Ìwé Nehemáyà 11:1-36 BYB2014 - Bible AI

1Nísinsinyìí àwọn olórí àwọn ènìyàn tẹ̀dó sí Jérúsálẹ́mù, àwọn ènìyàn tó kù sì dìbò láti mú ẹnì kọ̀ọ̀kan jáde nínú àwọn mẹ́wàá mẹ́wàá láti máa gbé ní Jérúsálẹ́mù, ìlú mímọ́, nígbà tí àwọn mẹ́sàn-án tó kù yóò dúró sí àwọn ìlúu wọn.

2Àwọn ènìyàn súre fún gbogbo àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn láti gbé ní Jérúsálẹ́mù.

3ⓐ Wọ̀nyí ni àwọn olórí agbègbè ìjọba tí wọ́n tẹ̀dó sí Jérúsálẹ́mù (díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti àwọn ìran àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì ń gbé àwọn ìlúu Júdà, olúkúlùkù ń gbé lórí ilẹ̀ ìníi rẹ̀ ní àwọn ìlú náà.

4Nígbà tí àwọn ènìyàn tó kù nínú àwọn Júdà àti Bẹ́ńjámínìn ń gbé ní Jérúsálẹ́mù): Átaáyà ọmọ Úṣáyà ọmọ Ṣekaráyà, ọmọ Ámáráyà, ọmọ Ṣefatayà, ọmọ Máhálálélì, ìran Pérésì;

4Nínú àwọn ọmọ Júdà:

5àti Maaṣeayà ọmọ Bárúkì, ọmọ Koli-Hóṣè, ọmọ Haṣaíyà, ọmọ Ádáyà, ọmọ Joiaribù, ọmọ Ṣekaráyà, ìran Ṣélà.

6Àwọn ìran Pérésì tó gbé ní Jérúsálẹ́mù jẹ́ àádọ́rin lé nírínwó ó dín méjì (468) alágbára ọkùnrin.

7Nínú àwọn ìran Bẹ́ńjámínì: Ṣálù ọmọ Mésúlámù, ọmọ Jóédì, ọmọ Pédáyà, ọmọ Kóláyà, ọmọ Maaṣéyà, ọmọ Itíélì, ọmọ Jéṣáyà,

8àti àwọn ọmọ ẹ̀yìnin rẹ̀, Gábáì àti Ṣáláì jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rún ó lé mẹ́jọ (928) ọkùnrin.

9Jóẹ́lì ọmọ Ṣíkírì ni olóórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn, Júdà ọmọ Haṣenuáyà sì ni olórí agbégbé kejì ní ìlú náà.

10Nínú àwọn àlùfáà: Jédáyà; ọmọ Jóáríbù; Jákínì;

11Ṣéráyà ọmọ Hílíkáyà, ọmọ Mésúlámù, ọmọ Ṣádókì, ọmọ Méráótì, ọmọ Áhítúbì alábojútó ní ilé Ọlọ́run,

12àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ní tẹ́ḿpìlì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó lé mẹ́rinlélógún (822) ọkùnrin: Ádáyà ọmọ Jéróhámù, ọmọ Péláyà, ọmọ Ámísì, ọmọ Ṣakaráyà, ọmọ Pásúrì, ọmọ Málíkíjà,

13àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí ìdílé jẹ́ òjìlúgba ó lé méjì (242) ọkùnrin: Ámáṣíṣáì ọmọ Áṣárélì, ọmọ Áṣáì, ọmọ Méṣílémótì, ọmọ Ìmérì,

14àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ alágbára ọkúnrin jẹ́ méjìdínláàdọ́je (128). Olórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn ni Sábídíelì ọmọ Hágédólímù.

15Láti inú àwọn ọmọ Léfì: Ṣémáyà ọmọ Háṣúbù, ọmọ Ásíríkámù, ọmọ Háṣábíyà ọmọ Búnì;

16Ṣábétaì àti Jóṣábádì, olórí méjì nínú àwọn ọmọ Léfì, àwọn tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ tí ó wà ní ẹ̀yìn àgbàlá ilé Ọlọ́run;

17Mátaníyà ọmọ Míkà, ọmọ Ṣábídì, ọmọ Áṣáfì, adarí tí ó rí ṣáájú ìdúpẹ́ àti àdúrà; Bákíbúkíyà ẹnìkejì láàrin àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀; àti Ábídà ọmọ Ṣámúyà, ọmọ Gálálì, ọmọ Jédútúmù.

18Àwọn ọmọ Léfì nínú ìlú mímọ́ jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́rin (284).

19Àwọn aṣọ́nà: Ákúbù, Tálímónì, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n máa ń ṣọ́nà jẹ́ méjìléláàdọ́-sàn-án (172) ọkùnrin.

20Àwọn tó kù nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, wà ní gbogbo ìlúu Júdà, olúkúlùkù lórí ilẹ̀ ìníi tirẹ̀.

21Àwọn ìránṣẹ́ẹ tẹ́ḿpílì ń gbé lórí òkè òfélì, Ṣíhà àti Gíṣípà sì ni alábojútó wọn.

22Olórí òṣìṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì ní Jérúsálẹ́mù ní Húsì ọmọ Bánì, ọmọ Hásábíà, ọmọ Mátaníyà ọmọ Míkà. Húṣì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìran Áṣáfù tí wọ́n jẹ́ akọrin ojúṣe nínú ìjọsìn ní ilé Ọlọ́run.

23Àwọn akọrin wà ní abẹ́ àṣẹ ọba, èyí tí ó n díwọ̀n iṣẹ́ ojoojúmọ́ọ wọn.

24Petaiayọ̀ ọmọ Meṣeṣabélì, ọ̀kan nínú àwọn Ṣérà ọmọ Júdà ní aṣojú ọba nínú ohun gbogbo tí ó jẹ mọ́ ti àwọn ènìyàn náà.

25Fún ìletò pẹ̀lú oko wọn, díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn Júdà tí ń gbé Kíríátí-Ábà, àti àwọn ìletò agbégbé e rẹ̀, ní Díbónì àti ìletò rẹ̀, ní Jékábíṣéélì.

26Ní Jéṣúà, ní Móládà, ní Bétípélétì

27Ní Háṣárì Ṣúálì, ní Bíáṣébà àti àwọn agbégbé rẹ̀.

28Ní Ṣíkílágì, ní Mékónà àti àwọn ìletò rẹ̀,

29ní Ẹni-rímónì, ní ṣórà, ní Járímútì,

30Ṣánóà, Ádúlámù àti àwọn ìletò o wọn, ní Lákísì àti àwọn oko rẹ̀, àti ní Ásékà àti awọn ìletò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé láti Bíáṣébà títí dé àfonífojì Hínómì.

31Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì láti Gébì ń gbé ní Míkímásì, Áíjà, Bétélì àti àwọn ìletò rẹ̀.

32Ní Ánátótì, Nóbù àti Ánáníyà,

33Ní Háṣórì Rámà àti Gítaímù,

34Ní Hádídì, Ṣébóimù àti Nébálátì,

35Ní Lódì àti Ónò, àti ní àfonífojì àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà.

36Nínú ìpín àwọn ọmọ Léfì ni Júdà tẹ̀dó sí Bẹ́ńjámínì.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
/div>