1OLÚWA sọ fún Mósè àti Árónì pé:
2“Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa Àgọ́ wọn yí àgọ́ ìpàdé ká, kí wọ́n jẹ́ kí àgọ́ wọn jìnnà sí i díẹ̀, oníkálùkù lábẹ́ ọ̀págun pẹ̀lú àṣíá ìdílé wọn.”
3Ní ìlà oòrùn, ní ìdojúkọ àtiyọ oòrùn ni kí ìpín ti Júdà pa ibùdó wọn sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Júdà ni Náṣónì ọmọ Ámínádábù.
4Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlógójì ó lé ẹgbẹ̀ta (74,600).
5Ẹ̀yà Ísákárì ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Ísákárì ni Nìtaníẹ́lì ọmọ Súárì.
6Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlọ́gbọ̀n ó lé irínwó (54,400).
7Ẹ̀yà Sébúlúnì ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Sébúlónì ni Élíábù ọmọ Hélónì.
8Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gbọ̀n-ó-lé-egbéje (57,400).
9Gbogbo àwọn tí a yàn sí ibùdó Júdà, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́taléláàdọ́rin ó lé irínwó (186,400). Àwọn ni yóò kọ́kọ́ ṣáájú.
10Ní ìhà gúsù ni ìpín ti Rúbẹ́nì pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Rúbẹ́nì ni Elisúrì ọmọ Ṣedúérì.
11Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́talélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (46,500).
12Ẹ̀yà Símónì ni yóò pa ibùdó tẹ́lé wọn. Olórí Símónì ni Ṣélúmíélì ọmọ Surisadáì.
13Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbéje. (59,300).
14Ẹ̀yà Gáádì ló tẹ̀lé wọn. Olórí Gáádì ni Eliásáfì ọmọ Déúélì.
15Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé àádọ́ta (45,650).
16Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Rúbẹ́nì, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá márùndínlọ́gọ́rún ó lé àádọ́tàlélégbéje (151,450). Àwọn ni yóò jáde sìkéjì.
17Nígbà náà ni àwọn ọmọ Léfì Àti Àgọ́ ìpàdé yóò tẹ̀ṣíwájú láàrin ibùdó àwọn ènìyàn, wọn yóò tẹ̀ṣíwájú ní ṣíṣẹ̀ n tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe pa ibùdó, olúkúlùkù láàyè rẹ̀, àti lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀.
18Ní ìhà ìlà oòrùn ni ìpín Éfúráímù yóò pa ibùdó rẹ̀ sí lábẹ́ ọ́págun rẹ̀. Olórí Éfúráímù ni Élíṣámà ọmọ Ámíhúdì.
19Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (40,500).
20Ẹ̀yà Mánásè ni yóò tẹ̀lé wọn. Olórí Mánásè ni Gàmálíélì ọmọ Pedasúrì.
21Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́rìndínlógún-ó-lé-igba (32,200).
22Ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni yóò tẹ̀ lé e. Olórí Bẹ́ńjámínì ni Ábídánì ọmọ Gídíónì.
23Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́tadínlógún ó lé egbéje (35,400).
24Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Éfúráímù, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnléláàdọ́ta-ó-lé-ọgọ́rùn-ún (108,100). Àwọn ni yóò jáde sìkẹ́ta.
25Ní ìhà àríwá, ni ìpín Dánì yóò pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olóri Dánì ni Áyésérì ọmọ Ámíṣádáyì.
26Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin. (62,700).
27Ẹ̀yà Ásérì ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Ásérì ni Págíélì ọmọ Ókíránì.
28Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500).
29Ẹ̀yà Náfítanì ni yóò kàn lẹ́yìn wọn. Olórí Náfítanì ni Áhírà ọmọ Énánì.
30Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún-ó-lé-egbéje (53,400).
31Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Dánì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gọ̀rún-ó-lé-ẹgbẹ̀jọ (157,600). Àwọn ni yóò jáde kẹ́yìn lábẹ́ ọ̀págun wọn.
32Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kà nípa ìdílé wọn. Gbogbo àwọn tó wà ní ibùdó, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́-ó-lé-egbéjìdínlógún-dín àádọ́ta (603,550).
33Ṣùgbọ́n a kò ka àwọn ọmọ Léfì papọ̀ mọ́ àwọn Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pa á láṣẹ fún Mósè.
34Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì se gbogbo ohun tí OLÚWA pa láṣẹ fún Mósè, báyìí ni wọ́n ṣe pa ibùdó lábẹ́ ọ̀págun wọn, bẹ́ẹ̀ náà sì ni wọ́n ṣe jáde, oníkálùkù pẹ̀lú ẹbí àti ìdílé rẹ̀.