1
2“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti fún àwọn Léfì ní ilẹ̀ láti gbé lára ogún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jogún. Kí ẹ sì fún wọn ní ilẹ̀ lára pápá oko tútù, káàkiri ìlú.
3Nígbà náà, wọn yóò ní ìlú tí wọn yóò gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn, ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú gbogbo ìní wọn.
4“Ilẹ̀ pápá oko tútù káàkiri ìlú tí ẹ ó fi fún àwọn ọmọ Léfì, wíwọ̀n rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbàá ìgbọ̀nwọ́ (1500) ẹsẹ̀ bàtà láti ògiri ìlú náà.
5Lẹ́yin náà, wọn ẹgbẹ̀ẹ́dogun (3000) ẹṣẹ̀ bàtà lápá ibi ìhà ìlà oòrùn ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ẹṣẹ̀ bàtà ní ìhà gúsù, ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, àríwá. Pẹ̀lú ìlú ní àárin. Wọn yóò ní agbégbé yìí gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ pápá oko tútù fún ìlú náà.
6
7Ní gbogbo rẹ̀, kí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì ní éjìdínláàdọ́ta (48) ìlú lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.
8Ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì láti ara ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jogún, olúkúlùkù kí ó fi nínú ìlú rẹ̀ fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní rẹ̀ tí ó ní. Gba púpọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní púpọ̀ àti díẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní díẹ̀.”
9
10“Sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì sọ fún wọn: ‘Nígbà tí ẹ bá rékọjá odò Jọ́dánì sí Kénánì,
11Yan àwọn ìlú kan láti jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìlú ìsásí fún yín, kí apani tó pa ènìyàn ní àìmọ̀ máa sá lọ síbẹ̀.
12Wọn yóò jẹ́ ibi ìsásí kúrò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san, kí ẹní tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn má baà kú kí ó tó dúró níwájú àwọn ìjọ àwọn ènìyàn ní ìdájọ́.
13Mẹ́fà nínú ìlú tí ẹ ó fi fún wọn yóò jẹ́ ìlú ààbò fún yín.
14Yan ìlú mẹ́ta ní ìhà ti Jọ́dánì, kí ẹ sì yan ìlú mẹ́ta ní ìhà Kénánì tí yóò máa jẹ́ ìlú ìsásí.
15Ìlú mẹ́fà yìí yóò jẹ́ ìlú ìsásí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, fún àlejò àti ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé láàrin wọn, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn ní àìmọ̀ sá lọ ṣíbẹ̀.
16“ ‘Bí ọkùnrin kan bá fi ohun èlò irin lu ènìyàn tí ó kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pá, apànìyàn náà.
17Tàbí tí ènìyàn bá mú òkúta tí ó lè pa ènìyàn lọ́wọ́ tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pa apànìyàn náà.
18Tàbí tí ènìyàn bá mú ohun èlò igi ní ọwọ́ ọ rẹ̀ tí ó sì lẹ̀ ẹ́ pa ènìyàn, tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni; pípa ní a ó pa apànìyàn náà.
19Olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ yóò pa apànìyàn náà; tí ó bá bá a, yóò pa á.
20Tí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń yan odì pẹ̀lú ìríra tí ẹlòmíràn tàbí ju nǹkan sí i pẹ̀lú èrò, tí ó sì kú.
21Tàbí pẹ̀lú ìjà gbangba lù ú pẹ̀lú ìkúùkù tí ó sì kú, pípa ni a ó pa ẹni bẹ́ẹ̀; apànìyàn ni. Olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ yóò pa apànìyàn náà tí ó bá bá a.
22“ ‘Ṣùgbọ́n bí ó bá fi nǹkan gún un lójijì láìṣọ̀ta, tàbí tí ó sọ ohunkóhun lù ú láìmọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣe
23tàbí, láìri, ju òkúta sí tí ó lè pa á, tí ó sì kú, nígbà tí kì í ṣe ọ̀ta rẹ̀, láti ṣe é léṣe,
24Àwọn àpèjọ gbúdọ̀ dájọ́ láàrin rẹ̀ àti olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà.
25Àpèjọ gbọ́dọ̀ dá ààbò bo ẹni tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn, kí a sì ran-an padà lọ sí ìlú ìsásí tí ó ti wá. Ó gbúdọ̀ dúró níbẹ̀ títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú, ẹni tí a fi àmì òróró yàn.
26“ ‘Ṣùgbọ́n ti ẹni tí a fi sùn kan bá jáde kọjá ààlà ìlú ìsásí tí ó sá sí.
27Tí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ sì ri ní ìta ìlú náà, olùgbẹ̀san lè pa ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn láì jẹ́bi ẹ̀sùn ìpànìyàn.
28Ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn gbọdọ̀ dúró nínú ìlú ìsásí títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú; lẹ́yìn ikú olórí àlùfáà, ni ó tó lè padà sí ibi tí dúkìá rẹ̀ wà.
29“ ‘Wọ̀nyí ni ó jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún yín ní ìran yín tó ń bọ̀, ní ibikíbi tí ẹ bá ń gbé.
30
31“ ‘Má ṣe gba ohun ìràpadà fún ẹ̀mí olùpànìyàn, tí ó yẹ kí ó kú. A gbọ́dọ̀ pa á.
32“ ‘Má ṣe gba ìràsílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá lọ sí ìlú ìsásí, pe kí ó padà máa gbé ní ilẹ̀ tirẹ̀ kí ó tó di ìgbà ikú olórí àlùfáà.
33“ ‘Má ṣe sọ ilẹ̀ tí ẹ wà di àìmọ́. Ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sọ ilẹ̀ náà di àìmọ́. Atúnṣe kì yóò sí fún ilẹ̀ tí a ti ta ẹ̀jẹ̀ lé lórí, àyà fi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó ta á sílẹ̀.
34Má se sọ di àìmọ́, ilẹ̀ tí ẹ ń gbé, àti èyí tí mo ń gbé, nítorí Èmi JÈHÓFÀ, ń gbé láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’ ”