1
2
3Òun yóò sì jókòó bí ẹni tí n yọ́, tí ó sì ń da fàdákà; yóò wẹ àwọn ọmọ Léfì mọ́, yóò sì tún wọn dà bí wúrà àti fàdákà, kí wọn bá a lè mú ọrẹ òdodo wá fún OLÚWA,
4nígbà náà ni ọrẹ Júdà àti ti Jérúsálẹ́mù yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ àtijọ́, àti gẹ́gẹ́ bí ọdún ìgbàanì.
5“Èmi ó sì súnmọ́ yin fún ìdájọ́. Èmi yóò sì yára ṣe ẹlẹ́rìí sí àwọn oṣó, sí àwọn panṣágà, sí àwọn abúra èké, àti àwọn tí ó fi ọ̀yà alágbàṣe dù ú, àti àwọn tí ó ni àwọn opó àti àwọn aláìní baba lara, àti sí ẹni tí kò jẹ́ kí àlejò rí ìdájọ́ òdodo gbà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi,” ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí.
6“Èmi OLÚWA kò yípadà. Nítorí náà ni a kò ṣe run ẹ̀yin ọmọ Jákọ́bù.
7Láti ọjọ́ àwọn baba-ńlá yín wá ni ẹ̀yin tilẹ̀ ti kọ ẹ̀yìn sí ìlànà mi, tí ẹ kò sì pa wọ́n mọ́. Ẹ padà wá sí ọ̀dọ̀ mi, Èmi yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,” ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí.
8“Ènìyàn yóò ha ja Ọlọ́run ni olè bí? Ṣíbẹ̀ ẹ̀yin ti jà mí ní olè.
9Ríré ni a ó fi yín ré: gbogbo orílẹ̀ èdè yìí, nítorí ẹ̀yin ti jà mi lólè.
10Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ báà lè wà ní ilé mi, ẹ fi èyí dán mi wò,” ní OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí, “kí ẹ sì wò bí èmi kò bá ní sí àwọn fèrèsé ọ̀run fún yin, kí èmi sì tú ìbùkún àkúnwọ́ sílẹ̀ jáde fún yín, tóbẹ́ẹ̀ tí kì yóò sì àyè láti gbà á.
11Èmi yóò sì bá kòkòrò ajẹnirun wí nítorí yín, òun kò sì ni run èso ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni àjàrà inú oko yín kò ní rẹ̀ dànù,” ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí.
12“Nígbà náà ni gbogbo orílẹ̀ èdè yóò sì pè yín ni alábùkún fún, nítorí ti yín yóò jẹ́ ilẹ̀ tí ó wuni,” ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí.
13“Ẹ̀yin ti sọ ọ̀rọ̀ líle sí mi,” ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí.
14“Ẹ̀yín ti wí pé, ‘Asán ni láti sin Ọlọ́run. Kí ni àwa jẹ ní èrè, nígbà tí àwa ti pa ìlànà rẹ mọ́, tí àwa sì ń rìn kiri bí ẹni tí ń sọ̀fọ̀ ní iwájú OLÚWA àwọn ọmọ ogun?
15Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí àwa pé agbéraga ni alábùkún fún Ní otitọ ni àwọn ti ń ṣe búburú ń gbèrú sí i, kódà àwọn ti ó dán OLÚWA wò ni a dá sí.’ ”
16Nígbà náà ni àwọn tí ó bẹ̀rù OLÚWA ń ba ara wọn sọ̀rọ̀, Olúwa sì tẹ́tí sí i, ó sì gbọ́. A sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀, fún àwọn tí o bẹ̀rù OLÚWA, ti wọn sì bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀.
17“Wọn yóò sì jẹ́ tèmi,” ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí, “ni ọjọ́ náà, tí èmi ó dá; èmi yóò sì da wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí máa ń dá ọmọ rẹ̀ tí yóò ń sìn ín sí.
18Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rí ìyàtọ̀, ìyàtọ̀ láàrin olódodo àti ẹni búburú, láàrin ẹni tí ń sìn Ọlọ́run, àti ẹni tí kò sìn ín.