1OLÚWA sọ fún Mósè pé:
2“Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.
3Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní Éjíbítì níbi tí ẹ ti gbé rí: bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Kénánì níbi tí èmi ń mú yín lọ. Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé iṣe wọn.
4Ẹ gbọdọ̀ tẹ̀lé òfin mi kí ẹ sì kíyèsí àti pa àṣẹ mi mọ́.
5
6“ ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ súnmọ́ ìbátan rẹ̀ láti bá a lòpọ̀, èmí ni OLÚWA.
7
8“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù u bàbá rẹ nípa bíbá ìyàwó bàbá rẹ lòpọ̀: nítorí ìhòòhò bàbá rẹ ni.
9
10“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin, ọmọ rẹ ọkùnrin lòpọ̀ tàbí ọmọbìnrin ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀ nítorí pé ìhòòhò wọn, ìhòòhò ìwọ fúnrarẹ ni.
11“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin aya bàbá rẹ lòpọ̀; èyí tí a bí fún bàbá rẹ nítorí pé arábìnrin rẹ ni
12
13“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin mọ̀mọ́ rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan ìyá rẹ ni.
14
15
16
17
18“ ‘Má ṣe fẹ́ àbúrò ìyàwó rẹ obìnrin ní aya gẹ́gẹ́ bí orogún tàbi bá a lòpọ̀, nígbà tí ìyàwó rẹ sì wà láàyè.
19
20“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá aya aládúgbò rẹ lòpọ̀, kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́ pẹ̀lú rẹ̀.
21
22
23
24“ ‘Má ṣe fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ba ara rẹ jẹ́, torí pé nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀ èdè tí mo lé kúrò níwájú yín ti ba ara wọn jẹ́.
25Nítorí pé ilẹ̀ náà di àìmọ́ nítorí náà mo fi ìyà jẹ ẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ilẹ̀ náà sì pọ àwọn olùgbé ibẹ̀ jáde.
26Ṣùgbọ́n kí ẹ máa pa àṣẹ àti òfin mi mọ́. Onílé tàbí àlejò tó ń gbé láàrin yín kò gbọdọ̀ ṣe ọ̀kan nínú àwọn ohun ìríra wọ̀nyí.
27Nítorí pé gbogbo ohun ìríra wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ti gbé ilẹ̀ náà ṣáájú yín ti ṣe tí ó sì mú kí ilẹ̀ náà di aláìmọ́.
28Bí ẹ bá sọ ilẹ̀ náà di àìmọ́ yóò pọ̀ yín jáde bí ó ti pọ àwọn orílẹ̀ èdè tí ó ti wá ṣáájú yín jáde.
29“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ohun ìríra wọ̀nyí, kí ẹ gé irú ẹni náà kúrò láàrin àwọn ènìyàn.
30Nítorí náà ẹ gbọdọ̀ ṣe ohun tí mo fẹ́, kí ẹ má sì lọ́wọ́ nínú àṣà ìríra wọ̀nyí, tí wọn ń ṣe kí ẹ tó dé. Ẹ má ṣe fi wọ́n ba ara yín jẹ́. Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.’ ”