1OLÚWA sọ fún Mósè pé,
2
3
4
5“ ‘Nígbà tí ẹ̀yín bá sì rú ẹbọ àlàáfíà sí OLÚWA, kí ẹ̀yin kí ó se é ní ọ̀nà tí yóò fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò yín!
6Ní ọjọ́ tí ẹ bá rú u náà ni ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ tàbí ní ọjọ́ kejì; èyí tí ó bá sẹ́kù di ọjọ́ kẹta ni kí ẹ fi iná sun.
7Bí ẹ bá jẹ nínú èyí tí ó sẹ́kù di ọjọ́ kẹta, àìmọ́ ni èyí jẹ́, kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.
8Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù, nítorí pé ó ti ba ohun mímọ́ OLÚWA jẹ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.
9
10Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kórè oko yín tan pátapáta, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sa èso tí ó rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ nínú oko àjàrà yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn aláìní àti fún àwọn àlejò. Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.
11
12
13
14
15
16“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olófofó láàrin àwọn ènìyàn rẹ.
17“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kóríra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládúgbò rẹ wí, kí o má baà jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀.
18
19
20“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá obìnrin tí ó jẹ́ ẹrú lòpọ̀, ẹni tí a ti mọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn tí a kò sì tí ì rà á padà tàbí sọ ọ́ di òmìnira. Ẹ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí kí ẹ sì jẹ wọ́n ní ìyà tó tọ́ ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ pa wọ́n, torí pé kò ì tíì di òmìnira.
21Kí ọkùnrin náà mú àgbò kan wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé bí i ẹbọ ẹ̀bi sí OLÚWA.
22Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà níwájú OLÚWA fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀. A ó sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ náà jìn-ní.
23“ ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí ẹ sì gbin igi eléso, kí ẹ ká èso wọn bí ohun èèwọ̀. Fún ọdún mẹ́ta ni kí ẹ kà á sí èèwọ̀, ẹ kò gbọdọ jẹ ẹ́
24Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹrin, gbogbo èso wọ̀nyí yóò jẹ́ mímọ́, ọrẹ fún ìyìn OLÚWA.
25Ní ọdún karùn ún ni ẹ̀yin tó lè jẹ nínú èso igi náà, kí èso wọn ba à le máa pọ̀ sí i. Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.
26
27
28“ ‘Ẹ má ṣe titorí òkú, gé ibi kankan nínú ẹ̀yà ara yín, Ẹ kò sì gbọdọ̀ sín gbẹ́rẹ́ kankan. Èmi ni OLÚWA.
29
30
31
32“ ‘Fi ọ̀wọ̀ fún ọjọ́ orí arúgbó kí ẹ sì bọlá fún àwọn àgbàlagbà. Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run yín: Èmi ni OLÚWA.
33
34kí àjèjì tí ń gbé pẹ̀lú yín dàbí onílé láàrin yín kí ẹ sì fẹ́ràn rẹ̀ bí i ara yín, torí pé ẹ̀yin ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Éjíbítì rí. Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.
35
36Ẹ jẹ́ olódodo pẹ̀lú àwọn òsùwọ̀n yín òsùwọ̀n ìtẹ̀wọ̀n, òsùwọ̀n wíwúwo, òsùwọ̀n ìyẹ̀fun àti òsùwọ̀n nǹkan olómi yín ní láti jẹ́ èyí tí kò ní èrú nínú. Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì.
37“ ‘Ẹ ó sì máa pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, ẹ ó sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni OLÚWA.’ ”