1OLÚWA sọ fún Mósè pé,
2“Gbẹ̀san lára àwọn Mídíánì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn ìgbà náà a ó kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ.”
3Mósè sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wọ ìhámọ́ra ogun fún àwọn kan nínú yín láti lọ da ojú ìjà kọ àwọn ọmọ Mídíánì láti gba ẹ̀san OLÚWA lára wọn.
4Rán ẹgberún (1000) ọmọ ogun láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní Ísírẹ́lì.”
5Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yan nínú àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹgbẹ̀rún (1000) ènìyan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ènìyàn tí ó wọ ìhámọ́ra ogun.
6Mósè rán wọn lọ sí ogun, ẹgbẹ̀rún (1000) láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú Fínéhásì ọmọ Élíásárì, ti ó jẹ́ àlùfáà, ti òun ti ohun èlò ibi mímọ́ àti ìpè wọ̀n-ọn-nì ní ọwọ́ rẹ̀.
7Wọ́n dojú ìjà kọ Mídíánì gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti láṣẹ fún Mósè, kí wọn sì pa gbogbo wọn.
8Wọ́n sì pa àwọn ọba Mídíánì pẹ̀lú: àwọn ìyókù tí wọ́n pa lára wọn ni Éfì, Rékémù, Ṣúrù àti Húrì, àti Rébà: ọba Mídíánì márùn ún, wọ́n sì fi idà pa Bálámù ọmọ Béórì.
9Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì mú gbogbo obìnrin Mídíánì ní ìgbékùn àti àwọn ọmọ kékeré wọn, wọ́n sì kó gbogbo ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo agbo ẹran wọn àti gbogbo ẹrù wọn.
10Wọ́n finá jó gbogbo ìlú wọn àti ibùdó wọn.
11Wọ́n sì kó gbogbo ìní wọn, àti ènìyàn àti ẹran.
12Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí wọ́n bàjẹ́ àti ènìyàn àti ẹran wá sọ́dọ̀ Mósè àti Élíásárì àlùfáà, àti sọ́dọ̀ ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ibùdó àgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì létí Jẹ́ríkò.
13Mósè, Élíásárì àlùfáà àti gbogbo olórí ìgbéríko lọ láti lọ bá wọn ní ìta ibùdó.
14Inú bí Mósè sí àwọn olórí ọmọ ogun, pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹ̀rún (1000) àti olórí ọrọrún (1000) tí wọ́n ti ogun dé.
15Mósè sì bèèrè wí pé, “Ẹ̀yin ha dá gbogbo àwọn obìnrin sí bí?
16
17Nísinsìnyìí, pa gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó ti súnmọ́ ọkùnrin,
18Ṣùgbọ́n kí o dá obìnrin tí kò bá tí ì sún mọ́ ọkùnrin sí fún ara yín.
19“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti pa ènìyàn tàbí fọwọ́ kan ẹni tí a pa gbọdọ̀ dúró ní ìta ibùdó àgọ́ fún ọjọ́ méje, Ní ọjọ́ kẹ́ta àti ọjọ́ kéje ẹ gbọdọ̀ ya ara yín àti ẹni tí ẹ kó lẹ́rú sí mímọ́.
20Kí ẹ̀yin kí ó ya aṣọ yín sí mímọ́ àti gbogbo ohun tí a fi awọ ṣe àti gbogbo iṣẹ́ irun ewúrẹ́ àti ohun tí a fi igi ṣe.”
21Élíásárì àlùfáà sì wí fún àwọn olórí ogun náà pé, “Èyí ní ìlànà òfin tí OLÚWA fi lélẹ̀ ní àṣẹ fún Mósè.
22Kìkì i wúrà, fàdákà, idẹ, irin, tanńganran àti òjé.
23Ohunkóhun tí ó lè la iná ni kí ẹ̀yin ó mú la iná, nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n ẹ ó ò fi omi ìyàsímímọ́ sọ ọ́ di mímọ́. Àti gbogbo ohun tí kò lè la iná kọjá ni kí a mú la inú omi.
24Ní ọjọ́ kéje, ẹ fọ aṣọ yín, ẹ̀yin yóò sì mọ́, nígbà náà ní ẹ̀yin yóò lè wọ inú ibùdó àjọ.”
25OLÚWA sọ fún Mósè pé,
26“Ìwọ àti Élíásárì àlùfáà àti àwọn olórí ilé baba ìjọ ni kí o ka iye àwọn ènìyàn àti ẹranko tí a kó ní ìgbékùn.
27Pín ohun ìní àti ìkógún náà láàrin àwọn ọmọ ogun náà tí ó kópa nínú ogun náà àti láàrin gbogbo ìjọ.
28Kí o sì gba ìdá ti OLÚWA lọ́wọ́ àwọn ológun tí wọn jáde lọ sí ogun náà: ọ̀kan nínú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nínú àwọn ènìnyàn àti nínú màlúù àti nínú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti nínú agbo ẹran.
29Gbà ìdá yìí lára ààbọ̀ ìpín ti wọn, kí o sì fún Élíásárì àlùfáà, fún ẹbọ ìgbésókè OLÚWA.
30Lára ààbọ̀ ti Ísírẹ́lì, yan ọ̀kan kúrò nínú àádọ́ta, (50) yálà ènìyàn, ẹran ọ̀sìn, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, ewúrẹ́ tàbí ẹ̀yà ẹranko mìíràn. Kó wọn fún àwọn Léfì, tí ó dúró fún olùtọ́jú àgọ́ OLÚWA.”
31Nígbà náà Mósè àti Élíásárì àlùfáà ṣe gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti paláṣẹ fún Mósè.
32Èrè tí ó kù lára ìkógun tí àwọn ọmọ ogun kó jẹ́, ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (675,000) ó dín ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àgùntàn.
33Ẹgbàá mẹ́rìndínlógójì (72,000) màlúù
34ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹgbẹ̀rin (61,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
35Pẹ̀lú obìnrin ẹgbàá mẹ́rìndínlógún, (32,000) ni kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin rí.
36Ìpín ààbọ̀ àwọn tí ó jáde lọ sí ogun sì jẹ́:
37
38
39
40
41Mósè fi ìdá náà fún Élíásárì, àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìdá ti OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pa á láṣẹ fún Mósè.
42Ààbọ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí Mósè yà sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọkùnrin tí ó ja ogun.
43(Ààbọ̀ tí àwọn ará ìlú sì jẹ́ ẹgbàá méjìdínláàdọ́sàn-án ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (337,500) àgùntàn,
44pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún (36,000) màlúù
45tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (30,500)
46Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ;) (16,000).
47Lára ààbọ̀ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Mósè yan ọ̀kan lára àádọ́ta (50) ènìyàn àti ẹranko gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pa á láṣẹ fún un. Ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì, tí ń ṣe olùtọ́jú àgọ́ OLÚWA.
48Pẹ̀lú àwọn olórí tí ó wà lórí ẹgbẹẹgbẹ̀rin ogun náà, àti àwọn balógun ọrọọrún wá sọ́dọ̀ Mósè.
49Wọ́n sì sọ fún un pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ti ka àwọn ọmọ ogun náà tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú wa, kò sì sí ìkọkan tó dín.
50Nítorí náà làwa ṣe mú ọrẹ ẹbọ wá fún OLÚWA, gbogbo ọrẹ wíwà tí a ní, wúrà, ẹ̀wọ̀n, àti júfù, àti òrùka: àmi, àti òrùka etí, àti ìlẹ̀kẹ̀ láti fi ṣe ètùtù fún ọkàn an wa níwájú OLÚWA.”
51Mósè àti Élíásárì àlùfáà, gba wúrà náà lọ́wọ́ ọ wọn pẹ̀lú gbogbo ohun iṣẹ́ ọ̀ṣọ́.
52Gbogbo wúrà tí àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún mú wá fún Mósè àti Élíásárì, èyí tí ó jẹ́ ẹbọ ìgbésókè fún OLÚWA jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé àádọ́ta (16,750) ṣékélì.
53Nítorí ológun kọ̀ọ̀kan ti kó ẹrù fún ara rẹ̀.
54Mósè àti Élíásárì àlùfáà gba wúrà náà lọ́wọ́ àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti lọ́wọ́ balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún wọ́n sì ko wá sínú Àgọ́ Ìpàdé fún ìrántí àwọn Ísírẹ́lì níwájú OLÚWA.