Ìwé Nọ́ḿbà 16:1-50 BYB2014 - Bible AI

1Kórà ọmọ Íṣárì, ọmọ Kóhátì, ọmọ Léfì àwọn ọmọ Rúbẹ́nì: Dátanì àti Ábírámù, àwọn ọmọ Élíábù, àti Ónù ọmọ Pélétì mú ènìyàn mọ́ra.

2Wọ́n sì dìde sí Mósè, Pẹ̀lú àádọ́tàlénígba (250) ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gbajúmọ̀ nínú ìgbìmọ̀ ìlú.

3Wọ́n kó ara wọn jọ láti tako Mósè àti Árónì, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ti kọjá ààyè yín, ó tó gẹ́ ẹ́! Mímọ́ ni gbogbo ènìyàn, kò sí ẹni tí kò mọ́ láàrin wọn, OLÚWA sì wà pẹ̀lú wọn, nítorí kí wá ni ẹ̀yin ṣe gbé ara yín ga ju ìjọ ènìyàn OLÚWA lọ?”

4Nígbà tí Mósè gbọ́ èyí, ó dojú bolẹ̀,

5ⓐ Ó sì sọ fún Kórà àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ní ọ̀la ni OLÚWA yóò fi ẹni tí í ṣe tirẹ̀ àti ẹni tó mọ́ hàn, yóò sì mú kí ẹni náà súnmọ́ òun. Ẹni tí ó bá yàn ni yóò mú kí ó súnmọ́ òun.

6Kí Kórà àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe èyí, Ẹ mú àwo tùràrí.

7Kí ẹ sì fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀ lọ́la níwájú OLÚWA, yóò si se, ọkùnrin tí OLÚWA bá yàn oun ni. Ẹ̀yin ọmọ Léfì, ẹ ti kọjá ààyè yín!”

8Mósè sì tún sọ fún Kórà pé, “Ẹ gbọ́ báyìí o, ẹ̀yin ọmọ Léfì!

9Kò ha tọ́ fún yín pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti yà yín sọ́tọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóòkù, tó sì mú yín súnmọ́ ara rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ OLÚWA àti láti dúró ṣiṣẹ́ ìsìn níwájú àwọn ènìyàn?

10Ó ti mú àwọn ènìyàn yín tó jẹ́ ọmọ Léfì súnmọ́ ara rẹ̀, ṣùgbọ́n báyìí ẹ tún ń wá ọnà láti ṣiṣẹ́ àlùfáà.

11OLÚWA ni ìwọ àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ takò. Ta a ni Árónì jẹ́ tí ẹ̀yin ó fi kùn sí i?”

12Mósè sì ránṣẹ́ sí Dátanì àti Ábírámù àwọn ọmọ Élíábù. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé “Àwa kò ní í wá!

13Kò ha tó gẹ́ ẹ́ pé o ti mú wa jáde láti ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin láti pa wá sínú ihà yìí? O tún wá fẹ́ sọ ara rẹ di OLÚWA lé wa lórí bí?

14Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ ìwọ kò sì tí ì mú wa dé ilẹ̀ tó ń ṣàn fún wàrà àti oyin, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì pín ilẹ̀ ìní wa fún wa. Ìwọ ha fẹ́ sọ wá di ẹrú bí? Rárá o, àwa kò ní wá!”

15Nígbà náà ni Mósè bínú gidigidi, ó sì sọ fún OLÚWA pé, “Má ṣe gba ọrẹ wọn, èmi kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́wọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì pa ẹnikẹ́ni nínú wọn lára!”

16Mósè sọ fún Kórà pé, “Ìwọ àti ọmọ lẹ́yìn rẹ gbọdọ̀ fara hàn níwájú OLÚWA lọ́la—gbogbo yín, ìwọ, àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ àti Árónì.

17Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín mú àwo tùràrí, kí ó sì fi tùràrí sínú rẹ̀, kí gbogbo rẹ̀ jẹ́ àádọ́tàlénígba àwo tùràrí (250) kí ẹ sì ko wá ṣíwájú OLÚWA. Ìwọ àti Árónì yóò mú àwo tùràrí wá pẹ̀lú.”

18Nígbà náà ni oníkálukú wọn mú àwo tùràrí, wọ́n fi iná àti tùràrí sí i nínú, wọ́n sì dúró sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé, àwọn pẹ̀lú Mósè àti Árónì.

19Nígbà tí Kórà kó gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé, ògo OLÚWA sì farahan gbogbo ìjọ ènìyàn.

20OLÚWA sì sọ fún Mósè àti Árónì pé,

21“Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn wọ̀nyí, kí ń ba à le pa wọ́n run lẹ́ẹ̀kan náà.”

22Ṣùgbọ́n Mósè àti Árónì dojúbolẹ̀ wọ́n sì kígbe sókè pé, “Ọlọ́run, Ọlọ́run ẹ̀mi gbogbo ènìyàn, Ìwọ ó wa bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn nígbà tó jẹ́ pé ẹnì kan ló ṣẹ̀?”

23OLÚWA tún sọ fún Mósè pé,

24“Sọ fún ìjọ ènìyàn pé, ‘Kí wọ́n jìnnà sí àgọ́ Kórà, Dátanì àti Ábírámù.’ ”

25Mósè sì dìde lọ bá Dátanì àti Ábírámù àwọn olórí Ísírẹ́lì sì tẹ̀lé.

26Ó sì kìlọ̀ fún ìjọ ènìyàn pé, “Ẹ kúrò ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú yìí! Ẹ má ṣe fọwọ́ kan ohun kan tí í ṣe tiwọn kí ẹ má ba à parun nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

27Àwọn ènìyàn sì sún kúrò ní àgọ́ Kórà, Dátanì àti Ábírámù. Dátanì àti Ábírámù jáde, àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọ wọn sì dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn.

28Nígbà náà ni Mósè wí pé, “Báyìí ni ẹ ó ṣe mọ̀ pé OLÚWA ló rán mi láti ṣe gbogbo iṣẹ́ wọ̀nyí àti pé kì í ṣe ìfẹ́ inú mi ni àwọn ohun tí mò ń ṣe.

29Bí àwọn ènìyàn yìí bá kú bí gbogbo ènìyàn ti ń kú, bí ìrírí wọn kò bá sì yàtọ̀ sí ti àwọn ènìyàn yóòkù, a jẹ́ pé kì í ṣe OLÚWA ló rán mi.

30Ṣùgbọ́n bí OLÚWA bá ṣe ohun túntún, tí ilẹ̀ sì la ẹnu, tó gbé wọn mì, àwọn pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ní, tí wọ́n sì wọ inú ibojì wọn lọ láàyè, nígbà náà ni ẹ̀yin ó mọ̀ pé àwọn ènìyàn yìí ti kẹ́gàn OLÚWA.”

31Bí ó sì ṣe parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ilẹ̀ pín sí méjì nísàlẹ̀ wọn,

32ilẹ̀ sì lanu ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ará ilé wọn àti àwọn ènìyàn Kórà àti gbogbo ohun tí wọ́n ní.

33Gbogbo wọn sì sọ̀kalẹ̀ sínú ibojì wọn láàyè pẹ̀lú ohun gbogbo tí wọ́n ní, ilẹ̀ sì padé mọ́ wọn, wọ́n sì ṣègbé kúrò láàrin ìjọ ènìyàn.

34Nígbà tí àwọn yóòkù gbọ́ igbe wọn, wọ́n sálọ, wọ́n wí pé, “Ilẹ̀ yóò gbé àwa náà mì pẹ̀lú.”

35Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ OLÚWA ó sì run àádọ́tàlénígba ọkùnrin (250) tí wọ́n mú tùràrí wá.

36OLÚWA sọ fún Mósè pé,

37“Sọ fún Élíásárì ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà, pé kí ó mú àwọn àwo tùràrí jáde kúrò nínú iná nítorí pé wọ́n jẹ́ mímọ́, kí ó sì tan iná náà káàkiri síbi tó jìnnà.

38Èyí ni àwo tùràrí àwọn tí ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kí ẹ gún àwo tùràrí yìí, kí ẹ sì fi ṣe ìbòrí fún pẹpẹ, wọ́n jẹ́ mímọ́ nítorí pé wọ́n ti mú wọn wá ṣíwájú OLÚWA. Kí wọ́n jẹ́ àmì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”

39Élíásárì tí í ṣe àlùfáà sì kó gbogbo àwo tùràrí tí àwọn tí ó jóná mú wa, ó gún wọn pọ̀, ó fi ṣe ìbòrí fún pẹpẹ,

40Gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ṣe sọ láti ẹnu Mósè. Èyí yóò jẹ́ ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ẹlòmíràn yàtọ̀ sí irú ọmọ Árónì kò gbọdọ̀ jó tùràrí níwájú OLÚWA, ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóò dàbí Kórà àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.

41Ní ọjọ́ kejì gbogbo ìjọ ènìyàn kùn sí Mósè àti Árónì pé, “Ẹ ti pa àwọn ènìyàn OLÚWA.”

42Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn péjọ lòdì sí Mósè àti Árónì, níwájú àgọ́ ìpàdé, lójijì ni ìkúùkù bolẹ̀, ògo OLÚWA sì fara hàn.

43Nígbà náà ni Mósè àti Árónì lọ ṣíwájú àgọ́ ìpàdé,

44OLÚWA sì sọ fún Mósè pé,

45“Yàgò kúrò láàrin ìjọ ènìyàn yìí, kí ń ba le run wọ́n ní ìṣẹ́jú kan.” Wọ́n sì dojú bolẹ̀.

46Mósè sì sọ fún Árónì pé, “Mú àwo tùràrí, kí o fi iná sí i lórí pẹpẹ, fi tùràrí sínú rẹ̀, kí o sì tètè mu lọ sí àárin ìjọ ènìyàn láti ṣètùtù fún wọn nítorí pé ìbínú OLÚWA ti jáde, àjàkálẹ̀-àrùn sì ti bẹ̀rẹ̀.”

47Árónì ṣe bí Mósè ti wí, ó sáré lọ sí àárin àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-àrùn ti bẹ̀rẹ̀ láàrin wọn, ṣùgbọ́n Árónì fín tùràrí, ó sì ṣe ètùtù fún wọn.

48Ó dúró láàrin àwọn alààyè àti òkú, àjàkálẹ̀-àrùn náà sì dúró.

49Ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-àrùn ti pa ẹgbàá méje ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (14,700) ènìyàn ní àfikún sí àwọn tí ó kú níbi ìṣẹ̀lẹ̀ Kórà.

50Árónì padà tọ Mósè lọ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpade nítorí pé àjàkálẹ̀-àrùn náà ti dúró.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>