Ìwé Nọ́ḿbà 23:1-30 BYB2014 - Bible AI

1Bálámù sọ́ wí pé, “Kọ́ pẹpẹ méje fún mi níbí, kí o sì mú akọ màlúù méje àti àgbò méje wá fún mi.”

2Bálákì ṣe bí Bálámù ti sọ, àwọn méjèèjì fi akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

3Nígbà náà Bálámù sọ fún Bálákì pé, “Dúró ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ kí èmi sì lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Bóyá OLÚWA yóò farahàn mí. Ohunkóhun tí ó bá fihàn, mí màá sọ fún ọ.” Nígbà náà ó sì lọ sí ibi gíga.

4Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀, Bálámù sì sọ pé, “Mo tí ṣe pẹpẹ méje, lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan mo ti fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ.”

5OLÚWA sì fi ọ̀rọ̀ sí ẹnu Bálámù ó wí pé, “Padà sí ọ̀dọ̀ Bálákì kí o sì jẹ́ iṣẹ́ yìí fún un.”

6Ó sì padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì ba tí ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè Móábù.

7Nígbà náà ni Bálámù sọ ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ jáde wí pé:

7“Bálákì mú mi láti Árámù wá, ọba Móábù láti òkè ìlà oòrùn wá Ó wí pé, ‘Wá fi Jákọ́bù bú fún mi; wá, kí o sì jẹ́rì i sí Ísírẹ́lì.’

8Báwo ní èmi ó ṣe fi bú àwọn tí Ọlọ́run kò fi bú? Báwo ni èmi ó ṣe bá wọn wí àwọn tí OLÚWA kò bá wí?

9Láti ṣónṣó ibi gíga orí àpáta ni mo ti rí wọn, láti orí ibi gíga ni mo ti ń wò wọ́n. Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbé lọ́tọ̀ wọn kò sì ka ará wọn kún ara àwọn orílẹ̀ èdè.

10Ta ni ó lè ka eruku Jákọ́bù tàbí ka ìdámẹ́rin Ísírẹ́lì? Jẹ́ kí èmi kú ikú olóòtọ́, kí ìgbẹ̀yìn mi kí ó dàbí ti wọn!”

11Bálákì sọ fún Bálámù pé, “Kí lo ṣe fún mi? Mo gbé ọ wá láti fi àwọn ọ̀ta mi bú, Ṣùgbọ́n o kò ṣe nǹkan kan Ṣùgbọ́n o bùkún wọn!”

12Ó sì dáhùn wí pé, “Sé kí n má sọ nǹkan tí OLÚWA fi sí mi lẹ́nu?”

13Nígbà náà Bálákì sọ fún un pé, “Wá pẹ̀lú mi sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn; wà á rí díẹ̀ Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn. Láti ibẹ̀, wá fi wọ́n bú fún mi.”

14Ó sì lọ sí pápá Ṣóímù ní orí òkè Písígà, ó sì kọ́ pẹpẹ méje síbẹ̀ ó sì fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

15Bálámù ṣo fún Bálákì pé, “Dúró níbí ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ nígbà tí mo bá lọ pàdé rẹ̀ níbẹ.”

16OLÚWA pàdé Bálámù ó sì fí ọ̀rọ̀ sí ní ẹnu wí pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ Bálákì kí o sì jísẹ́ fún un.”

17Nígbà náà ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì báà tí ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Móábù. Bálákì sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni OLÚWA wí?”

18Nígbà náà ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ: “Dìde, Bálákì; kí o sì gbọ́ mi ọmọ Sípórà.

19Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, tí yóò fi purọ́, tàbí ọmọ ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ̀ padà. Ǹjẹ́ ó sọ̀rọ̀ kí ó má ṣe é? Ǹjẹ́ ó ti ṣèlérí kí ó má mu-un ṣẹ?

20Èmi gba àṣẹ láti bùkún; Ó sì ti bùkún, èmi kò sì lè yípadà.

20

21“Kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan nínú Jákọ́bù, kò sì rí búburú kankan nínú Ísírẹ́lì. OLÚWA Ọlọ́run wọn sì wà pẹ̀lú wọn. Ìhó ọba sì wà pẹ̀lú wọn.

22Ọlọ́run mú wọn jáde láti Éjíbítì wá, wọ́n ní agbára màlúù ẹhànnà.

23Kò ní àfọ̀ṣẹ sí Jákọ́bù, tàbí àfọ̀ṣẹ sí àwọn Ísírẹ́lì. Nísinsìnyìí a ó sọ nípa ti Jákọ́bù àti Ísírẹ́lì, ‘Wo ohun tí OLÚWA ti ṣe!’

24Àwọn ènìyàn dìde bí abo kìnnìún; wọ́n dìde bí i kìnnìún tí kì í sinmi títí yóò fi pa ìkógún jẹ tàbí mu ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó fi ara pa.”

25Nígbà náà ni Bálákì sọ fún Bálámù pé, “O ko fi wọ́n bú tàbí bùkún wọn rárá!”

26Bálámù dáhùn pé, “Ǹjẹ́ mi ò sọ fún ọ pé mo gbọdọ̀ Ṣe ohun tí OLÚWA bá sọ?”

27Nígbà náà Bálákì sọ fún Bálámù pé, “Wá jẹ́ kí èmi kí ó mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá yóò tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn kí ó fi wọ́n bú láti ibẹ̀ lọ.”

28Bálákì gbé Bálámù wá sí orí òkè Péórì, tí ó kọjú sí ihà.

29Bálámù sọ pé, “Kọ́ pẹpẹ méje fún mi níbí kí o sì pèsè akọ màlúù àti àgbò fún mi.”

30Bálákì sì ṣe bí Bálámù ti sọ fún un, ó sì gbé akọ màlúù kan àti àgbò lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>