1Nádábù àti Ábíhù tí í ṣe ọmọ Árónì sì mú àwo tùràrí kọ̀ọ̀kan, wọ́n fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀, wọ́n sì rú iná àìmọ́ níwájú OLÚWA, èyí tó lòdì sí àṣẹ OLÚWA.
2Torí èyí iná jáde láti ọ̀dọ̀ OLÚWA, ó sì jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú OLÚWA.
3Mósè sì sọ fún Árónì pé, “Ohun tí OLÚWA ń sọ nípa rẹ̀ nìyìí nígbà tó wí pé”
4Mósè pe Másáélì àti Élísáfánì ọmọ Yúsíélì tí í ṣe arákùnrin Árónì, ó sọ fún wọn pé “Ẹ wá, kí ẹ sì gbé àwọn arákùnrin yín jáde kúrò níwájú ibi mímọ́ lọ sí ẹ̀yìn ibùdó.”
5Wọ́n sì wá gbé wọn, pẹ̀lú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn ní ọrùn wọn lọ sí ẹ̀yìn ibùdó bí Mósè ti sọ.
6Mósè sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóòkù, Élíásárì àti Ítamárì pé, “ẹ má ṣe sọ̀fọ̀ nípa ṣíṣe aláìtọ́jú irun yín tàbí kí ẹ sí orí yín sílẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ya aṣọ, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, OLÚWA yóò sì bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ẹbí yín, àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì le è ṣọ̀fọ̀ lórí àwọn tí OLÚWA fi iná parun.
7Ẹ má ṣe kúrò ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá kúrò níbẹ̀, ẹ ó kùú, nítorí pé òróró ìtasórí OLÚWA wà lórí yín” Wọ́n sì ṣe bí Mósè ti wí.
8
9“Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀ kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle mìíràn nígbàkigbà tí ẹ bá n lọ inú àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, èyí jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín láti ìrandíran.
10Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrin mímọ́ àti àìmọ́, láàrin èérí àti àìléérí.
11Ẹ gbọdọ̀ kọ́ àwọn ara Ísírẹ́lì ní gbogbo àṣẹ tí OLÚWA fún wọn láti ẹnu Mósè.”
12
13Ẹ jẹ́ ẹ́ ní ibi mímọ́, nítorí pé òun ni ìpín rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ nínú ẹbọ tí a finá sun sí OLÚWA nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe pa á láṣẹ.
14
15Itan tí wọ́n mú wá àti igẹ̀ ẹran tí ẹ fì ni ẹ gbọdọ̀ mú wá pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ tí a finá sun láti le fí wọ́n níwájú OLÚWA bí ẹbọ fífì. Èyí yóò sì jẹ́ ìpín tìrẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ nígbà gbogbo bí OLÚWA ṣe pa á láṣẹ.”
16Nígbà tí Mósè wádìí nípa ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tó sì rí i pé wọ́n ti sun ún, ó bínú sí Élíásárì àti Ítamárì, àwọn ọmọ Árónì yóòkù, ó sì bèèrè pé,
17
18Níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sí ibi mímọ́, ẹ̀ bá ti jẹ ewúrẹ́ náà ní agbégbé ibi mímọ́ bí mo ṣe pa á láṣẹ.”
19Árónì sì dá Mósè lóhùn pé, “Lónìí tí wọ́n rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun wọn níwájú OLÚWA ni irú èyí tún sẹlẹ̀ sí mi. Ǹjẹ́ inú OLÚWA yóò wá dùn bí mo bá jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lónìí?”
20Nígbà tí Mósè gbọ́ èyí, ọkàn rẹ̀ balẹ̀.