Ìwé Kíróníkà Kejì 36:1-23 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jehóáhásì ọmọ Jósíà wọn sì fi jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù ni ipọ̀ Baba rẹ̀.

2Jehóáhásì sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́talélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ni Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́ta.

3Ọba Éjíbítì lé e kúrò lórí ìtẹ́ ní Jérúsálẹ́mù ó sì bù fún un lórí Júdà, ọgọ́rún talẹ́ńtì fàdákà (100) àti talẹ́ntì wúrà kan.

4Ọba Éjíbítì sì mú Élíákímù, arákùnrin Jehóáhásì, jẹ ọba lórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù, ó sì yí orúkọ Eliákímù padà sí Jéhóíákíámù, ṣùgbọ́n Nékò mú arákùnrin Eliákímù, Jehóáhásì ó sì gbé e lórí Éjíbítì.

5ⓑ Jéhóíákímù sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjìlá. Ó sì ṣe búburú ní ojú OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀.

6Nebukadínésárì ọba Bábílónì sì mú un, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti mú-un lọ sí Bábílónì.

7Nebukadínésárì pẹ̀lú mú-un lọ sí Bábílónì, ohun èlò láti ilé OLÚWA, ó sì mú wọn lọ sí ààfin tirẹ̀ níbẹ̀.

8Ìyòókù isẹ́ ìjọba Jéhóíákíámù, àwọn ohun ìríra tí ó ṣe àti gbogbo ohun tí a rí nípa rẹ̀, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì àti Júdà. Jéhóíákínì ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

9ⓒ Jehóiakínì sì jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún (18) nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ́ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún oṣù mẹ́ta àti ijọ́ mẹ́wàá ó sì ṣe búburú ní ojú OLÚWA.

10Ní àmọ́dún, ọba Nebukadínsárì ránsẹ́ síi ó sì mú-un wá sí Bábílónì, pẹ̀lú ohun èlò dáradára láti ilé OLÚWA, ó sì mú arákùnrin Jehóíákínì, Sedekíà, jọba lórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù.

11ⓓ Sedekíáyà sì jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlèlógún. Nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kànlá.

12Ó sì ṣe búburú ní ojú OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀ ko si rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jeremíà wòlíì, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ OLÚWA.

13Ó sì tún ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Nebukadinésárì pẹ̀lú, ẹni tí ó mú kí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra. Ó sì di ẹni tí ọrùn rẹ̀ wàkì, ó sì mú ọkàn rẹ̀ le láti má lè yípadà sí OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

14Síwájú síi gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn sì di ẹni tí ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi, pẹ̀lú gbogbo ìríra àwọn orílẹ̀ èdè wọ́n sì sọ ilé OLÚWA di èérí, tí ó ti yà sí mímọ́ ní Jérúsálẹ́mù.

15OLÚWA, Ọlọ́run àwọn baba wọn ránsẹ́ sí wọn láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣíwájú àti ṣíwájú síi, nítorí tí ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ àti sí ibùgbé rẹ̀.

16Ṣùgbọ́n wọ́n ń kùn sí àwọn ìransẹ́ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n fi àwọn wòlíì rẹ̀ sẹ̀sín títí tí ìbínú Ọlọ́run ṣe ru sórí wọn, sí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì sí àtúnṣe.

17Ó sì mú wá sórí wọn ọba àwọn ará Bábílónì tí wọ́n bá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn jà pẹ̀lú idà ní ilẹ̀ ibi mímọ́, kò sì ní ìyọ́nú sí àgbà ọkùnrin tàbí ọ̀dọ́mọdé bìnrin, wúndíá, tàbí arúgbó. Ọlọ́run sì fi gbogbo wọn lé Nebukadinésárì lọ́wọ́.

18Ó sì mú gbogbo ohun èlò láti ilé Ọlọ́run lọ sí Bábílónì, níńlá àti kékeré àti ìṣúra ilé OLÚWA àti ìṣúra ọba àti ìjòyè rẹ̀.

19Wọ́n sì fi iná sí ilé Ọlọ́run, wọ́n sì wó gbogbo ògiri ilé Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì jó gbogbo ààfin wọn, wọ́n sì ba gbogbo ohun-èlò ibẹ̀ jẹ́.

20Ó sì kó èyí tí ó kù lọ sí Bábílónì àwọn tí ó rí ibi sá láti ẹnu idà wọ́n sì di ìránṣẹ́ fún un àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí tí ìjọba Pásíà fi gba agbára.

21Ìlẹ̀ náà sì gbádùn ìsinmi rẹ̀, ní gbogbo ìgbà ìdahoro, òun sì ń sinmi títí ó fi di àádọ́rin ọdún (70) fi pé ní ìmúsẹ ọ̀rọ̀ OLÚWA tí a sọ láti ẹnu Jeremíà.

22ⓔ Ní ọdún kín-ín-ní Kírúsì ọba Pásíà, kí ọ̀rọ̀ OLÚWA tí a tẹnu Jeremáyà sọ báà le ṣẹ pé, OLÚWA run ẹ̀mí Kírúsì ọba Pásíà láti ṣe ìkéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì kọọ́ sínú ìwé pẹ̀lú.

23“Èyí ni ohun tí Kérúsì ọba Pásíà sọ wí pé: “ ‘OLÚWA, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mí ní gbogbo ìjọba ayé yìí, ó sì ti yàn mí láti kọ́ ilé OLÚWA fún òun ní Jérúsálẹ́mù ti Júdà. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàárin yín le gòkè lọ pẹ̀lú rẹ̀; kí OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀ kí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.’ ”

cle>