1
2“Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn àjọ̀dún tí mo ti yàn, àwọn àjọ̀dún ti OLÚWA èyí tí ẹ gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí ìpàdé àjọ mímọ́.
3“ ‘Ọjọ́ mẹ́fà ni ẹ le fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi. Ọjọ́ ìpàdé àjọ mímọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. Ọjọ́ ìsinmi OLÚWA ni.
4“ ‘Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọdún tí OLÚWA yàn, ìpàdé àjọ mímọ́ tí ẹ gbọdọ̀ kéde lákókò wọn.
5Àjọ ìrékọjá OLÚWA bẹ̀rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní (Épírì).
6Ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kìnm-ín-ní ni àjọ̀dún àkàrà àìwú (àkàrà tí kò ní ìwúkàrà) tí OLÚWA bẹ̀rẹ̀ fún ọjọ́ méje ni ẹ gbọdọ̀ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.
7Ẹ pe ìpàdé àjọ mímọ́ ní ọjọ́ kìn-ín-ní, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́ yín.
8Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún OLÚWA. Ní ọjọ́ keje, ẹ pe ìpàdé àjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́.’ ”
9OLÚWA sọ fún Mósè pe
10“Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi yóò fún yín, tí ẹ bá ń ṣe ìkórè, kí ẹ mú síírì ọkà àkọ́kọ́ tí ẹ kórè wá fún àlùfáà.
11Kí o fí síírì ọkà náà níwájú OLÚWA, kí ó le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín: kí àlùfáà fì í ní ọjọ́ kejì ìsinmi.
12Ní ọjọ́ tí ẹ bá fí síírì ọkà náà, kí ẹ mú ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dúnkan láìní àbùkù rú ẹbọ sísun sí OLÚWA.
13Pẹ̀lú ọrẹ ọkà rẹ tí ó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ẹ́fà (èyí jẹ́ lítà mẹ́rin ààbọ̀) ti ìyẹ̀fun, tí a fi òróró pò ọrẹ tí a fi iná ṣe fún OLÚWA òórùn dídùn pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀ tí í ṣe ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hini (Èyí jẹ́ lítà kan).
14Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àkàrà kankan tàbí kí ẹ sun ọkà tuntun títí di ọjọ́ tí ẹ fi mú ọrẹ yín wá fún Ọlọ́run yín. Èyí ni ìlànà ayérayé fún ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.
15“ ‘Ẹ ka ọ̀sẹ̀ méje gbangba, láti ọjọ́ kejì ọjọ́ ìsinmi, àní ọjọ́ tí ẹ mú sììrì ọkà fífì wá.
16Ẹ ka àádọ́ta (50) ọjọ́ títí dé ọjọ́ kejì ọ̀sẹ̀ méjèèje, kí ẹ sì mú ọrẹ ọkà titun wá fún OLÚWA.
17Láti ibikíbi tí ẹ bá ń gbé, ẹ mú ìṣù àkàrà méjì tí a fi òṣùwọ̀n ìdáméjì nínú mẹ́wàá tí ẹ́fà (Èyí jẹ́ lítà mẹ́rin ààbọ̀) ti ìyẹ̀fun, tí a fi ìwúkàrà ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì àkọ́so sí OLÚWA.
18Ẹ fi akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù, ọmọ màlúù kan àti àgbò méjì kún àkàrà yìí: wọn yóò jẹ́ ọrẹ sísun sí OLÚWA.
19Lẹ́yìn náà kí ẹ fi akọ ewúrẹ́ kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ọ̀dọ́ àgùntàn méjì ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan fún ọrẹ àlàáfíà.
20Kí àlùfáà fí ọ̀dọ́ àgùntàn méjèèjì náà níwájú OLÚWA bí i ọrẹ fífì pẹ̀lú oúnjẹ àkọ́so wọn jẹ́ ọrẹ mímọ́ sí OLÚWA fún àlùfáà.
21Ní ọjọ́ yìí náà ni kí ẹ kéde ìpàdé àjọ mímọ́: ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́ Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀ níbi yòówù tí ẹ ń gbé.
22
23OLÚWA sọ fún Mósè pé
24“Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì: ‘Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje, kí ẹ ní ọjọ́ ìsinmi, ìpàdé àjọ mímọ́ tí a fi fèrè fífọn ṣe ìrántí
25Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ ojúmọ́, ṣùgbọ́n ẹ mú ọrẹ tí a fi iná sun wá ṣíwájú OLÚWA.’ ”
26OLÚWA sọ fún Mósè pé,
27“Ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí ni ọjọ́ ètùtù. Ẹ ni ìpàdé àjọ mímọ́, kí ẹ sì ṣẹ́ ara yín kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún OLÚWA.
28Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, torí pé ọjọ́ ètùtù ni, nínú èyí tí a ń ṣe ètùtù fún yín níwájú OLÚWA Ọlọ́run yín.
29Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣẹ́ ara rẹ̀ ní ọjọ́ náà ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.
30Èmi yóò pa ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́kiṣẹ́ ní ọjọ́ náà run kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.
31Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan rárá. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.
32Ọjọ́ ìsinmi ni fún yín, ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín, láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsàn-án oṣù náà, títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, ni kí ẹ fi sinmi.”
33
34“Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé: ‘Ní ọjọ́ kẹẹdógún oṣù keje ni kí àjọ̀dún ọdún Àgọ́ ti OLÚWA bẹ̀rẹ̀ kí ó sì wà títí di ọjọ́ méje.
35Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìpàdé mímọ́: ṣẹ kò gbọdọ̀ e iṣẹ́ ojúmọ́.
36Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá, ní ọjọ́ kẹjọ ẹ pe ìpàdé mímọ́ kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún OLÚWA, èyí jẹ́ ìpàdé tí ó gbẹ̀yìn; ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ ojojúmọ́.
37(“ ‘Ìwònyí ni àwon àjọ̀dún tí OLÚWA ti yàn tí ẹ gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí i ìpàdé mímọ́ fún mímu àwọn ọrẹ tí a fi iná ṣe sí OLÚWA wá—ọrẹ sísun àti ọrẹ ọkà, ọrẹ ẹbọ àti ọrẹ ohun mímu, fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan:
38Àwọn ọrẹ wọ̀nyí wà ní àfikún pẹ̀lú àwọn ọrẹ ọjọ́ ìsinmi OLÚWA, àti pẹ̀lú ẹ̀bùn yín àti ohunkóhun tí ẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ àti gbogbo ọrẹ àtinúwá yín fún OLÚWA.)
39“ ‘Torí náà, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹẹ̀dógún osù kéje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti kórè ilẹ̀ náà, ẹ se àjọ̀dún yìí fún OLÚWA ní ọjọ́ méje. Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ kẹjọ pẹ̀lú si tún jẹ́ ọjọ́ ìsinmi.
40Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí ẹ mú àṣàyàn èso láti orí igi, igi tẹ́ẹ́rẹ́ etídò, àti ẹ̀ka igi tó rúwé, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLÚWA Ọlọ́run yín fún ọjọ́ méje.
41Ẹ ṣe èyí ní àjọ̀dún sí OLÚWA fún ọjọ́ méje lọ́dọọdún. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀: Ẹ ṣe é ní oṣù keje.
42Ẹ gbé inú àgọ́ fún ọjọ́ méje. Kí gbogbo ọmọbíbí Ísírẹ́lì gbé nínú àgọ́.
43Kí àwọn ìran yín le mọ̀ pé mo mú kí Ísírẹ́lì gbé nínú àgọ́, nígbà tí mo mú wọn jáde ní Éjíbítì. Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.’ ”
44Báyìí ni Mósè kéde àwọn àṣàyàn ọdún OLÚWA fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.