Ìwé Onídájọ́ 15:1-20 BYB2014 - Bible AI

1Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ní àkókò ìkórè jéró Sámúsónì mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan láti bẹ ìyàwó rẹ̀ wò. Ó ní, “Èmi yóò wọ yàrá ìyàwó mi lọ.” Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà á láàyè láti wọlé.

2Baba ìyàwó dá a lóhùn pé, “Ó dá mi lójú pé o kórìíra rẹ̀, torí náà mo ti fi fún ọ̀rẹ́ rẹ, ṣebí àbúrò rẹ̀ obìnrin kò ha lẹ́wà jù lọ? Fẹ́ ẹ dípò rẹ̀.”

3Sámúsónì dáhùn pé, “Ní àkókò yìí tí mo bá ṣe àwọn Fílístínì ní ibi èmi yóò jẹ́ aláìjẹ̀bi.”

4Òun sì jáde lọ, ó mú ọ̀ọ́dúnrún (300) kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ó so ìrù wọn mọ́ ara wọn ní méjìméjì. Ó mú ètùfù iná, ó so ó mọ́ àwọn ìrù tí ó so pọ̀.

5Ó fi iná ran àwọn ètúfù tí ó so náà, ó sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ sínú àwọn oko ọkà àwọn Fílístínì. Ó jó àwọn pòpóòrò ọkà tí ó dúró àti àwọn tí a dì ní ìtí, ìtí, pẹ̀lú àwọn oko àjàrà àti ólífì.

6Nígbà tí àwọn Fílístínì béèrè pé, “Ta ni ó ṣe èyí?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Sámúsónì ará Tímínà ni, nítorí o gba ìyàwó rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Nítorí náà àwọn Fílístínì lọ wọ́n sì ṣun obìnrin náà àti baba rẹ̀.

7Sámúsónì sọ fún un pé, “Nítorí pé ẹ̀yin ṣe èyí, èmi kò dẹṣẹ̀ (dúró) títí èmi yóò fi gbẹ̀ṣan mi lára yín.”

8Ó kọ lù wọ́n pẹ̀lú ìbínú àti agbára ńlá, ó sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn. Lẹ́yìn náà ni ó lọ, ó sì dúró nínú ihò àpáta kan nínú àpáta Étamù.

9Àwọn ará Fílístínì sì dìde ogun sí Júdà, wọ́n ti tan ara wọn ká sí agbégbé Léhì.

10Àwọn ọkùnrin Júdà sì bèèrè pé, “Èéṣe tí ẹ fi wá gbógun tì wá?”

10Ìdáhùn wọn ni pé, “Awá láti mú Sámúsónì ní ìgbékùn, kí a ṣe sí i bí òun ti ṣe sí wa.”

11Nígbà náà ni ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ọkùnrin láti Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ sí ihò àpáta nínú àpáta Étamù, wọ́n sì sọ fún Sámúsónì pé, “Kò ti yé ọ pé àwọn Fílístínì ní ń ṣe alákóṣo lórí wa? Kí ni o ṣe sí wa?” Òun sì dáhùn pé, “Ohun tí wọ́n ṣe sí mi ni èmi náà ṣe sí wọn.”

12Wọ́n wí pé, “Àwa wá láti dè ọ́, kí a sì fi ọ́ lé àwọn Fílístínì lọ́wọ́.” Sámúsónì wí pé, “Ẹ búra fún mi pé, ẹ̀yin kì yóò fúnra yín pa mí.”

13“Àwá gbà,” ni ìdáhùn wọn. “Àwa yóò kàn dè ọ́, awa yóò sì fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́, àwa kì yóò pa ọ́.” Wọ́n sì dé pẹ̀lú okùn túntún méjì, wọ́n sì mú u jáde wá láti ihò àpáta náà.

14Bí ó ti sún mọ́ Léhì, àwọn Fílístínì ń pariwo bí wọ́n ṣe ń tò bọ̀. Ẹ̀mí OLÚWA bà lé e pẹ̀lú agbára. Àwọn okùn ọwọ́ rẹ̀ dàbí òwú tí ó jóná, ìdè ọwọ́ rẹ̀ já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

15Nígbà tí ó rí egungun àgbọ̀n ìṣàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ túntún kan, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹ̀rún ọkùnrin.

16Sámúsónì sì wí pé, “Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan Mo sọ wọ́n di òkìtì kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan Mo ti pa ẹgbẹ̀rún ọkùnrin.”

17Nígbà tí ó dákẹ́ ọ̀rọ̀ ísọ, ó ju egungun àgbọ̀n ìṣàlẹ̀ náà nù, wọ́n sì pe ibẹ̀ ní Ramati-Léhì (ìtúmọ̀ rẹ̀ jẹ́ egungun àgbọ̀n ìṣàlẹ̀ pa).

18Nítorí tí òǹgbẹ gbẹ ẹ́ gidigidi, ó ké pe OLÚWA, wí pé, “Ìwọ ti fún ìránṣẹ́ ní ìṣẹ́gun tí ó tóbi yìí. Ṣé èmi yóò ha kú pẹ̀lú òǹgbẹ, kí èmi sì ṣubú sí ọwọ́ àwọn aláìkọlà ènìyàn?”

19Nígbà náà ni Ọlọ́run la kòtò ìṣun omi tí ó wà ní Léhì, omi sì tú jáde láti inú rẹ̀. Nígbà tí Sámúsónì mú mi tan, agbára rẹ̀ sì padà, ọkàn sì sọjí, fún ìdí èyí wọ́n pe ìṣun omi náà ni. Ẹni Hákkò rẹ (oríṣun ẹni tí ó pe Ọlọ́run) èyí tí ó sì wà ní Léhì di òní.

20Sámúsónì ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ogún ọdún ní àkókò àwọn ará Fílístínì.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
/div>