1
2Nísinsìnyìí Bálákì ọmọ Sípórì rí gbogbo ohun tí àwọn Ísírẹ́lì ti ṣe sí àwọn ará Ámórì,
3ẹ̀rù sì ba Móábù nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn wà níbẹ̀ nítòótọ́, Móábù kún fún ẹ̀rù nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
4Móábù sọ fún àwọn àgbààgbà Mídíánì pé, “Nísinsìnyìí ni àwọn wọ̀nyí yóò lá gbogbo ohun tí ó yí wa ká, bí màlúù ṣe ń jẹ koríko tí ó wà nínú oko.” Bẹ́ẹ̀ ni Bálákì ọmọ Ṣípórì, tí ó jẹ́ ọba Móábù nígbà náà,
5rán oníṣẹ́ pé Bálámù ọmọ Béórì, tí ó wà ní Pétórì, ní ẹ̀bá odò ti ilẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ. Bálákì sọ pé:
6Nísinsìnyìí wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú, nítorí wọ́n ní agbára jù fún mi. Nípa ṣíṣe èyí èmi ó ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ yìí. Nítorí tí mo mọ̀ pé ìbùkún ni fún àwọn tí ìwọ bá bùkún, ìfibú sì ni ẹni tí ìwọ bá fi bú.”
7Olórí àwọn Móábù àti Mídíánì sì lọ pẹ̀lú owó àyẹ̀wò lọ́nà wọn, Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Bálámù, wọ́n sọ nǹkan tí Bálákì sọ fún wọn.
8“Ẹ sùn níbí lálẹ́ yìí” Bálámù sọ fún un pé, “Èmi ó padà wá fún un yín ní èsì nǹkan tí OLÚWA bá wí fún mi.” Nítorí tí àwọn ìjòyè Móábù dúró sọ́dọ̀ rẹ̀.
9Ọlọ́run tọ Bálámù wá ó sì wí pé, “Ta ni àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ yìí?”
10Bálámù sọ fún Ọlọ́run pé, “Bálákì ọmọ Sípórì, ọba Móábù, rán iṣẹ́ yìí sí mi pé:
11‘Ènìyàn tí ó jáde láti Éjíbítì wá bo ojú ayé. Nísinsin yìí wá kí o wá fi wọ́n bú fún mi. Bóyá màá le bá wọn jà èmi ó sì lé wọn jáde.’ ”
12Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún Bálámù pé, “Má ṣe bá wọn lọ. Ìwọ kò gbọdọ̀ gé ègún lé àwọn ènìyàn náà lórí, nítorí a ti bùkún wọn.”
13Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Bálámù dìde ó sì sọ fún àwọn ìjòyè Bálákì pé, “Ẹ padà sí orílẹ̀ èdè yín, nítorí tí OLÚWA ti kọ̀ láti jẹ́ kí n tẹ̀lé yín.”
14Nígbà náà àwọn ìjòyè Móábù sì padà tọ Bálákì lọ wọ́n sì wí pé, “Bálámù kọ̀ láti tẹ̀lé wa.”
15Nígbà náà Bálákì rán àwọn ìjòyè mìíràn tí wọ́n pọ̀ àwọn tí wọ́n sì níyì ju alákọ́kọ́ lọ.
16Wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Bálámù wọ́n sì sọ pé:
17Nítorí pé èmi yóò fún ọ ní ẹ̀bùn dáradára màá sì ṣe ohunkóhun tí o bá sọ. Wá kí o sì wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú fún mi.”
18Ṣùgbọ́n Bálámù dá wọn lóhùn pé, “Kó dà tí Bálákì bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, n kò ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí kéré tí o kọjá òfin OLÚWA Ọlọ́run mi.
19Nísinsìnyìí ẹ dúró níbí di ọjọ́ kejì gẹ́gẹ́ bí àwọn tókù ti ṣe nígbà náà èmi yóò mọ ohun tí OLÚWA yóò tún sọ fún mi.”
20Ní alẹ́ ọjọ́ náà Ọlọ́run sì tọ Bálámù wá ó sì sọ wí pé, “Nígbà tí ọkùnrin yìí ti wá pè ọ́, lọ pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ẹnu nǹkan tí mo sọ fún ọ ni kí o ṣe.”
21Bálámù dìde ní òwúrọ̀, ó sì di ẹrù lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ òun pẹ̀lú àwọn ìjòyè Móábù.
22Ṣùgbọ́n Ọlọ́run bínú gidigidi, áńgẹ́lì OLÚWA sì dúró lójú ọ̀nà láti dojú ìjà kọ ọ́. Bálámù ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lọ, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
23Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì rí áńgẹ́lì OLÚWA tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà tí a fà yọ ní ọwọ́ rẹ̀, ó kọjú kúrò ní ọ̀nà lọ sínú oko. Bálámù sì lù ú pé kí ó gbé òhun padà lọ sí ojú ọ̀nà.
24Nígbà náà ángẹ́lì OLÚWA dúró ní ojú ọ̀nà tóóró láàrin ọgbà àjàrà, pẹ̀lú ògiri ní ọ̀nà méjèèjì.
25Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí ángẹ́lì OLÚWA, ó lẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ ògiri, ó sì rún ẹsẹ̀ Bálámù mọ́ ògiri. Nígbà náà, ó tún nàá, lẹ́ẹ̀kan sí i.
26Nígbà náà ángẹ́lì OLÚWA súnmọ́ wájú ó sì dúró níbi ọ̀nà tóóró níbi tí kò ti sí ọ̀nà láti yípadà, bóyá ní ọ̀tún tàbí òsì.
27Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí ángẹ́lì OLÚWA, ó sì jókó ní abẹ́ Bálámù, inú sì bí i tó sì ná-àn pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀.
28Nígbà náà OLÚWA sí ẹnu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì sọ fún Bálámù pé, “Kí ni mo ṣe fún ọ tí o fi nà mí lẹ́ẹ̀mẹ́ta?”
29Bálámù sọ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pé, “Nítorí ìwọ fi mí ṣẹ̀sín! Bí mo bá ní idà ní ọwọ́ ni èmi ì bá pa ọ́ nísinsin yìí.”
30Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sọ fún Bálámù pé, “Ṣé mi kì í ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni, tí o máa ń gùn ní gbogbo ìgbà, láti ìgbà pípẹ́ wá? Ǹjẹ́ mo hu irú ìwà báyìí sí ọ rí?”
31Nígbà náà OLÚWA sí ojú Bálámù, ó sì rí ángẹ́lì OLÚWA tí ó dúró ní oju ọ̀nà pẹ̀lú idà rẹ̀ tí ó fàyọ. Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba.
32Nígbà náà ángẹ́lì OLÚWA bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí o fi na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ nígbà mẹ́ta yìí? Mo wá síbí láti kọ ojú ìjà sí ọ nítorí ọ̀nà rẹ kò tọ́ níwájú mi.
33Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí mi ó sì yà kúrò fún mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta yìí. Tí ó bá jẹ́ wí pé kò yà kúrò. Èmi kì ìbá ti pa ọ́ pátapáta nísinsìnyìí, ṣùgbọ́n Èmi yóò sì dá òun sí.”
34Bálámù sọ fún ángẹ́lì OLÚWA pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀, èmi kò mọ̀ pé o dúró níwájú ọ̀nà láti dojú kọ mí, Nísinsin yìí tí inú rẹ kò bá dùn, èmi ó padà.”
35Ańgẹ́lì OLÚWA sọ fún Bálámù pé, “Lọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin náà, ṣùgbọ́n nǹkan tí mo sọ fún ọ nìkan ni kí o sọ.” Nígbà náà Bálámù lọ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Bálákì.
36Nígbà tí Bálákì gbọ́ pé Bálámù ń bọ̀ wá, ó jáde lọ láti lọ pàdé rẹ̀ ní ìlú Móábù tí ó wà ní agbégbé Ánónì, ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ̀.
37Bálákì sì sọ fún Bálámù pé, “Ǹjẹ́ èmi kò a ránṣẹ́ kánjúkánjú sí ọ? Kí ló dé tí ìwọ kò fi wá sí ọ̀dọ̀ mi? Ṣé èmi kò tó láti sọ ọ́ di ẹni ńlá?”
38“Kíyèsi, èmi ti wá sọ́dọ̀ rẹ nísinsin yìí,” Bálámù fẹ̀sì pé. “Ṣùgbọ́n ṣe mo lè sọ ohunkóhun? Mo gbọdọ̀ sọ nǹkan tí OLÚWA fi sí mi lẹ́nu.”
39Nígbà náà Bálámù lọ pẹ̀lú Bálákì sí Kriati-Hosotíà.
40Bálákì rú ẹbọ akọ màlúù pẹ̀lú àgùntàn, ó sì fún Bálámù ní díẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.
41Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Bálákì gbé Bálámù lọ sí òkè Báálì, láti ibẹ̀ ló ti rí apákan àwọn ènìyàn.