Ìwé Léfítíkù 8:1-36 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ  OLÚWA sọ fún Mósè pé,

2“Mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, aṣọ wọn, òróró ìtasórí, akọ mààlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò méjì àti apẹ̀rẹ̀ tí a kó àkàrà aláìwú sínú rẹ̀.

3Kí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn jọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.”

4Mósè sì ṣe bí OLÚWA ti pa á láṣẹ fún un, gbogbo ènìyàn sì péjọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.

5Mósè sì sọ fún ìjọ ènìyàn pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA ti pa láṣẹ pé kí á ṣe.”

6Nígbà náà ni Mósè mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá ṣíwájú, ó sì fi omi wẹ̀ wọ́n.

7Ó sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Árónì, ó fi àmùrè dì í, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ìgúnwà, ó sì tún wọ̀ ọ́ ni aṣọ ìlékè oyè àlùfáà tí ó ní ìgbànú tí a ṣe ọnà dáradára sí.

8Ó fi ìgbàyà sí àyà rẹ̀, ó sì fi Úrímù àti Júmímù síbi ìgbàyà náà.

9Ó dé e ní fìlà, ó sì fi àwo wúrà tíí ṣe adé mímọ́ ṣíwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mósè.

10Mósè sì fi òróró ìtasórí ya àgọ́ àti ohun gbogbo tó wà nínú rẹ̀ sí mímọ́.

11Ó wọ́n díẹ̀ nínú òróró yìí sórí pẹpẹ lẹ́ẹ̀meje, ó ta òróró sórí pẹpẹ àti gbogbo ohun èlò àti agbada pẹ̀lú ohun tó gbé agbada yìí dúró láti lè yà á sí mímọ́,

12ó da díẹ̀ lára òróró ìtasórí yìí sórí Árónì, ó sì yà á sí mímọ́.

13Lẹ́yìn èyí ló mú àwọn ọmọ Árónì wá ṣíwájú, ó sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n, ó fi àmùrè dì wọ́n lára, ó fi fìlà dé wọn lórí gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mósè.

14Ó sì mú akọ mààlúù wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí ẹran náà.

15Mósè pa akọ màlúù náà, ó sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí gbogbo ìwo pẹpẹ láti wẹ pẹpẹ náà mọ́. Ó da ìyóòkù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ ní ó ṣe yà á sí mímọ́ láti ṣe ètùtù fún un.

16Mósè tún mú gbogbo ọ̀rá tó bo nǹkan inú, èyí tó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn, ó sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ.

17Ṣùgbọ́n akọ màlúù yìí pẹ̀lú àwọ àti ara ẹran àti ìgbẹ́ rẹ̀ ní ó sun lẹ́yìn ibùdó gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pa á láṣẹ fún Mósè.

18Lẹ́yìn náà ló mú àgbò wá fún ẹbọ sísun Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí àgbò náà.

19Mósè sì pa àgbò náà, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí pẹpẹ náà ká.

20Ó gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ó sì sun orí àti àwọn ègé àti ọ̀rá rẹ̀.

21Ó fi omi fọ gbogbo nǹkan inú àti ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó sì sun odidi àgbò náà lórí pẹpẹ bí ẹbọ sísun òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná se sí OLÚWA gẹ́gẹ́ bí OLÚWA tí pàṣẹ fún Mósè.

22Ó sì mú àgbò kejì wa, èyí ni àgbò ìfinijoyè àlùfáà, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé e lórí.

23Mósè sì pa àgbò náà, ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀, ó tọ́ ọ sí ètí ọ̀tún Árónì, sórí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti ti ẹṣẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.

24Mósè sì tún mú àwọn ọmọ Árónì wá ṣíwájú, ó sì mú ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ ó fi sí etí ọ̀tún wọn, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ yí pẹpẹ náà ká.

25Ó mú ọ̀rá ẹran náà, ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, gbogbo ọ̀rá tó wà lára nǹkan inú àti èyí tó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn pẹ̀lú itan ọ̀tún.

26Lẹ́yìn náà ló mú àkàrà aláìwú sí, èyí tó wà níwájú OLÚWA àti àkàrà tí a fi òróró ṣe, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì kó gbogbo rẹ̀ sórí ọ̀rá àti itan ọ̀tún ẹran náà.

27Ó kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí lé Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLÚWA.

28Lẹ́yìn náà, Mósè gba gbogbo rẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ó sì sun wọn lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìfinijoyè àlùfáà òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná sun sí OLÚWA.

29Mósè sì mú igẹ̀ ẹran náà, èyí tó jẹ́ ìpín rẹ̀ nínú àgbò fún ìfinijoyè, ó sì fìí níwájú OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, bi OLÚWA ti pàṣẹ fún Mósè.

30Mósè sì mú díẹ̀ lára òróró ìtasórí àti díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ láti orí pẹpẹ, ó wọ́n sára àwọn ọmọ Árónì àti aṣọ rẹ̀, ó sì tún wọ́n sára àwọn ọmọ Árónì àti aṣọ wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Mósè ya Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ wọn sí mímọ́.

31Mósè sì sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe ẹran náà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbẹ̀ pẹ̀lú àkàrà tí a mú láti inú apẹ̀rẹ̀ ọrẹ ìfinijoyè àlùfáà gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ pé, ‘Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó jẹ ẹ́.’

32Kí ẹ fi iná sun ìyóòkù àkàrà àti ẹran náà.

33Ẹ má ṣe kúrò ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje, títí tí ọjọ́ ìfinijoyè àlùfáà yín yóò fi pé, nítorí pé ìfinijoyè àlùfáà yín yóò gba ọjọ́ méje gbáko.

34Ohun tí a ṣe lónìí jẹ́ ohun tí OLÚWA ti pa láṣẹ láti ṣe ètùtù fún yín.

35Ẹ gbọdọ̀ wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé lọ́sàn án àti lóru fún ọjọ́ méje kí ẹ sì ṣe ohun tí OLÚWA fẹ́, kí ẹ má ba à kú, nítorí ohun tí OLÚWA pa láṣẹ fún mi ni èyí.”

36Báyìí ni Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ohun gbogbo tí OLÚWA pa láṣẹ láti ẹnu Mósè.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>