Ìwé Léfítíkù 13:1-59 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA sọ fún Mósè àti Árónì pé,

2“Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìwú, èélá tàbí àmì dídán kan ní ara rẹ̀, èyí tí ó le di àìsàn àwọ̀ ara tí ó le ràn ká. Ẹ gbọdọ̀ mú-un tọ́ Árónì àlùfáà lọ tàbí sí ọ̀dọ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó jẹ́ àlùfáà.

3Àlùfáà náà ni ó gbọdọ̀ yẹ egbò ara rẹ̀ wò: bí irun egbò náà bá di funfun tí egbò náà sì dà bí i pé ó jinlẹ̀ kọjá awọ ara: èyí jẹ́ àrùn ara tí ó le è ràn: Bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò kí ó sọ ọ́ di mímọ̀ pé aláìmọ́ ni ẹni náà.

4Bí àpá ara rẹ̀ bá funfun tí ó sì dàbí ẹni pé kò jinlẹ̀ jù awọ ara, tí irun rẹ̀ kò sì yípadà sí funfun kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje.

5Ní ọjọ́ keje ni kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ó bá rí i pé egbò náà wà ṣíbẹ̀ tí kò sì ràn ká àwọ̀ ara, kí ó tún fi pamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn.

6Ní ọjọ́ keje ni kí àlùfáà tún padà yẹ̀ ẹ́ wò, bí egbò náà bá ti san tí kò sì ràn ká awọ ara rẹ̀. Kí àlùfáà pè é ní mímọ́. Kí ọkùnrin náà fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì mọ́

7Ṣùgbọ́n bí èélá náà bá ń ràn ká awọ ara rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti fi ara rẹ̀ han àlùfáà láti sọ pé ó ti mọ́. Ó tún gbọdọ̀ fi ara rẹ̀ hàn níwájú àlùfáà.

8Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí èélá náà bá ràn ká awọ ara rẹ̀, kí àlùfáà fi hàn pé kò mọ́. Àrùn ara tí ń ràn ni èyí.

9“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àrùn awọ ara tí ń ràn yìí ni kí a mú wá sọ́dọ̀ àlùfáà.

10Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí ìwú funfun kan bá wà lára rẹ̀: èyí tí ó ti sọ irun ibẹ̀ di funfun: tí a sì rí ojú egbò níbi ìwú náà.

11Àrùn ara burúkú gbáà ni èyí, kí àlùfáà jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò mọ́: kí ó má ṣe ya ẹni náà sọ́tọ̀ fún àyẹ̀wò torí pé aláìmọ́ ni ẹni náà jẹ́ tẹ́lẹ̀.

12“Bí àrùn náà bá ràn yíká gbogbo awọ ara rẹ̀ tí àlùfáà sì yẹ̀ ẹ́ wò, tí ó rí i pé àrùn náà ti gba gbogbo ara rẹ̀ láti orí títí dé ẹṣẹ̀,

13àlùfáà yóò yẹ̀ ẹ́ wò, bí àrùn náà bá ti ran gbogbo àwọ̀ ara rẹ̀, kí àlùfáà sọ pé ó di mímọ́, torí pé gbogbo ara ẹni náà ti di funfun, ó ti mọ́.

14Ṣùgbọ́n bí ẹran ara rẹ̀ bá tún hàn jáde: Óun yóò di àìmọ́.

15Bí àlùfáà bá ti rí ẹran ara rẹ̀ kan kí ó pè é ni aláìmọ́. Ẹran ara rẹ̀ di àìmọ́ torí pé ó ní àrùn tí ń ràn.

16Bí ẹran ara rẹ̀ bá yípadà sí funfun, kí o farahan àlùfáà.

17Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò: bí egbò rẹ̀ bá ti di funfun kí àlùfáà pe ẹni náà ni mímọ́. Òun yóò sì di mímọ́.

18“Bí oówo bá mú ẹnikẹ́ni nínú ara rẹ̀ tí ó sì san.

19Tí ìwú funfun tàbí àmì funfun tí ó pọ́n díẹ̀ bá farahàn ní ojú ibi tí oówo náà wà: kí ẹni náà lọ sọ fún àlùfáà.

20Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ó bá jinlẹ̀ jù awọ ara rẹ̀ lọ tí irun tirẹ̀ sì ti di funfun: kí àlùfáà pe ẹni náà ni aláìmọ́. Àrùn ara tí ó le ràn ló yọ padà lójú oówo náà.

21Bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò tí kò sì sí irun funfun níbẹ̀ tí ó sì ti gbẹ: kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje.

22Bí ó bá ràn ká: awọ ara, kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́. Àrùn tí ó ń ràn ni èyí.

23Ṣùgbọ́n bí ojú ibẹ̀ kò bá yàtọ̀, tí kò sì ràn kára: èyí jẹ́ àpa oówo lásán: kí àlùfáà pe ẹni náà ni mímọ́.

24“Bí iná bá jó ẹnìkan tí àmì funfun àti pupa sì yọ jáde lójú egbò iná náà.

25Kí àlùfáà yẹ ojú ibẹ̀ wò. Bí irun ibẹ̀ bá ti di funfun tí ó sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lásán lọ, àrùn tí ń ràn ká ti wọ ojú iná náà, kí àlùfáà pè é ní aláìmọ́. Àrùn tí ń ran ni ni èyí.

26Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò tí kò sí irun funfun lójú egbò náà tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ tí ó sì ti gbẹ, kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje.

27Kí àlùfáà yẹ ẹni náà wò ní ọjọ́ keje, bí ó bá ń ràn ká àwọ̀ ara, kí àlùfáà kí ó pè é ní aláìmọ́. Àrùn ara tí ń ràn ni èyí.

28Ṣùgbọ́n bí ojú iná náà kò bá yípadà tí kò sì ràn ká àwọ̀ ara. Ṣùgbọ́n tí ó gbẹ: ìwú lásán ni èyí láti ojú iná náà; kí àlùfáà pè é ní mímọ́. Ojú àpá iná lásán ni.

29“Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá ní egbò lórí tàbí ní àgbọ̀n.

30Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí ó bá jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ tí irun ibẹ̀ sì pọ́n fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ tí kò sì kún; kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́; làpálàpá ni èyí. Àrùn tí ń ràn ká orí tàbí àgbọ̀n ni.

31Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ egbò yìí wò tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ tí kò sì sí irun dúdú kan níbẹ̀. Kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje.

32Ní ọjọ́ kéje kí àlùfáà yẹ ojú ibẹ̀ wò, bí làpálàpá náà kò bá ràn mọ́ tí kò sì sí irun pípọ́n fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ nínú rẹ̀ tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ.

33Kí a fá gbogbo irun rẹ̀ ṣùgbọ́n kí ó dá ojú àpá náà sí, kí àlùfáà sì tún fi pamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn.

34Kí àlùfáà yẹ làpálàpá náà wò, ní ọjọ́ kéje bí kò bá ràn ká gbogbo àwọ̀ ara: tí kò sì jinlẹ̀ ju inú àwọ̀ ara lọ. Kí àlùfáà pè é ní mímọ́: Kí ó fọ aṣọ rẹ̀: òun yóò sì mọ́.

35Ṣùgbọ́n bí làpálàpá náà bá ràn ká àwọ̀ ara rẹ̀ lẹ́yìn tí a ti fi hàn pé ó ti mọ́.

36Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí làpálàpá náà bá ràn ká àwọ̀ ara; kí àlùfáà má ṣe yẹ irun pupa fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ wò mọ́. Ẹni náà ti di aláìmọ́.

37Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdájọ́ àlùfáà pé ẹni náà kò mọ́, tí ojú làpálàpá náà kò bá yípadà, tí irun dúdú si ti hù jáde lójú rẹ̀. Làpálàpá náà ti san. Òun sì ti di mímọ́. Kí àlùfáà fi í hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti di mímọ́.

38“Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá ní ojú àpá funfun lára àwọ̀ ara rẹ̀.

39Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ojú àpá náà bá funfun àrùn ara tí kò léwu ni èyí tí ó farahàn lára rẹ̀: Ẹni náà mọ́

40“Bí irun ẹnìkan bá rẹ̀ dànù tí ó sì párí. Ẹni náà mọ́.

41Bí irun ẹnìkan bá rẹ̀ dànù níwájú orí tí ó sì párí níwájú orí. Ẹni náà mọ́.

42Ṣùgbọ́n bí ó bá ní egbò pupa fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ní ibi orí rẹ̀ tí ó pá, tàbí níwájú orí rẹ̀: àrùn tí ń ràn ká iwájú orí tàbí ibi orí ni èyí.

43Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí egbò tó wù níwájú orí rẹ̀ tàbí tí orí rẹ̀ bá pupa díẹ̀ tí ó dàbí àrùn ara tí ń ràn kálẹ̀.

44Alárùn ni ọkùnrin náà: kò sì mọ́, kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́ torí egbò tí ó wà ní orí rẹ̀.

45“Kí ẹni tí àrùn náà wà ní ara rẹ̀ wọ àkísà. Kí ó má ṣe gé irun rẹ̀, kí ó daṣọ bo ìṣàlẹ̀ ojú rẹ̀ kí ó sì máa ké wí pé, ‘Aláìmọ́! Aláìmọ́!’

46Gbogbo ìgbà tí àrùn náà bá wà ní ara rẹ̀; aláìmọ́ ni: kí ó máa dá gbé. Kí ó máa gbé lẹ́yìn ibùdó.

47“Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá ba aṣọ kan jẹ́ yálà aṣọ onírun àgùtàn tàbí aṣọ funfun.

48Ìbáà ṣe títa tàbí híhun tí ó jẹ́ aṣọ funfun tàbí irun àgùtàn, bóyá àwọ̀ tàbí ohun tí a fi àwọ̀ ṣe.

49Bí ìbàjẹ́ ara aṣọ: ìbáà ṣe awọ, irun àgùtàn, aṣọ títa, aṣọ híhun tàbí ohun tí a fi awọ ṣe bá di aláwọ̀ ewé tàbí kí ó pupa: èyí jẹ́ ẹ̀tẹ̀ tí ń ràn ká. Ẹ gbọdọ̀ fi hàn fún àlùfáà.

50Àlùfáà yóò yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, yóò sì pa gbogbo ohun tí ẹ̀tẹ̀ náà ti ràn mọ́ fún ọjọ́ méje.

51Ní ọjọ́ keje kí ó yẹ̀ ẹ́ wò bí àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá ràn ká ara aṣọ tàbí irun àgùtàn, aṣọ híhun tàbí awọ, bí ó ti wù kí ó wúlò tó, ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí jẹ́, irú ohun bẹ́ẹ̀ kò mọ́.

52Ó gbọdọ̀ sun aṣọ náà tàbí irun àgùtàn náà, aṣọ híhun náà tàbí awọ náà ti ó ni ìbàjẹ́ kan lára rẹ̀ ni iná torí pé ẹ̀tẹ̀ tí í pa ni run ni. Gbogbo nǹkan náà ni ẹ gbọdọ̀ sun ní iná.

53“Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò tí ẹ̀tẹ̀ náà kò ràn ká ara aṣọ náà yálà aṣọ títa, aṣọ híhun tàbí aláwọ.

54Kí ó pàṣe pé kí wọ́n fọ ohunkóhun tí ó bàjẹ́ náà kí ó sì wà ní ìpamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn.

55Lẹ́yìn tí ẹ bá ti fọ ohun ti ẹ̀tẹ̀ náà mú tan, kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò: bí ẹ̀tẹ̀ náà kò bá yí àwọn aṣọ náà padà, bí kò tilẹ̀ tí ì ràn: Àìmọ́ ni ó jẹ́. Ẹ fi iná sun un, yálà ẹ̀gbẹ́ kan tàbí òmíràn ní ẹ̀tẹ̀ náà dé.

56Bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò ti ẹ̀tẹ̀ náà bá ti kúrò níbẹ̀: lẹ́yìn tí a ti fọ̀ ohunkóhun tí ó mú, kí ó ya ibi tí ó bàjẹ́ kúrò lára aṣọ náà, awọ náà, aṣọ híhun náà tàbí aṣọ tìta náà.

57Ṣùgbọ́n bí ó bá tún ń farahàn níbi aṣọ náà, lára aṣọ títa náà, lára aṣọ híhun náà tàbí lára ohun èlò awọ náà, èyí fi hàn pé ó ń ràn ká. Gbogbo ohun tí ẹ̀tẹ̀ náà bá wà lára rẹ̀ ni kí ẹ fí iná sun.

58Aṣọ náà, aṣọ títa náà, aṣọ híhun náà tàbí ohun èlò àwọ náà tí a ti fọ̀ tí ó sì mọ́ lọ́wọ́ ẹ̀tẹ̀ náà ni kí a tún fọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Yóò sì di mímọ́.”

59Ìlànà wọ̀nyí wà fún àwọn ohun tí ẹ̀tẹ̀ bàjẹ́ níbi, aṣọ irun àgùtàn aṣọ funfun, aṣọ títa, aṣọ híhun tàbí ohun èlò awọ, láti fi hàn bóyá wọ́n wà ní mímọ́ tàbí àìmọ́.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
/div>