Ìwé Kíróníkà Kejì 33:1-25 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Mánásè jẹ́ ọmọ ọdún Méjìlá nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún márùndínlọ́gọ́ta.

2Ó sì ṣe búburú ní ojú OLÚWA. Nípa títẹ̀lé ọ̀nà iṣẹ́ ìríra ti àwọn orílẹ̀ èdè tí OLÚWA ti lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn.

3Ó tún kọ́ àwọn ibi gíga tí baba rẹ̀ Heṣekáyà ti fọ́ túútúú. Ó sì gbé àwọn pẹpẹ dìde fún àwọn Báálì ó sì ṣe àwọn òpó Áṣérà. Ó foríbalẹ̀ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run ó sì sìn wọ́n.

4Ó kọ́ àwọn pẹpẹ sínú ilé OLÚWA ní èyí tí OLÚWA ti wí pé “Orúkọ mi yóò wà ní Jérúsálẹ́mù títí láé.”

5Nínú ààfin méjèèje ti ilé OLÚWA, ó kọ́ àwọn pẹpẹ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run

6Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ rúbọ nínú iná ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Bẹni-Hínómù, ó ń ṣe oṣó, àfọ̀ṣẹ, ìsàjẹ́ pẹ̀lú bíbéèrè lọ́dọ̀ àwọn abókúsọ̀rọ̀, àti ẹlẹ́mìí. O se ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú OLÚWA láti mú un bínú.

7Ó mú ère gbígbẹ́ tí ó ti gbẹ́ ó sì gbé e sínú ilé OLÚWA, ní èyí tí Ọlọ́run ti sọ fún Dáfídì àti sí ọmọ rẹ̀ Solómónì, “Nínú ilé OLÚWA yìí àti ní Jérúsálẹ́mù, tí mo ti yàn kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, èmi yóò fi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé.

8Èmi kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ilẹ̀ tí a yàn fún àwọn baba ńlá yín tí wọ́n bá ṣe pẹ̀lẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí mo palásẹ fún wọn. Nípa gbogbo àwọn òfin, àsẹ àti àwọn ìlànà tí a fún yín ní pasẹ̀ Mósè.”

9Ṣùgbọn Mánásè mú kí Júdà àti àwọn tí ń gbé Jérúsálẹ́mù yapa, àti láti ṣe búburú ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ, àwọn tí OLÚWA ti parun níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

10Ọlọ́run bá Mánásè sọ̀rọ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò kọbi ara sí i

11Bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA mú àwọn alákòóso ọmọ ogun ọba Ásíríà láti dojúkọ wọ́n, tí ó mú Mánásè lẹ́lẹ́wọ̀n, ó fi ìkọ́ mú-un ní imú rẹ̀, ó dè é pẹ̀lú Ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ ó sì mú-un lọ sí Bábílónì.

12Nínú ìpọ́njú rẹ̀, ó wá ojú rere OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀.

13Nígbà tí ó sì gbàdúrà síi, inú OLÚWA dùn sí àdúrà rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ó mú un padà wá sí Jérúsálẹ́mù àti sí ìjọba rẹ̀. Nígbà náà Mánásè mọ̀ wí pé OLÚWA ni Ọlọ́run.

14Lẹ́yìn èyí, ó tún ìta ògiri ìlú ńlá Dáfídì kọ́. Ìhà ìwọ̀ oòrùn orísun Gíhónì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní jìnnà réré bí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ẹja àti yíyí orí òkè Ófélì; ó se é ní gíga díẹ̀. Ó mú àwọn alákòóso ológun wà ní ìdúró nínú gbogbo àwọn ìlú ńlá olódi ní Júdà.

15Ó pa gbogbo àwọn Ọlọ́run àjòjì run. Ó sì hú gbogbo àwọn ère kúrò nínú ilé OLÚWA, pẹ̀lú gbogbo àwọn pẹpẹ tí ó ti kọ́ ní òkè ilé OLÚWA àti ní Jérúsálẹ́mù; ó sì kó wọn jáde kúrò nínú ìlú.

16Nígbà náà ó mú àwọn pẹpẹ padà bọ̀ sípò. Ó sì rú ọrẹ ìdàpọ̀ àti ọrẹ ọpẹ́ lórí rẹ̀. Ó sì sọ fún Júdà láti sin OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

17Àwọn ènìyàn, bí ó ti wù kí ó rí, tẹ̀ṣíwájú láti máa rú ẹbọ ní àwọn ibi gíga. Ṣùgbọ́n sí OLÚWA Ọlọ́run wọn nìkan.

18Àwọn isẹ́ yòókù ti ìjọba Mánásè pẹ̀lú àdúrà rẹ̀ sí Ọlọ́run rẹ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn aríran sọ sí i wà nínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì.

19Àdúrà rẹ̀ àti bí inú Ọlọ́run ṣe dùn sí àdúrà rẹ̀ àti gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àti àìsòótọ́ àti àwọn ipò níbi tí ó kọ́ àwọn ibi gíga sí, ó sì gbé àwọn òpó Áṣérà àti àwọn òrìṣà kí ó tó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, gbogbo rẹ̀ ni a kọ sínu ìwé ìrántí àwọn aríran.

20ⓑ Mánásè sinmi pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín sínú ààfin rẹ̀. Ámónì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba

21ⓒ Ámónì jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjì.

22Ó ṣe búburú ní ojú OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ Mánásè ti ṣe. Ámónì sìn ó sì rú ẹbọ sí àwọn òrìṣà tí Mánásè ti ṣe.

23Ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i baba a rẹ̀ Mánásè. Kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú OLÚWA: Ẹ̀bi Ámónì ń ga sí i.

24Àwọn onísẹ́ Ámónì dìtẹ̀ síi. Wọ́n sì pa á ní ààfin rẹ̀

25Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Ámónì, wọ́n sì mú Jósíà ọmọ rẹ̀ jọba ní ipò rẹ̀.

cle>