Ìwé Léfítíkù 25:1-55 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA sọ fún Mósè ní orí òkè Sínáì pé,

2ⓐ “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì wí fún wọn pé: ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún yín: ilẹ̀ náà gbọdọ̀ sinmi fún OLÚWA.

3Ọdún mẹ́fà ni kí ẹ fi gbin èso ọgbà yín, kí ẹ sì kórè èso wọn.

4Ṣùgbọ́n ní ọdún keje kí ilẹ̀ náà ní ìsinmi: ìsinmi fún OLÚWA. Ẹ má ṣe gbin èso ọgbà yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ rò wọ́n.

5Ẹ má ṣe kórè ohun tí ó tìkálárarẹ̀ hù: ẹ má ṣe kórè èso àjàrà ọgbà tí ẹ ò tọ́jú. Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ ní ìsinmi fún ọdún kan

6Ohunkóhun tí ilẹ̀ náà bá mú jáde ní ọdún ìsinmi ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún yín àní fún ẹ̀yin tìkálárayín, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin yín, àwọn alágbàṣe àti àwọn tí ń gbé pẹ̀lú yín fún ìgbàdíẹ̀.

7Fún àwọn ohun ọ̀sìn yín, àti àwọn ẹranko búburú ní ilẹ̀ yín. Ohunkóhun tí ilẹ̀ náà bá mú jáde ní ẹ lè jẹ.

8“ ‘Ọdún ìsinmi méje èyí tí í ṣe ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta ni kí ẹ kà.

9Lẹ́yìn náà, kí ẹ fọn fèrè ní gbogbo ibikíbi ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kéje ní ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́. Ní ọjọ́ ètùtù yìí, ẹ fọn fèrè yíká gbogbo ilẹ̀ yín.

10Ẹ ya àádọ́ta ọdún náà sọ́tọ̀ kí ẹ sì kéde òmìnira fún gbogbo ẹni tí ń gbé ilẹ̀ náà. Yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Kí olúkúlùkù padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀.

11Àádọ́ta ọdún ni yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Ẹ má ṣe gbin ohunkóhun, ẹ kò sì gbọdọ̀ kórè ohun tí ó hù fúnrarẹ̀ tàbí kí ẹ kórè ọgbà àjàrà tí ẹ kò dá.

12Torí pé ọdún ìdásílẹ̀ ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún yín. Ẹ jẹ ohun tí ẹ mú jáde nínú oko náà.

13“ ‘Ní ọdún idásílẹ̀ yìí, kí olúkúlùkù gbà ohun ìní rẹ̀ padà.

14“ ‘Bí ẹ bá ta ilẹ̀ fún ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín tàbí bí ẹ bá ra èyíkéyí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ.

15Kí ẹ ra ilẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn yín ní gẹ́gẹ́ bí iye owó tí ó kù kí ọdún ìdásílẹ̀ pé, kí òun náà sì ta ilẹ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí iye ọdún rẹ̀ tó kù láti kórè.

16Bí iye ọdún rẹ̀ bá gùn, kí iye owó rẹ̀ pọ̀, bí iye ọdún rẹ̀ bá kúrú, kí iye owó rẹ̀ kéré, torí pé ohun tí ó tà gan an ní iye èso rẹ̀.

17Ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ, ṣùgbọ́n ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run: Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.

18“ ‘Ẹ tẹ̀lé àwọn ìlànà mi, kí ẹ sì kíyèsí láti pa òfin mi mọ́, kí ẹ baà le máa gbé láìléwu ní ilẹ̀ náà

19Nígbà yìí ni ilẹ̀ náà yóò so èso rẹ̀, ẹ ó sì jẹ àjẹyó, ẹ ó sì máa gbé láìléwu.

20Ẹ le bèèrè pé, “Kí ni àwa ó jẹ ní ọdún keje, bí a kò bá gbin èso tí a kò sì kórè?”

21Èmi ó pèsè ìbùkún sórí yín tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ yín yóò so èso tó tó fún ọdún mẹ́ta lẹ́yìn rẹ̀.

22Bí ẹ bá gbin èso yín ní ọdún kejọ, àwọn èso ti tẹ́lẹ̀ ní ẹ ó máa jẹ, títí tí ìkórè ti ọdún kẹsàn-án yóò fi dé.

23“ ‘Ẹ má ṣe ta ilẹ̀ yín ní àtàpa torí pé ẹ̀yin kọ́ lẹ ni-ín, ti Ọlọ́run ni, ẹ̀yin jẹ́ àlejò àti ayálégbé,

24Ní gbogbo orílẹ̀ èdè ìní yín, ẹ fi àyè sílẹ̀ fún ìràpadà ilẹ̀ náà.

25“ ‘Bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín bá talákà, débi pé ó ta ara àwọn ẹrù rẹ̀, kí ará ilé rẹ̀ tí ó sún mọ́ ọ ra ohun tí ó tà padà.

26Ẹni tí kò ní ẹni tó lè ràápadà fún un, tí òun fúnrarẹ̀ sì ti lọ́rọ̀, tí ó sì ní ànító láti rà á.

27Kí ó mọ iye owó tí ó jẹ fún iye ọdún tí ó tà á, kí ó dá iye tí ó kù padà fún ẹni tí ó tà á fún: lẹ́yìn náà, ó lè padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

28Ṣùgbọ́n bí kò bá rí ọ̀nà àti san án padà fún un. Ohun tí ó tà wà ní ìkáwọ́ ẹni tí ó ràá títí di ọdún ìdásílẹ̀. Kí ó dáa padà fún ẹni tí ó ni i ní ọdún ìdásílẹ̀, ẹni tí ó ni í tẹ́lẹ̀ lè tún padà gbà ohun ìní rẹ̀.

29“ ‘Bí arákùnrin kan bá ta ilẹ̀ tí ó wà nínú ìlú, ó ní ẹ̀tọ́ láti rà á padà láàrin ọdún kan sí àkókò tí ó tà á.

30Ṣùgbọ́n bí kò bá rà á padà láàrin ọdún náà ilé náà tí ó wà láàrin ìlú ni kí ó yọ̀ǹda pátapáta fún ẹni tí ó rà á, àti àwọn ìdílé rẹ̀. Kí wọ́n má da padà ní ọdún ìdásílẹ̀.

31Ṣùgbọ́n àwọn ilé tí ó wà ní abúlé láìní odi ni kí a kà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ oko, a lè rà wọ́n padà, kí wọ́n sì da padà ní ọdún ìdásílẹ̀.

32“ ‘Àwọn ọmọ Léfì ní ẹ̀tọ́, nígbàkugbà láti ra ilẹ̀ wọn, tí ó jẹ́ ohun ìní wọn ní àwọn ìlú tí ó jẹ́ ti ọmọ Léfì.

33Torí náà ohun ìní àwọn ọmọ Léfì ni wọ́n rà padà, fún àpẹẹrẹ, èyí ni pé ilẹ̀ tí a bá tà ní ìlúkílú tí ó jẹ́ tiwọn, ó sì gbọdọ̀ di dídápadà ní ọdún ìdásílẹ̀, torí pé àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní ìlú àwọn Léfì ni ìní wọn láàrin àwọn ará Ísírẹ́lì

34Ṣùgbọ́n ilẹ̀ tí wọ́n ti ń da ẹran tí ó jẹ́ ti ìlú wọn, wọn kò gbọdọ̀ tà wọ́n, ilẹ̀ ìní wọn láéláé ni.

35ⓑ “ ‘Bí arákùnrin yín kan bá talákà tí kò sì le è pèsè fún àìní ara rẹ̀: ẹ pèsè fún un bí ẹ ti ń ṣe fún àwọn àlejò tàbí àwọn tí ẹ gbà sílé: kí ó baà leè máa gbé láàrin yín.

36ⓒ Ẹ kò gbọdọ̀ gba èlé kankan lọ́wọ́ rẹ̀: ẹ bẹ̀rù OLÚWA kí arákùnrin yín leè máa gbé láàrin yín.

37Ẹ má ṣe gba èlé lórí owó tí ẹ yá a bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ èrè lórí oúnjẹ tí ẹ tà fún un.

38Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì láti fún yín ní ilẹ̀ Kénánì àti láti jẹ́ Ọlọ́run yín.

39ⓓ “ ‘Bí arákùnrin yín kan bá talákà débi pé ó ta ara rẹ̀ fún ọ bí ẹrú. Má se lò ó bí ẹrú.

40Jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ rẹ bí alágbàṣe tàbí àlejò láàrin yín: kí ó máa ṣiṣẹ́ sìn ọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀.

41Nígbà náà ni kí ó yọ̀ǹda òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọ́n padà sí ìdílé wọn àti sí ilẹ̀ ìní bàbá wọn.

42Torí pé ìránṣẹ́ mi ni àwọn ará Ísírẹ́lì jẹ́. Ẹni tí mo mú jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, torí èyí ẹ kò gbọdọ̀ tà wọ́n lẹ́rú.

43Ẹ má ṣe rorò mọ́ wọn: ṣùgbọ́n ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run yín.

44“ ‘Àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín lè jẹ́ láti orílẹ̀ èdè tí ó yí yín ká: Ẹ lè ra àwọn ẹrú wọ̀nyí lọ́wọ́ wọn.

45Bákan náà, ẹ sì le è ra àwọn àlejò tí ń gbé láàrin yín, àti àwọn ìdílé wọn tí a bí sáàrin yín. Wọn yóò sì di ohun ìní yín.

46Ẹ lè fi wọ́n sílẹ̀ bí ogún fún àwọn ọmọ yín; Wọ́n sìle sọ wọ́n di ẹrú títí láé. Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rorò mọ́ ọmọ Ísírẹ́lì kankan.

47“ ‘Bí àlejò kan láàrin yín tàbí ẹni tí ń gbé àárin yín fún ìgbà díẹ̀ bá lọ́rọ̀ tí ọmọ Ísírẹ́lì sì talákà débi pé ó ta ara rẹ̀ lẹ́rú fún àlejò tàbí ìdílé àlejò náà.

48Ó lẹ́tọ́ si ki a rà á padà lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ta ara rẹ̀. Ọ̀kan nínú ìbátan rẹ̀ le è rà á padà.

49Àbúrò bàbá rẹ̀ ọkùnrin tàbí àbúrò rẹ̀ obìnrin tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá a tan nínú ìdílé rẹ̀ le è rà á padà: Bí ó bá sì ti là (Lówólọ́wọ́) ó lè ra ara rẹ̀ padà.

50Kí òun àti olówó rẹ̀ ka iye ọdún tí ó ta ara rẹ̀ títí dé ọdún ìdásílẹ̀ kí iye owó ìdásílẹ̀ rẹ̀ jẹ́ iye tí wọ́n ń san lórí alágbàṣe fún iye ọdún náà.

51Bí iye ọdún rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù bá pọ̀, kí iye owó fún ìràpadà rẹ̀ pọ̀.

52Bí ọdún rẹ̀ kò bá pọ̀ sí àkókò ìdásílẹ̀, kí ó ṣe ìṣírò rẹ̀, kí ó sì san owó náà bí iye ìṣírò rẹ̀.

53Bí ẹ ti ń ṣe sí i lọ́dọọdún, ẹ rí i dájú pé olówó rẹ̀ kò korò mọ́ ọ.

54“ ‘Bí a kò bá rà á padà nínú gbogbo ọ̀nà wọ̀nyí, kí ẹ tú òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ ní ọdún ìdásílẹ̀.

55Torí pé ìránṣẹ́ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ fún mi. Ìránṣẹ́ mi ni wọ́n, tí mo mú jáde láti Éjíbítì wá. Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
/div>