1
2“Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe àìsòótọ́ sí OLÚWA nípa títan ẹnìkejì rẹ̀ lórí ohun tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ tàbí tí wọ́n fi pamọ́ sí i lọ́wọ́, tàbí bí ó bá jalè, tàbí kí ó yan ẹnìkejì rẹ̀ jẹ,
3tàbí kí ó rí ohun tó sọnù he tó sì parọ́ tàbí kí ó búra èké, tàbí kí ó tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ kan, irú èyí tí ènìyàn lè ṣẹ̀.
4Bí ó bá dẹ́ṣẹ̀ báyìí tó sì jẹ̀bi, ó gbọdọ̀ dá ohun tó jí tàbí ohun tó fi agbára gbà, tàbí ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ̀, tàbí ohun tó sọnù tó rí he,
5tàbí ohunkóhun tó búra èké lé lórí. Ó gbọdọ̀ dá gbogbo rẹ̀ padà ní pípé, kí ó fi ìdá márùn ún iye rẹ̀ kún, kí ó sì dá gbogbo rẹ̀ padà fún ẹni tí ó ni í, ní ọjọ́ tó bá ń rú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀.
6Fún ìtanràn rẹ̀, ó gbọdọ̀ mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá fún àlùfáà, àní ṣíwájú OLÚWA, ọrẹ fún ẹ̀ṣẹ̀ àgbò aláìlábùkù, tó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́.
7Báyìí ní àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún un ètùtù ìwẹ̀nùmọ́ níwájú OLÚWA, a ó sì dárí jìn-ní nítorí ohun tó ti ṣe tó sì mú-un jẹ̀bi.”
8OLÚWA sọ fún Mósè pé:
9“Pàṣẹ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé: Èyí ni ìlànà fún ẹbọ sísun; ẹbọ sísun gbọdọ̀ wà lórí pẹpẹ láti alẹ́ di òwúrọ̀, kí iná sì máa jó lórí pẹpẹ
10kí àlùfáà sì wọ èwù funfun rẹ̀ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ lára rẹ̀, yóò sì kó eérú tó wà nibi ẹbọ sísun tí iná ti jó lórí pẹpẹ, sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.
11Nígbà náà ni yóò bọ́ aṣọ rẹ̀, yóò sì wọ òmíràn, yóò wá gbé eérú náà lọ sí ẹ̀yìn ibùdó níbi tí a kà sí mímọ́.
12Iná tó wà lórí pẹpẹ gbọdọ̀ máa jó, kò gbọdọ̀ kú, ní àràárọ̀ ni kí àlùfáà máa to igi si, kí ó sì to ẹbọ sísun sórí iná, kí ó sì máa sun ọ̀rá ẹran ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀.
13Iná gbọdọ̀ máa jó lórí pẹpẹ títí, kò gbọdọ̀ kú.
14“Ìwọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ohun jíjẹ, kí àwọn ọmọ Árónì gbé ẹbọ sísun náà wá ṣíwájú OLÚWA níwájú pẹpẹ.
15Kí àlùfáà bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kíkúná dáradára àti òróró pẹ̀lú gbogbo tùràrí tó wà lórí ẹbọ ohun jíjẹ náà kí ó sì sun ẹbọ ìrántí náà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí OLÚWA.
16Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò jẹ ìyókù ṣùgbọ́n wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́ láì sí máa wú máa wú ohun tí n mú àkàrà wú nínú rẹ̀ ní ibi mímọ́, ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé ni kí wọn ó ti jẹ ẹ́.
17Ẹ má ṣe ṣè é pẹ̀lú yíìsìtì. Èmi ti fún àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nínú ẹbọ tí a fi iná sun sí mi! Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe jẹ́.
18Èyíkéyí nínú àwọn ọmọkùnrin ìran Árónì ló le jẹ ẹ́. Èyí ni ìpín rẹ tí ó gbọdọ̀ máa ṣe déédé lára àwọn ẹbọ tí a fi iná sun sí OLÚWA láti ìrandíran. Ohunkóhun tí ó bá kàn án yóò di mímọ́.”
19OLÚWA sọ fún Mósè pé,
20“Èyí ni ọrẹ tí Árónì àti àwọn ọmọ rẹ gbọdọ̀ mú wá fún OLÚWA ní ọjọ́ tí a bá fi òróró yan ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; ìdámẹ́wàá òsùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára fún ẹbọ ohun jíjẹ lójoojúmọ́, ìdajì rẹ̀ ní àárọ̀ àti ìdajì rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́.
21Ẹ pèsè rẹ̀ pẹ̀lú òróró nínú àwo fífẹ̀, ẹ pò ó pọ̀ dáradára, kí ẹ sì gbé ọrẹ ohun jíjẹ náà wá ní ègé kéé-kèè-kéé bí òórùn dídùn sí OLÚWA.
22Ọmọkùnrin Árónì tí yóò rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tí a fi òróró yàn ni yóò rú ẹbọ náà. Ó jẹ́ ìpín ti OLÚWA títí láé, wọn sì gbọdọ̀ sun ún pátapáta.
23Gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ ti àlùfáà ni wọ́n gbọdọ̀ sun pátapáta, wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.”
24OLÚWA sọ fún Mósè pé:
25“Sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ Ọkùnrin: ‘Wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kí ẹ sì pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níwájú OLÚWA níbi tí ẹ ti ń pa ẹran ẹbọ sísun, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.
26Àlùfáà tó rú ẹbọ náà ni kí ó jẹ ẹ́, ibi mímọ́ ni kí ó ti jẹ ẹ́, ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé.
27Ohunkóhun tí ó bá kàn án yóò di mímọ́, bí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ bá sì ta sí ara aṣọ kan, ẹ gbọdọ̀ fọ̀ ọ́ ní ibi mímọ́.
28Ẹ gbọdọ̀ fọ́ ìkòkò amọ̀ tí ẹ fi ṣe ẹran náà, ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìkòkò idẹ ni ẹ fi ṣe é, ẹ gbọdọ̀ bó o, kí ẹ sì fi omi sìn ín dáradára.
29Gbogbo ọkùnrin ní ìdílé àlùfáà ló lè jẹ ẹ́, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.
30Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kankan, èyí tí wọ́n bá mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sínú àgọ́ ìpàdé láti fi ṣe ètùtù ní ibi mímọ́, sísun ni kí ẹ sun ún.