1Ní osù kìn-ní-ní, gbogbo àgbájọ ọmọ Ísírẹ́lì gúnlẹ̀ sí pápá Sínì, wọ́n sì dúró ní Kádésì. Níbẹ̀ ni Míríámù kú, wọ́n sì sin ín.
2
3Wọ́n bá Mósè jà wọ́n sì wí pé, “Ìbá kúkú sàn kí a kú nígbà tí àwọn arakùnrin ti kú níwájú OLÚWA!
4Kí ni ó dé tí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn OLÚWA wá sí ihà yìí, kí àwa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa báà kú síbí?
5Kí ni ó dé tí o fi mú wa gòkè kúrò ní Éjíbítì wá sí ibi búburú yìí? Ibi tí kò ní oúnjẹ tàbí igi ọ̀pọ̀tọ́, èṣo àjàrà tàbí pamonganati. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi tí a ó mu níhín-ín!”
6Mósè àti Árónì kúrò ní ibi àpéjọ, wọ́n sì lọ dojúbolẹ̀ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo OLÚWA sì farahàn wọ́n.
7OLÚWA sọ fún Mósè pé,
8“Mú ọ̀pá, náà kí o sì pe ìjọ àwọn ènìyàn jọ, ìwọ àti Árónì arákùnrin rẹ, kí ẹ sọ̀rọ̀ sí àpáta náà ní ójú wọn, yóò sì tú omi rẹ̀ jáde ìwọ ó sì fún ìjọ àti ẹran wọn mu”
9Báyìí ni Mósè mú ọ̀pá láti iwájú OLÚWA wá, gẹ́gẹ́ bí ó ti paláṣẹ fún un.
10Òun àti Árónì pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mósè sì sọ fún wọn, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yín ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí?”
11Nígbà náà ni Mósè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu.
12Ṣùgbọ́n OLÚWA sọ fún Mósè àti Árónì pé, “Nítorí pé ẹ̀yin kò gbà mí gbọ́ tó láti bu ọlá fún mi níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìwọ kò ní kó àwọn ìjọ ènìyàn yìí dé ilẹ̀ tí mo fún wọn.”
13Èyí ni omi ti Méríbà, níbi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti bá OLÚWA jà àti ibi tí O ti fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni mímọ́ láàrin wọn.
14Mósè sì ránṣẹ́ láti Kádésì sí ọba Édómù, wí pé:
15Àwọn bàbá ńlá wa sọ̀kalẹ̀ wá sí Éjíbítì, a sì gbé ibẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ará Éjíbítì ni wá lára àti àwọn bàbá wa,
16ṣùgbọ́n nígbà tí a sunkún sí OLÚWA, ó gbọ́ ẹkún wa, ó sì rán ańgẹ́lì kan sí wa, ó sì mú wa jáde láti Éjíbítì.
17Jọ̀wọ́ jẹ́ kí a gba orílẹ̀ èdè rẹ kọjá, Àwa kì yóò gba inú oko tàbí ọgbà àjàrà rẹ kọjá, tàbí mu omi láti inú kàǹga. A ó ma kọjá ní òpópónà ọba, àwa kì yóò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì títí àwa yóò fi kọjá ní ilẹ̀ rẹ.”
18Ṣùgbọ́n Édómù dáhùn pé:
19Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dáhùn pé:
20Wọ́n tún dáhùn wí pé:
21Nígbà tí Édómù sì kọ̀ jálẹ̀ láti jẹ́ kí wọn kọjá ní ilẹ̀ wọn, Ísírẹ́lì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.
22Gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì jáde láti Kádésì wọ́n sì wá sí orí òkè Hórì.
23Ní orí òkè Hórì, ní ẹ̀gbẹ́ ààlà Édómù OLÚWA sọ fún Mósè àti Árónì pé,
24“Árónì yóò kú. Kò ní wọ ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí ẹ̀yin méjèèjì ṣe àìgbọ́ràn sí òfin mi níbi omi Méríbà.
25
26Bọ́ aṣọ Árónì kí o sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Élíásárì, nítorí pé Árónì yóò kú ṣíbẹ̀.”
27Mósè sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pa láṣẹ: Wọ́n lọ sí orí òkè Hórì ní ojú gbogbo ìjọ ènìyàn.
28Mósè bọ́ aṣọ Árónì ó sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Élíásárì, Árónì sì kú sí orí òkè. Nígbà náà Mósè àti Élíásárì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè,
29Nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbọ́ pé Árónì ti kú, gbogbo ilé Ísírẹ́lì ṣe ìdárò rẹ̀ fún ọgbọ̀n (30) ọjọ́.