1OLÚWA sì sọ fún Mósè pé
2“Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí o sì gba ọ̀pá méjìlá lọ́wọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ olórí ìdílé ẹ̀yà ìran wọn, kọ orúkọ ènìyàn kọ̀ọ̀kan sí ara ọ̀pá rẹ̀.
3Lórí ọ̀pá Léfì kọ orúkọ Árónì, nítórí ọ̀pá kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà fún olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan tí yóò jẹ́ orí fún ẹ̀yà ìran kọ̀ọ̀kan.
4Kó wọn sí Àgọ́ Ìpàdé níwájú Ẹ̀rí níbi tí èmi ti ń pàdé yín.
5Ọ̀pá tí ó bá yí jẹ́ ti ẹni tí èmi bá yàn yóò rú wé, èmi yóò sì dá kíkùn gbogbo ìgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí yín dúró.”
6Nígbà náà Mósè bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, àwọn olórí wọn sì fún un ní ọ̀pá méjìlá, ọ̀pá kan fún olórí kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà ìran wọn, ọ̀pá Árónì sì wà lára àwọn ọ̀pá náà.
7Mósè sì fi ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú OLÚWA nínú àgọ́ ẹ̀rí.
8
9Nígbà náà ni Mósè kó gbogbo àwọn ọ̀pá jáde láti iwájú OLÚWA wá fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wọ́n wò wọ́n, ẹnìkọ̀ọ̀kan sì mú ọ̀pá tirẹ̀.
10OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Mú ọ̀pá Árónì padà wá ṣíwájú Ẹ̀rí, láti fi pamọ́ gẹ́gẹ́ bí àmìn fún àwọn ọlọ̀tẹ̀. Èyí ó sì mú òpin bá kíkùn sínú wọn sí mi, kí wọn kí ó má baà kú.”
11Mósè sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pa a láṣẹ fún un.
12Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ fún Mósè pé, “Àwa yóò kú! A ti sọnù, gbogbo wa ti sọnù!
13Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ tabánákù OLÚWA yóò kú. Ṣé gbogbo wa ni yóò kú?”