1Nígbà kan Sámúsónì gòkè lọ sí Tímínà níbẹ̀ ni ó ti rí ọmọbìnrin Fílístínì kan.
2Nígbà tí ó darí (padà sílé) dé, ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ (baba àti ìyá rẹ̀) pé, “Mo rí obìnrin Fílístínì kan ní Tímínà: báyìí ẹ fẹ́ ẹ fún mi bí aya mi”
3Baba àti ìyá rẹ̀ dáhùn pé, ṣé kò sí obìnrin tí ó dára tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn ní àárin àwọn ìbátan rẹ, tàbí láàárin gbogbo àwọn ènìyàn wa? Ṣé ó di túlàsì fún ọ láti lọ sí àárin àwọn Fílístínì aláìkọlà kí o tó fẹ́ ìyàwó?
4(Àwọn òbí rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀dọ̀ OLÚWA ni nǹkan yìí ti wá, ẹni tí ń wá ọ̀nà àti bá Fílístínì jà; nítorí àwọn ni ń ṣe àkóso Ísírẹ́lì ní àkókò náà.)
5Sámúsónì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Tímínà òun àti bàbá àti ìyá rẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń súnmọ́ àwọn ọgbà àjàrà tí ó wà ní Tímínà, láìrò tẹ́lẹ̀, ọ̀dọ́ kìnnìún kan jáde síta tí ń ké ramúramù bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
6Ẹ̀mí OLÚWA sì bà lé e pẹ̀lú agbára tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fa kìnnìún náà ya pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lásán bí ẹní ya ọmọ ewúrẹ́, ṣùgbọ́n òun kò sọ ohun tí ó ṣe fún baba tàbí ìyá rẹ̀.
7Ó sì lọ bá obìnrin náà sọ̀rọ̀, inú Sámúsónì sì yọ́ sí i.
8Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, nígbà tí ó padà lọ láti gbé e níyàwó, ó yà lọ láti wo òkú kìnìún náà. Inú rẹ̀ ni ó ti bá ọ̀pọ̀ ìṣù oyin àti oyin,
9ó fi ọwọ́ ha jáde, ó sì ń jẹ ẹ́ bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, ó fún wọn ní díẹ̀, àwọn náà sì jẹ, ṣùgbọ́n kò sọ fún wọn pé ara òkú kìnnìún ni òun ti rí oyin náà.
10Baba rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti kí obìnrin náà. Sámúsónì sì ṣe àṣè gẹ́gẹ́ bí àṣà ọkọ ìyàwó ní àkókò náà.
11Nígbà tí ó fara hàn, tí àwọn ènìyàn náà rí i wọ́n fún un ní ọgbọ̀n àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti wá bá a kẹ́gbẹ́.
12Sámúsónì sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún un yín, bí ẹ̀yin bá lè fún mi ní ìtúmọ̀ rẹ̀ láàárin ọjọ́ méje àsè yìí, tàbí ṣe àwárí àdìtú náà èmi yóò fún un yín ní ọgbọ̀n (30) aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun, àti ọgbọ̀n (30) ìpàrọ̀ aṣọ ìyàwó.
13Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kò bá le sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún mi, ẹ̀yin yóò fún mi ní ọgbọ̀n (30) aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun àti ọgbọ̀n ìpàrọ̀ aṣọ ìgbéyàwó.”
14Ó dáhùn pé,
15Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n wí fún ìyàwó Sámúsónì, pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó lè ṣe àlàyé àlọ́ náà fún wa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò sun ìwọ àti ìdílé baba rẹ̀ ní iná. Tàbí ṣe o pè wá sí ibi àsè yìí láti sọ wá di òtòsì tàbí kó wa lẹ́rú ni?”
16Nígbà náà ni ìyàwó Sámúsónì ṣubú lé e láyà, ó sì sunkún ní iwájú rẹ̀ pé, “O kórìíra mi! o kò sì ní ìfẹ́ mi nítòótọ́, o pàlọ́ fún àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún mi.”
17Fún gbogbo ọjọ́ méje tí wọ́n fi ṣe àsè náà ni ó fi sunkún, nítorí náà ní ọjọ́ keje ó sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún un nítorí pé ó yọ ọ́ lẹ́nu ní ojoojúmọ́. Òun náà sì sọ ìtúmọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ènìyàn rẹ̀
18Kí ó tó di àṣálẹ́ ọjọ́ keje àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún un pé,
19Lẹ́yìn èyí, ẹ̀mí OLÚWA bà lé e pẹ̀lú agbára. Ó lọ sí Ásíkélónì, ó pa ọgbọ̀n (30) nínú àwọn ọkùnrin wọn, ó gba àwọn ohun ìní wọn, ó sì fi àwọn aṣọ wọn fún àwọn tí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà. Ó sì padà sí ilé baba rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú ríru.
20Wọ́n sì fi ìyàwó Sámúsónì fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ rẹ̀ nígbà ìgbéyàwó rẹ̀.