Ìwé Nehemáyà 7:1-73 BYB2014 - Bible AI

1Lẹ́yìn ìgbà tí a tún odi mọ tán tí mo sì rì àwọn ìlẹ̀kùn sí ààyè wọn, a sì yan àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin àti àwọn Léfì.

2Mo fún Hánánì arákùnrin mi pẹ̀lú Hananáyà olórí ilé ìṣọ́ ní àṣẹ lórí Jérúsálẹ́mù, nítorí tí ó jẹ́ ènìyàn olóòótọ́, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run jù bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ṣe lọ.

3Mo sọ fún wọn pé, “A kò gbọdọ̀ sí ìlẹ̀kùn Jérúsálẹ́mù títí oòrùn yóò fi mú. Nígbà tí àwọn aṣọ́bodè bá sì wà lẹ́nu iṣẹ́, jẹ́ kí wọn ti ìlẹ̀kùn kí wọn sì há wọn. Bákan náà, yàn nínú àwọn tí ń gbé Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́. Àwọn mìíràn níbi tí a pín wọn sí àti àwọn mìíràn ní tòsí ilé e wọn.”

4Ìlú náà tóbi ó sì ní ààyè, ṣùgbọ́n ènìyàn inú rẹ̀ kéré, a kò sì tí ì tún àwọn ilé inú rẹ̀ kọ́.

5Nígbà náà ni Ọlọ́run mi fi sí mi ní ọkàn láti kó àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè, àti àwọn ènìyàn jọ fún ìforúkọsílẹ̀ ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn ìran àwọn tí ó kọ́ gòkè padà wá láti ìgbèkùn. Èyí ni ohun tí mo rí tí a kọ sínú ìwé náà:

6ⓐ Èyí ni àwọn ènìyàn agbègbè náà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti ìgbèkùn, àwọn tí Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì ti kó ní ìgbékùn (wọ́n padà sí Jérúsálẹ́mù àti Júdà, olúkúlùkù sí ìlúu rẹ̀.

7Wọ́n jọ rìn wá pẹ̀lú u Ṣérúbábélì, Jéṣúà, Nehemáyà, Asaráyà, Ráámáyà, Náhámánì, Módékáì, Bíṣánì, Míṣípérétì, Bígífáyì, Néhúmù, àti Báánà):

7Àkọsílẹ̀ Orúkọ Àwọn Ọkùnrin Ísírẹ́lì:

8Àwọn ìran Párósì ẹgbàá ó lé méjìléláàádọ́sàn-án — (2,172)

8

9ti Ṣéfátayà, òjìdínrinwó ó lé méjìlá — (372)

9

10ti Árà, ẹgbẹ̀tàléláàdọ́ta ó lé méjì — (652)

10

11ti Páhátì—Móábù (láti ipaṣẹ̀ ìran Jéṣúà àti Jóábù) ẹgbàá mẹ́rìnlá ó lé méjìdínlógún — (2,818)

11

12ti Élámù, ẹgbàafà ó lé mẹ́rìnléláàdọ́ta — (1,254)

12

13ti Ṣátù, òjìlélẹ́gbẹ̀rin ó lé márùn-ún — (845)

13

14ti Ṣákáì, òjìdínlẹ́gbẹ̀rin — (760)

14

15ti Bínúì, òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́jọ — (648)

15

16ti Bébáì, ẹgbẹ̀ta ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n — (628)

16

17ti Áṣígádì, ẹgbẹ̀ta ó dín méjìdínlọ́gọ́rin — (2,322)

17

18ti Ádóníkámù, ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méje — (667)

18

19ti Bígífáyì, ẹgbàá ó lé mẹ́tadínláàdọ́rin — (2,067)

19

20ti Ádínì, àádọ́tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé márùn-ún — (655)

20

21ti Átérì, (láti ipaṣẹ Esekáyà) méjìdínlọ́gọ́rùn-ún — (98)

21

22ti Áṣúmù, ọ̀rìndínnírinwó ó lé mẹ́jọ — (328)

22

23ti Béṣáì, ọ̀rìndínírinwó ó lé mẹ́rin — (324)

23

24ti Árífù méjìléláàdọ́fà — (112)

24

25ti Gíbíónì, márùnúndínlọ́gọ́rùn-ún — (95)

26Àwọn ọkùnrin Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti Nétófà, igba ó dín méjìlélógún — (188)

27ti Ánátótì, méjìdínláàdóje — (128)

27

28ti Bẹti-Ásímáfétì, méjìlélógójì — (42)

28

29ti Kiriati-Jíárímù, Kífírà, àti Béérótì, ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta — (743)

29

30ti Rámà àti Gébà, ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún — (621)

30

31ti Míkímásì, méjìlélọ́gọ́fà — (122)

31

32ti Bẹ́tẹ́lì àti Áì, mẹ́talélọ́gọ́fà — (123)

32

33ti Nébò mìíràn, méjìléláàdọ́ta — (52)

33

34ti Élámù mìíràn, ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́rìnléláàdọ́ta — (1,254)

34

35ti Hárímù, ọ̀rìndínnírínwó — (320)

35

36ti Jẹ́ríkò, ọ̀tàdínnírínwó ó lé márùn-ún — (345)

36

37ti Lódì, Hádídì, àti Ónò, ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó lé ọ̀kàn — (721)

37

38ti Ṣénáà ẹgbáàjì ó dín àádọ́rin — (3,930)

39Àwọn Àlùfáà: — àwọn ìran Jédáyà (láti ipaṣẹ̀ ìdílé Jéṣúà) ẹgbàá ó dín mẹ́tadínlọ́gbọ̀n — (973)

40ti Ímérì, ẹgbẹ̀rùn-ún ó lé méjìléláàdọ́ta — (1,052)

40

41ti Páṣúrì, ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tadínláàdọ́ta — (1,247)

41

42ti Hárímù ẹgbẹ̀rùn-ún ó lé mẹ́tadínlógún — (1,017)

43Àwọn Ìran Léfì: — àwọn ìran Jéṣúà (láti ipaṣẹ̀ Kádímélì, láti ipaṣẹ̀ Hódáfíà) mẹ́rìnléláàdọ́rin — (74)

44Àwọn akọrin: — àwọn ìran Áṣáfù, méjìdínláàdọ́jọ — (148)

45Àwọn Aṣọ́bodè: — àwọn ìran — Ṣílámù, Átérì, Támónì, Ákúbù, Hátítà, àti Ṣóbáì, méjìdínlógóje — (138)

46Àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì: — Àwọn Aran — Ṣíhà, Haṣúfà, Tábáótì,

47Kérósì, Ṣíà, Pádónì,

47

48Lébánà, Hágábà, Ṣámáyì,

48

49Hánánì, Gídélì, Gáhárì,

49

50Réáyà, Réṣínì, Nékódà,

50

51Gáṣámù, Úṣà, Fáṣíà,

51

52Béṣáì, Méhúnímù, Néfíṣésímù,

52

53Bábúkù, Hákúfà, Háhúrì,

53

54Básílítù, Méhídà, Hárísà,

54

55Bákósì, Ṣísérà, Témà,

55

56Néṣíà, àti Hátífà

57Àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì: — àwọn ìranṣẹ́ — Ṣótaì, Ṣóférétì; Pérídà,

58Jáálà, Dákónì, Gídélì,

58

59Ṣéfátíyà, Hatílì,

59— Pókérítì-Héṣebáímù, àti Ámónì.

60Àwọn ìránṣẹ́ ilé tẹ́ḿpìlì àti àwọn ìran ìránṣẹ́ Sólómónì jẹ́ irinwó dín mẹ́jọ — (392)

61Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti Tẹ́lì-mẹ́là, Tẹ́lì-Hásíhà, Kérúbù, Ádónì àti Ímérì, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Ísírẹ́lì:

62Àwọn ìran — Déláyà, Tóbíyà àti Nékódà, jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì — (642)

63Lára àwọn àlùfáà ni: — àwọn ìran — Hóbáíyà, Hákósì àti Básíláì (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Básíláì ará Gílíádì, ẹni tí a ń fi orúkọ yìí pè).

64Àwọn wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í nibẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́;

65Baálẹ̀, sọ fún wọn nítorí náà pé wọn kò gbọdọ̀ kópa nínú un jíjẹ oúnjẹ mímọ́ títí tí àlùfáà tí yóò wá tí ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lúu Úrímù àti Tímímù yóò fi dé.

66Gbogbo ìjọ ènìyàn tí wọ́n péjọ pọ̀ jẹ́ ẹgbàámọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó (42,360)

67yàtọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀tàdínlẹ́gbaàrin ó dín ẹ̀tàlélọ́gọ́ta (7,337); wọ́n sì tún ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún (245).

68Ẹṣin wọn jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin (736): ìbáákà wọn jẹ́ òjìlúgba ó dín márùn-ún (245);

69Ràkunmí wọn jẹ́ òjìlénírinwó ó dín márùn-ún (435); kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rinlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin (6720).

70Díẹ̀ lára àwọn olóórí ìdílé náà kópa nínú un ṣíṣe iṣẹ́ náà Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún dírámásì wúrà, (kílò mẹ́jọ ààbọ̀) àádọ́ta bóòlù àti ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́wàá ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.

71Díẹ̀ lára àwọn olóórí ìdílé fún ilé ìṣúra ní ọ̀kẹ́ méjì dírámásì wúrà (àádọ́sàn án kílò) (20,000) àti ẹgbọ̀kànlá mínà fàdákà (2,200) (tọ́ùn kan ààbọ̀).

72Àròpọ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn tókù fi sílẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì dírámásì wúrà, ẹgbẹ̀rùn-ún méjì mínà fàdákà àti ẹ̀tàdínláàdọ́rin ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.

73Àwọn àlùfáà, àwọn Léfì, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ènìyàn díẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ ilé Ọlọ́run, àti gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì wà ní ìlúu wọn. Nígbà tí ó di oṣù keje tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti wà nínú ìlúu wọn,

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>