Ìwé Léfítíkù 27:1-34 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA sọ fún Móse pé.

2“Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Bí ẹnìkan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì láti ya ènìyàn kan sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run nípa sísan iye tí ó tó,

3kí iye owó ọkùnrin láti ọmọ ogún ọdún sí ọgọ́ta ọdún jẹ́ àádọ́ta òṣùnwọ̀n Ṣékélì fàdákà, gẹ́gẹ́ bí oṣùwọ̀n sékélì ti ibi mímọ́ OLÚWA;

4Bí ẹni náà bá jẹ obìnrin, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n òṣùwọ̀n sékéli.

5Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún sí ogún ọdún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ ogún ṣékélì fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin.

6Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ oṣù kan sí ọdún márùn-ún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà márùn-ún fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà mẹ́ta fún obìnrin.

7Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọgọ́ta ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́ẹ̀dógún fún ọkunrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin.

8Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ bá tálákà púpọ̀ débi pé kò lè san iye owó náà, kí a mú ẹni náà wá ṣíwájú àlùfáà, àlùfáà yóò sì dá iye owó tí ó lè san lé e gẹ́gẹ́ bí agbára ẹni náà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́.

9“ ‘Bí ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́ bá jẹ́ ẹranko èyí tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ̀gbà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLÚWA, irú ẹran bẹ́ẹ̀ tí a bá fi fún OLÚWA di mímọ́.

10Ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ náà kò gbọdọ̀ pàrọ̀ ẹran mìíràn, yálà kí ó pàrọ̀ èyí tí ó dára sí èyí tí kò dára tàbí èyí tí kò dára sí èyí tí ó dára. Bí ó bá se bẹ́ẹ́ ti OLÚWA ni ẹranko méjèèjì.

11Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ níti ẹranko àìmọ́ tí a fi tọrẹ: èyí tí kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà bí i ọrẹ fún OLÚWA. Kí ọkùnrin náà mú ọrẹ náà lọ fún àlùfáà.

12Kí àlùfáà díye lé e, gẹ́gẹ́ bí ó ti dára tàbí bí ó ti bàjẹ́ sí. Iye owó náà ni kí ó jẹ́.

13Bí ẹni náà bá fẹ́ rà á padà: ó gbọdọ̀ san iye owó rẹ̀ àti ìdá ogún iye owó náà láfikún.

14“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ya ilẹ̀ rẹ̀ sí mímọ́ fún OLÚWA: kí àlùfáà kó sọ iye tí yóò san gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ náà ti dára tàbí bàjẹ́ sí: iye owó náà ni kí ó jẹ́.

15Bí ẹni tí ó yá ilé náà sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà. Jẹ́ kí ó fi ìdámárùn ún owó ìdíyelé rẹ̀ kún ún, yóò si jẹ́ tirẹ̀.

16“ ‘Bí ẹnìkan bá sì ya ara ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún OLÚWA. Iye tí ó bá jẹ́ ni kí wọ́n sètò gẹ́gẹ́ bí iye èso tí a ó fi gbìn ín. Àádọ́ta ṣékélì fàdákà fún òṣùwọ̀n ómà èso bárílì.

17Bí ó ba ṣe pé ní ọdún ìdásílẹ̀ ni ó yà ilẹ̀ náà sí mímọ́. Iye owó tí wọn sọ tẹ́lẹ̀ náà ni kí o san.

18Bí ó bá ya ilẹ̀ náà sí mímọ́ lẹ́yìn ọdún ìdásílẹ̀ kí àlùfáà sọ iye owó tí yóò san fún ọdún tó kù kí ọdún ìdásílẹ̀ mìíràn tó pé iye owó tí ó gbọdọ̀ jẹ yóò dínkù.

19Bí ẹni tí ó ya ilẹ̀ sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà: kí ó san iye owó náà pẹ̀lú àfikún ìdá márùn-ún. Ilẹ̀ náà yóò sì di tirẹ̀.

20Bí kò bá ra ilẹ̀ náà padà tàbí bí ó bá tàá fún ẹlòmíràn kò le è ri rà padà mọ́.

21Bí a bá fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ ní ọdún ìdásílẹ̀ yóò di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ tí a fi fún OLÚWA. Yóò sì di ohun ìní àlùfáà.

22“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ya ilẹ̀ tí ó ti rà tí kì í ṣe ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún OLÚWA.

23Kí àlùfáà sọ iye tí ó tọ títí di ọdún ìdásílẹ̀. Kí ọkùnrin náà sì san iye owó náà ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ sí OLÚWA.

24Ní ọdún ìdásílẹ̀ ilẹ̀ náà yóò padà di ti ẹni tí ó ni ín, lọ́wọ́ ẹni tí a ti rà á.

25Gbogbo iye owó wọ̀nyí gbọdọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ṣékélì ibi mímọ́ (ogún gera).

26“ ‘Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ ya gbogbo àkọ́bí ẹran sí mímọ́. Èyí jẹ́ ti OLÚWA nípaṣẹ̀ òfin àkọ́bí: yálà kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni tàbí àgùntàn, ti OLÚWA ni.

27Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹran tí kò mọ́, nígbà náà ni kí ó rà á padà gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé rẹ̀, kí ó sì fi ìdámárùn-ún lé e, tàbí bí a kò bá rà á padà kí ẹ tà á gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé rẹ̀.

28ⓐ “ ‘Ohun tí a bá yà sí mímọ́ pátapáta láti ọwọ́ ẹnikẹ́ni sí OLÚWA tàbí ẹranko tàbí ilẹ̀ tí ó jogún: òun kò gbọdọ̀ tàá kí ó rà á padà. Gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ bẹ́ẹ̀ di mímọ́ jùlọ fún OLÚWA.

29“ ‘Ẹni tí ẹ bá ti yà sọ́tọ̀ fún pípa, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ràá padà, pípa ni kí ẹ paá.

30ⓑ “ ‘Gbogbo ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà yálà tí èso ilẹ̀ ni, tàbí tí èso igi, ti OLÚWA ni. Mímọ́ ni fún OLÚWA.

31Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ra ìdámẹ́wàá nǹkan rẹ̀ padà: o gbọdọ̀ fi márùn-ún kún un.

32Gbogbo ìdámẹ́wàá àgbò àti ẹran ọ̀sìn, àní ìdámẹ́wàá ẹran tó bá kọjá lábẹ́ ọ̀pá darandaran kí ó jẹ́ mímọ́ fún OLÚWA.

33Ènìyàn kò gbọdọ̀ wádìí bóyá ó dára tàbí kò dára, kò sì gbọdọ̀ pààrọ̀ rẹ̀. Bí ó bá pààrọ̀ rẹ̀: àti èyí tí ó pààrọ̀ àti èyí tí ó fi pààrọ̀ ni kí ó jẹ́ mímọ́. Wọn kò gbọdọ̀ rà á padà.’ ”

34Àwọn àṣẹ wọ̀nyí ni OLÚWA pa fún Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní orí òkè Sínáì.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
/div>