1Hésékíà sì ránsẹ́ sí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà, ó sì kọ ìwé sí Éfúráímù àti Mánásè, kí wọn kí ó wá sínú ilé OLÚWA ní Jérúsálẹ́mù láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
2Nítorí tí ọba ti gbìmọ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo ìjọ ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù, láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní oṣù kejì.
3Nítorí wọn kò lè pa á mọ́ ní àkókò náà, nítorí àwọn àlùfáà kò tí i ya ara wọn sí mímọ́ tó; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò tí ì kó ara wọn jọ sí Jérúsálẹ́mù.
4Ọ̀ràn náà sí tọ́ lójú ọba àti lójú gbogbo ìjọ ènìyàn.
5Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi àṣẹ kan lélẹ̀, láti kéde ká gbogbo Ísírẹ́lì láti Beerí-sébà àní títí dé Dánì, láti wá pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì ní Jérúsálẹ́mù: nítorí wọn kò pa á mọ́ ní ọjọ́ púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́.
6Bẹ́ẹ̀ àwọn oníṣẹ tí ń sáré lọ pẹ̀lú ìwé láti ọwọ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ sí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà; àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, wí pé:
7Kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe dàbí àwọn baba yín, àti bí àwọn arákùnrin yín tí ó dẹ́sẹ̀ sí OLÚWA, Ọlọ́run àwọn baba wọn, nítorí náà ní ó ṣe fi wọ́n fún ìdahoro bí ẹ̀yin ti rí.
8Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin kí ó má se ṣe ọlọ́rùn líle, bí àwọn baba yín, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ara yín lọ́wọ́ fún OLÚWA, kí ẹ sì wọ inú ibi mímọ́ rẹ̀ lọ, ti òun ti ìyà sí mímọ́ títí láé: Kí ẹ sì sin OLÚWA, Ọlọ́run yín kí ìmúná ìbínú rẹ̀ kí ó lè yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ yín.
9Nítorí bí ẹ̀yin bá tún yípadà sí OLÚWA, àwọn arákùnrin yín, àti àwọn ọmọ yín, yóò rí àánú níwájú àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, kí wọn kí ó lè tún padà wá sí ilẹ̀ yí: nítorí OLÚWA Ọlọ́run yín, oníyọ́nú àti aláàánú ni, kì yóò sì yí ojú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ yín, bí ẹ̀yin bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀.”
10Bẹ́ẹ̀ ni àwọn onísẹ́ náà kọjá lati ìlú dé ìlú, ní ilẹ̀ Éfúráímù àti Mánásè títí dé Sébúlúnì: Ṣùgbọ́n wọ́n fi wọ́n rẹ́rín ẹlẹ́yà, wọ́n sì gàn wọ́n.
11Síbẹ̀ òmíràn nínú àwọn ènìyàn Áṣérì àti Mánásè àti Sébúlúnì rẹ̀ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Jérúsálẹ́mù.
12Ní Júdà pẹ̀lú, ọwọ́ Ọlọ́run wá láti fún wọn ní ọkàn kan láti pa òfin ọba mọ́ àti tí àwọn ìjòyè, nípa ọ̀rọ̀ OLÚWA.
13Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì péjọ ní Jérúsálẹ́mù, láti pa àjọ àkàrà aláìwú mọ́ ní oṣù kejì.
14Wọ́n sì dìde, wọ́n sì kó gbogbo pẹpẹ tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù lọ, àti gbogbo pẹpẹ tùràrí ni wọ́n kó lọ, wọ́n sì dà wọ́n sí odò Kídírónì.
15Nígbà náà ni wọ́n pa ẹran ìrékọjá náà ní ọjọ́ kẹ́rinlà oṣù kejì: ojú sì ti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, wọ́n sì yà ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì mú ẹbọ sísun wá sínú ilé OLÚWA.
16Wọ́n sì dúró ní ipò wọn, bí ètò wọn gẹ́gẹ́ bí òfin Mósè, ènìyàn Ọlọ́run: àwọn àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà, tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Léfì.
17Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó wà nínú ìjọ ènìyàn náà tí kò yà ara wọn sí mímọ́: wọn pa ẹran ìrékọjá fún olúkúlùkù ẹni tí ó ṣe aláìmọ́, láti yà á sí mímọ́ sí OLÚWA.
18Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àni ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú Éfíráimù àti Mánásè, Ísákárì, àti Sébúlúnì kò sá wẹ̀ ara wọn mọ́ síbẹ̀ wọ́n jẹ ìrékọjá naà, kì íṣe gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́. Ṣùgbọ́n Heṣekáyà bẹ̀bẹ̀ fún wọn, wí pé, OLÚWA, ẹni rere, dáríjin olúkúlùkù,
19Tí ó múra ọkàn rẹ̀ láti wá Ọlọ́run, OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kì íṣe nípa ìwẹ̀nùmọ́ mímọ́
20OLÚWA sì gbọ́ ti Hesékíà, ó sì mú àwọn ènìyàn náà lára dá.
21Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí a rí ní Jérúsálẹ́mù fi ayọ̀ ńlá pa àjọ àkàrà aláìwú mọ́ ní ọjọ́ méje: àwọn ọmọ Léfì, àti àwọn àlùfáà yin OLÚWA lójojúmọ́, wọ́n ń fi ohun èlò olóhùn gooro kọrin sí OLÚWA.
22Heṣekáyà sọ̀rọ̀ ìtùnú fún gbogbo àwọn ọmọ Léfì, tí ó lóye ní ìmọ̀ rere OLÚWA: ọjọ́ méje ni wọ́n fi jẹ àṣè náà wọ́n rú ẹbọ àlàáfíà, wọ́n sì ń fi ohùn rara dúpẹ́ fún OLÚWA, Ọlọ́run àwọn baba wọn.
23Gbogbo ìjọ náà sì gbìmọ̀ láti pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́: wọ́n sì fi ayọ̀ pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́.
24Nítorí Heṣekáyà, ọba Júdà, ta ìjọ ènìyàn náà ní ọrẹ, ẹgbẹ̀rún akọ màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárún àgùntàn: Ọ̀pọlọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà sì ya ara wọn sí mímọ́.
25Gbogbo ìjọ ènìyàn Júdà pẹ̀lú àwọn àlùfaà àti àwọn ọmọ Léfì, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó ti inú Ísírẹ́lì jáde wá, àti àwọn àlejò tí ó ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì jáde wá, àti àwọn tí ń gbé Júdà yọ̀.
26Bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ńlá sì wà ní Jérúsálẹ́mù: nítorí láti ọjọ́ Sólómónì, ọmọ Dáfídì, ọba Ísírẹ́lì, irú èyí kò sí ní Jérúsálẹ́mù.
27Nígbà náà ni àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì dìde, wọ́n sì súre fún àwọn ènìyàn náà: a sì gbọ́ ohùn wọn, àdúrà wọn sì gòkè lọ si ibùgbé mímọ́ rẹ̀, àni sí ọ̀run.