Ìwé Nọ́ḿbà 34:1-29 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA sọ fún Mósè pé,

2“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì sọ fún wọn pé: ‘Tí ẹ bá wọ Kénánì, ilẹ̀ tí a ó fi fún yín, gẹ́gẹ́ bí ogún yín yóò ní ààlà wọn yí:

3ⓐ “ ‘Ìhà gúṣù yín yóò bọ́ sí ara ihà Ṣínì lẹ́bá Édómù, àti ìlà-oòrùn, ààlà ìhà-gúsù yóò bẹ̀rẹ̀ láti òpin Òkun Iyọ̀,

4Kọjá lọ sí Síkọ́píọ́nì, tẹ̀ṣíwájú lọ si Sínì: kó bọ́ si gúsù Kadesi-Báníyà, kí o sì dé Hasari-Ádárò, kí o sì kọjá sí Ásímónì.

5Níbẹ̀ ni yóò ti padà, papọ̀ mọ́ odò Éjíbítì, tí yóò sì parí ní òpin Òkun.

6“ ‘Ìhà ìwọ̀ oòrùn yín yóò jẹ́ òpin lórí Òkun ńlá. Èyí yóò jẹ́ ààlà yín lórí ìhà-ìwọ̀ oòrùn:

7“ ‘Fún ààlà ìhà-àríwá, fa ìlà láti òkun ńlá lọ sí orí òkè Hórì

8Àti láti orí-òkè Hórì sí Lébò Hámátì. Nígbà náà ààlà náà yóò lọ sí Sédádì,

9Tẹ̀ṣíwájú lọ sí Sífírónì, kí o sì fò pín si ní Hasari-Énánì, Èyí yóò jẹ́ ààlà tìrẹ ní ìhà àríwá.

10“ ‘Kí ẹ sì sàmì sí ilẹ̀ ti yín ní ìhà ìlà oòrùn láti Hasari-Énánì lọ dé Ṣéfámù.

11Ààlà náà yóò ti Séfámù sọ̀kalẹ̀ wá lọ sí Ríbílà ní ìhà-ìlà oòrùn Háínì, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ dé ìhà Òkun Kínérétì ní ìhà ìlà oòrùn.

12Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jọ́dánì, yóò sì dópin nínú Òkun.

12“ ‘Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.’ ”

13ⓑ Mósè pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Yan ilẹ̀ yìí pẹ̀lú kèké gẹ́gẹ́ bí ìní ogún: OLÚWA ti paláṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́san, àti ààbọ̀.

14Nítorí ará ilẹ ẹ̀yà ti Rúbẹ́nì, ẹ̀yà ti Gádì àti ẹ̀yà ààbọ̀ ti Mánásè ti gba ogún ti wọn.

15Ẹ̀yà méjèèjì àti ààbọ̀ yìí ti gba ogún ti wọn ní ìhà Jódánì létí i Jéríkò, Gábásì, ní ìhà ìlà oòrùn.”

16OLÚWA sọ fún Mósè pé,

17“Èyí ni orúkọ àwọn ọkùnrin náà tí yóò pín ilẹ̀, náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ogún: Élíásárì àlùfáà àti Jóṣúà ọmọ Núnì.

18Kí o sì yan olórí kan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti pín ilẹ̀ náà.

19Èyí ni orúkọ wọn: láti ẹ̀yà Júdà;

19Kálẹ́bù ọmọ Jéfúnè,

20Ṣémúélì ọmọ Ámíhúdì,

20láti ẹ̀yà Ṣíméónì;

21Élídádì ọmọ Kísílónì,

21láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì;

22Búkì ọmọ Jógílì,

22láti ẹ̀yà olórí àwọn ọmọ Dánì;

23Háníélì ọmọ Éfódù,

23láti ẹ̀yà Mánásè, olórí àwọn ọmọ Jóṣẹ́fù,

24Kémúélì ọmọ Ṣífílánì,

24olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ, Éfúráímù, ọmọ Jóṣẹ́fù;

25Élísáfánì ọmọ Pánákì,

25olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Ṣébúlunì;

26Pátíélì ọmọ Ásánì,

26olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísákárì;

27Áhíhúdù ọmọ Ṣélómì,

27olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Áṣérì;

28Pédàhẹ́lì ọmọ Ámíhúdì,

28olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Náfitalì.”

29Èyí ni àwọn ẹni tí OLÚWA yàn láti pín ogún náà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ Kénánì.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>