1
2“Ka iye gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọ́n; láti ẹni ogun (20) ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó lè jà lójú ogun ní Ísírẹ́lì.”
3Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Móábù pẹ̀lú Jọ́dánì tí ó kọjá Jẹ́ríkò, Mósè àti Élíásárì àlùfáà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn ó wí pé,
4“Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ ogun (20) ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti paláṣẹ fún Mósè.”
5
6
7Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Rúbẹ́nì; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé ẹgbẹ̀sán ó dín àádọ́rin (43,730).
8Àwọn ọmọkùnrin Pálù ni Élíábù,
9àwọn ọmọkùnrin Élíábù ni Némúélì àti Dátanì àti Ábírámù. Èyí ni Dátanì àti Ábírámù náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Árónì tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kórà nígbà tí wọ́n bá OLÚWA jà.
10Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kórà, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́tàlérúgba ọkùnrin (250). Tí wọ́n sì di àmì ìkìlọ̀.
11Àwọn ọmọ Kórà, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú.
12Àwọn ọmọ ìrán Símónì bí ìdílé wọn:
13
14Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Símónì, ẹgbàámọ́kànlá ó lé igba. (22,200) ọkùnrin.
15Àwọn ọmọ Gádì bí ìdílé wọn:
16
17
18Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gádì tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).
19Àwọn ọmọ Júdà ni Érì àti Ónánì, ṣùgbọ́n Érì àti Ónánì kú ní ilẹ̀ Kénánì.
20Àti àwọn ọmọ Júdà gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
21
22Wọ̀nyí ni ìdílé Júdà; gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógójì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (76,500).
23Àwọn ọmọ Isákárì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
24
25Wọ̀nyí ni ìdílé Isákárì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàáméjìlélọ́gbọ̀n ó léọ̀ọ́dúnrún (64,300).
26Àwọn ọmọ Ṣebúlúnì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
27Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sebúlúnì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (60,500).
28Àwọn ọmọ Jósẹ́fù gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; Mánásè àti Éfúráímù:
29Àwọn ọmọ Mánásè:
30
31
32
33
34Wọ̀nyí ni ìdílé Mánásè tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàámẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (52,700).
35Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Éfúráímù gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
36
37Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Éfurémù, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàámẹ́rìndínlógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (32,500).
38Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn nì yí:
39
40
41Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì; gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; àti àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàáméjìlélógún ó lé ẹgbẹ̀jọ (45,600).
42Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dánì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
43Gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ṣúhámù, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàáméjìlélọ́gbọ̀n ó lé irínwó (64,400).
44Ti àwọn ọmọ Ásérì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
45
46
47Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Áṣérì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbéje (53,400).
48Ti àwọn ọmọ Náfítalì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
49
50Wọ̀nyí ni ìdílé ti Náfítalì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé egbéje (45,400).
51Àpapọ̀ iye tí a kà nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́, ó lé ẹgbẹ̀sán ó dín àádọ́rin (601,730).
52OLÚWA sọ fún Mósè pé,
53“Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ jẹ́ pínpín fún wọn gẹ́gẹ́ bí ogún wọn gẹ́gẹ́ bí iye orúkọ wọn
54Fún àwọn ọ̀pọ̀ ni kí ìwọ ó fún ní ogún ìlú púpọ̀ àti fún àwọn tí ó kéré ni kí ìwọ ó fi kékeré fún, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ gba ogún ìbí tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí a kọ.
55Rí dájú pé ilẹ̀ yìí gbọdọ̀ jẹ́ fífi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọn sì ti pọ̀ tó. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ẹ̀yà àwọn baba wọn ni kí wọn kí ó ni ín.
56Olúkúlùkù ogún ìní ni a gbọdọ̀ fi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pọ̀ tó láàrin ńlá àti kékeré.”
57
58
59
60
61
62Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Léfì láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn.
63Àwọn wọ̀nyí ni Mósè àti Élíásárì àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lẹ́bá odò Jọ́dánì létí Jẹ́ríkò.
64
65Nítorí OLÚWA ti sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kíkú ni wọn yóò kú sí ihà, kò sì sí ẹnìkankan nínú wọn tí kò kú à fi Kálẹ́bù ọmọ Jéfúnì, àti Jóṣúà ọmọ Núnì.