Ìwé Nehemáyà 4:1-23 BYB2014 - Bible AI

1Nígbà tí Ṣáńbálátì gbọ́ pé àwa ń tún odi náà mọ, ó bínú, ó sì bínú púpọ̀. Ó fi àwọn ará Júù ṣe ẹlẹ́yà,

2ó sọ níwájú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àti níwájú àwọn ọmọ ogun Ṣamáríà pé, “Kí ni àwọn aláìlera Júù wọ̀nyí ń ṣe yìí? Ṣé wọn yóò mú odi wọn padà ni? Ṣé wọn yóò rú ẹbọ ni? Ṣé wọn yóò paríi rẹ̀ lóòjọ́ ni bí? Ṣé wọ́n lè mú òkúta tí a ti ṣun láti inú òkítì padà bọ̀ sípò tí ó jóná bí wọ́n ṣe wà yẹn?”

3Tóbíyà ará Ámónì, ẹni tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, wí pé, “Ohun tí wọ́n ń mọ—bí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ lásán bá gùn-ún sókè, yóò fọ́ odi òkúta wọn lulẹ̀!”

4Gbọ́ ti wa, Ọlọ́run wa, nítorí àwa di ẹni ẹ̀gàn. Dá ẹ̀gàn wọn padà sórí ara wọn. Kí o sì fi wọ́n fún ìkógun ní ilẹ̀ ìgbékùn.

5Má ṣe bo ẹ̀bi wọn tàbí wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn nù kúrò níwájúú rẹ, nítorí wọ́n mú ọ bínú níwájú àwọn ọ̀mọ̀lé.

6Bẹ́ẹ̀ ni àwa mọ odi náà títí gbogbo rẹ̀ fi dé ìdajìi gíga rẹ̀, nítorí àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́ pẹ̀lúu gbogbo ọkàn an wọn.

7Ṣùgbọ́n nígbà tí Ṣáńbálátì, Tóbíyà, àwọn ará Árábù, ará Ámónì, àti àwọn ènìyàn Áṣídódì gbọ́ pé àtúnṣe odi Jérúsálẹ́mù ti ga dé òkè àti pé a ti mọ àwọn ibi tí ó yá dí, inú bí wọn gidigidi.

8Gbogbo wọn jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti wá bá Jérúsálẹ́mù jà àti láti dìde wàhálà sí í.

9Ṣùgbọ́n àwa gbàdúrà sí Ọlọ́run wa, a sì yan olùṣọ́ ọ̀sán àti ti òru láti kojú ìhàlẹ̀ yìí.

10Lákòókò yìí, àwọn ènìyàn Júdà wí pé, “Agbára àwọn òṣìṣẹ́ ti dínkù, àlàpà púpọ̀ ni ó wà tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi le è mọ odi náà.”

11Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọ̀ta wa wí pé, “Kí wọn tó mọ̀ tàbí kí wọn tó rí wa, àwa yóò ti dé àárin wọn, a ó sì pa wọ́n, a ó sì dá iṣẹ́ náà dúró.”

12Nígbà náà ni àwọn Júù tí ó ń gbé ní ẹ̀gbẹ́ẹ wọn wá sọ fún wa ní ìgbà mẹ́wàá pé, “Ibikíbi tí ẹ̀yin bá padà sí, wọn yóò kọ lù wá.”

13Nítorí náà mo dá ènìyàn díẹ̀ dúró níbi tí ó rẹlẹ̀ jù lẹ́yìn odi ní ibi gbangba, mo fi wọ́n síbẹ̀ nípa àwọn ìdílée wọn, pẹ̀lú àwọn idà wọn, àwọn ọ̀kọ̀ wọn àti àwọn ọrun wọn.

14Lẹ́yìn ìgbà tí mo wo àwọn nǹkan yíká, mo dìde mo sì wí fún àwọn ọlọ́lá àwọn ìjòyè àti àwọn ènìyàn tó kù pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù u wọn. Ẹ rántí OLÚWA, ẹni tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù, kí ẹ sì jà fún àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, àwọn ìyàwó yín àti àwọn ilée yín.”

15Nígbà tí àwọn ọ̀ta wa gbọ́ pé àwa ti mọ ọ̀tá wọn àti wí pé Ọlọ́run ti bàájẹ́, gbogbo wa padà sí ibi odi, ẹnìkọ̀ọ̀kan sí ibi iṣẹ́ tirẹ̀.

16Láti ọjọ́ náà lọ, ìdajì àwọn ènìyàn ń ṣe iṣẹ́ náà, nígbà tí àwọn ìdajì tó kù múra pẹ̀lú ọ̀kọ̀, àṣà, ọrun àti ìhámọ́ra. Àwọn ìjòyè sì pín ara wọn ṣẹ́yìn in gbogbo ènìyàn Júdà.

17Àwọn ẹni tí ó ń mọ odi. Àwọn tí ń ru àwọn ohun èlò ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú ọwọ́ kan, wọ́n sì fi ọwọ́ kejì di ohun ìjà mú,

18olúkúlùkù àwọn ọ̀mọ̀lé fi idàa wọn sí ẹ̀gbẹ́ẹ wọn bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ń fọn ìpè dúró pẹ̀lúù mi.

19Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè àti àwọn ènìyàn tó kù pé, “Iṣẹ́ náà fẹ̀ ó sì pọ̀, a sì ti jìnnà sí ara wa púpọ̀ lórí odi.

20Níbikíbi tí ẹ bá ti gbọ́ ohùn ìpè, ẹ da ara pọ̀ mọ́ wa níbẹ̀. Ọlọ́run wa yóò jà fún wa!”

21Bẹ́ẹ̀ ni àwa ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àwọn ìdajì ènìyàn tí ó di ọ̀kọ̀ mú, láti òwúrọ̀ kùtùkùtù títí di ìgbà tí ìràwọ̀ yóò fi yọ.

22Ní ìgbà náà mo tún sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn àti olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ dúró ní Jérúsálẹ́mù ní òru, nítorí kí wọn le jẹ́ ẹ̀ṣọ́ fún wa ní òru, kí wọn sì le ṣe iṣẹ́ ní ọ̀sán.”

23Bẹ́ẹ̀ ni èmi àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn ènìyàn mi àti àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó wà pẹ̀lúù mi kò bọ́ aṣọ wa, olúkúlùkù wa ní ohun ìjà tirẹ̀, kó dà nígbà tí wọ́n bá ń lọ pọn omi.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>