1
2Ó bẹ̀rẹ̀ sí kíkọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kejì oṣù kejì ní ọdún kẹ́rin ìjọba rẹ̀.
3Ìpìlẹ̀ tí Sólómónì gbé kalẹ̀ fún kíkọ́ ilé Ọlọ́run jẹ́ ọgọ́ta gígùn ìgbọ̀nwọ́ àti ogún fífẹ̀ ìgbọ̀nwọ́ (lílo ìgbọ̀nwọ́ tí tẹ́lẹ̀)
4Ìloro tí ó wà níwájú ilé OLÚWA náà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́.
5Ó fi igi fírì bo ilé yàrá ńlá náà ó sì bòó pẹ̀lú kìkì wúrà, ó sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú igi ọ̀pẹ àti àwòrán ẹ̀wọ̀n.
6Ó se ilé OLÚWA náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú òkúta iyebíye. Góòlù tí ó lò jẹ́ wúrà párifáímù.
7Ó tẹ́ àjà ilé náà pẹ̀lú ìtí igi àti ìlẹ̀kùn ògiri àti àwọn ìlẹ̀kùn ilé OLÚWA Pẹ̀lú wúrà, ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù sára ògiri.
8Ó kọ́ ibi mímọ́ jùlọ, gígùn rẹ̀ bá fífẹ̀ ilé OLÚWA mu, ogún ìgbọ̀nwọ́ fún gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú ọgọ́rin mẹ́fà talẹ́ntì ti wúrà dáradára.
9Ìwọn àwọn ìṣó náà jẹ́ àádọ́ta Ṣékélì. Ó tẹ́ àwọn apẹ òkè pẹ̀lú wúrà.
10Ní ibi mímọ́ jùlọ, ógbẹ́ àwòrán igi kérúbù kan, ó sì tẹ́ wọn pẹ̀lú wúrà.
11Iye ìyẹ́ apá ìbú atẹ́lẹwọ́ lápapọ̀ ní ti kérúbù, jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ọ̀kan nínú ìyẹ́ apá ti kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé OLÚWA. Nígbà tí ìyẹ́ apa kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-un ní gígùn ó sì, farakan ìyẹ́ apá kérúbù mìíràn.
12Ní ìjọra, ìyẹ́ apá kan ní ti kérúbù kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé OLÚWA mìíràn; ìyẹ́ apá rẹ̀ mìíràn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ní gígùn pẹ̀lú. Tí ó farakan ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́.
13Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù wọ̀nyìí gbà tó ogún ìgbọ̀nwọ́. Wọ́n dúró ní ẹsẹ̀ wọn, wọ́n kọjú sí yàrá pàtàkì ńlá naà.
14
15
16Ó ṣe ẹ̀wọ̀n tí a hun wọ inú ara wọn, ó gbé wọn ká orí òpó náà. Ó ṣe ọgọ́rin Pomígíránátìo (orúkọ èso igi) ó sì so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n náà
17Ó gbe òpó náà dúró níwájú ilé OLÚWA, ọ̀kan sí gúsù, pẹ̀lú ọ̀kan sí àríwá. Èyí ti gúsù, ó ṣe ní Jákínì àti èyí ti àríwá, ó ṣe ní Bóásì.