà ọba lámọ̀ràn ni? Dúró! Èéṣe tí a ó fi lù ọ́ bolẹ̀?”
17
18Ṣùgbọ́n Jéhóáṣì ọba Ísírẹ́lì fèsì padà sí Ámásíà ọba Júdà pé, “Òṣùṣù kan ní Lẹ́bánónì rán isẹ́ sí òpépé (igi) ní Lẹ́bánónì, fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwo. Nígbà náà, ẹhànnà ẹranko ènìyàn ni Lébánónì wá, ó sì tẹ òṣùṣù náà lábẹ́ ẹsẹ̀.
19Ìwọ wí fún ara à rẹ wí pé, ìwọ ti ṣẹ́gun Édómù àti nísinsin yìí ìwọ ní ìrera àti ìgbéraga. Ṣùgbọ́n dúró ní ilé! Kí ni ó dé tí o fi n wá wàhálà tí o sì fi ń fa ìṣubú rẹ àti ti Júdà pẹ̀lu?”
20Ámásíà, bí ó tì wù kí ó rí kò ní tẹ́tí nítorí Ọlọ́run ṣe é kí ó lè gbé wọn lé Jéhóásì lọ́wọ́: nítorí wọ́n wá àwọn ọlọ́run Édómù.
21Bẹ́ẹ̀ ni Jóásì, ọba Ísírẹ́lì: òun àti Ámásíà ọba Júdà dojúkọ ara wọn ní Bẹti Ṣeméṣì ní Júdà.
22Àwọn ọmọ Ísirẹ́lì da Júdà rú, gbogbo olúkúlùkù ènìyàn sì sálọ sí ìlú rẹ̀.
23Jóásì ọba Ísírẹ́lì fi agbára mú Áhásáyà ọba Júdà, ọmọ Jóáṣì ọmọ Áhásáyà ní Bétì Ṣéméṣì. Nígbà náà Jóásì mú u wá sí Jérúsálẹ́mù. Ó sì wó ògiri Jérúsálẹ́mù lulẹ̀ láti ẹnu ọ̀nà Éfíráímù sí igun ẹnu ọ̀nà apá kan títí ń lọ sí ọgọ́rùnún mẹ́fà ẹsẹ̀ bàtà ní gígùn.
24Ó kó gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò tí wọ́n rí ni ile Ọlọ́run tí ọ́ wà ní àbojútó Obedi Édómù, lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣura ààfin àti àwọn ìdógó, ó sì padà sí Saaríà.
25
26Fún ti iṣẹ́ mìíràn ti ìjọba Ámásíà láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé àwọn ọba Júdà àti Ísírẹ́lì?
27Láti ìgbà tí Ámásíà ti yípadà kúrò láti máa tẹ̀lé OLÚWA, wọ́n dìtẹ̀ síi ní Jérúsálẹ́mù, ó sì sálọ sí Lákíṣì ṣùgbọ́n, wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e lọ sí Lákiṣì, wọ́n sì paá síbẹ̀.
28A gbé e padà pẹ̀lú ẹsin. A sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Júdà.