1Ní ọjọ́ kan Sámúsónì lọ sí Gásà níbi tí ó ti rí obìnrin aṣẹ́wó kan. Ó wọlé tọ̀ ọ́ láti ṣun ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òru ọjọ́ náà.
2Àwọn ará Gásà sì gbọ́ wí pé, “Sámúsónì wà níbí.” Wọ́n sì yí agbégbé náà ká, wọ́n ń ṣọ́ ọ ní gbogbo òru náà ní ẹnu bodè ìlú náà. Wọn kò mira ní gbogbo òrú náà pé ní “àfẹ̀mọ́júmọ́ àwa yóò pa á”
3Ṣùgbọ́n Sámúsónì sùn níbẹ̀ di àárin ọ̀gànjọ́ (èyí nì di agogo méjìlá òru). Òun sì dìde ní ọ̀gànjọ́, ó fi ọwọ́ di àwọn ìlẹ̀kùn odi ìlú náà mú, pẹ̀lú òpó méjèèjì, ó sì fà wọ́n tu, pẹ̀lú ìdábú àti ohun gbogbo tí ó wà lára rẹ̀. Ó gbé wọn lé èjìká rẹ̀ òun sì gbé wọn lọ sí orí òkè tí ó kọjú sí Hébírónì.
4Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ó sì ní ìfẹ́ obìnrin kan ní àfonífojì Ṣórékì, orúkọ ẹni tí í ṣe Dẹ̀lílà.
5Àwọn ìjòyè Fílístínì sì lọ bá obìnrin náà, wọ́n sọ fún un wí pé, “Bí ìwọ bá le tàn án kí òun sì fi àsírí agbára rẹ̀ hàn ọ́, àti bí àwa ó ti lè borí rẹ̀, kí àwa sì dè é kí àwa sì ṣẹ́gun rẹ̀. Ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú wa yóò sì fún ọ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà fàdákà.”
6Torí náà Dẹ̀lílà sọ fún Sámúsónì pé, “Sọ àsírí agbára ńlá rẹ fún mi àti bí wọ́n ti le dè ọ́, àti bí wọ́n ṣe lè borí rẹ.”
7Sámúsónì dá a lóhùn wí pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fi okùn tútù méje tí ẹnìkan kò sá gbẹ dè mí, èmi yóò di aláìlágbára bí i gbogbo àwọn ọkùnrin yóòkù.”
8Àwọn olóyè Fílístínì sì mú okùn tútù méje tí ẹnikẹ́ni kò sá gbẹ wá fún Dẹ̀lílà òun sì fi wọ́n dè é.
9Nígbà tí àwọn ènìyàn tí sá pamọ́ sínú yàrá, òun pè pé, “Sámúsónì àwọn Fílístínì ti dé láti mú ọ.” Ṣùgbọ́n òun já àwọn okùn náà bí òwú ti í já nígbà tí ó bá wà lẹ́bàá iná. Torí náà wọn kò mọ àsírí agbára rẹ̀.
10Dẹ̀lílà sì sọ fún Sámúsónì pé, ìwọ ti tàn mí; o sì purọ́ fún mi. Wá báyìí kí o sì sọ bí a ti ṣe le dè ọ́.
11Òun dáhùn pé, “Bí wọ́n bá lè fi okùn túntún tí ẹnikẹ́ni kò tíì lò rí dì mí dáadáa, èmi yóò di aláìlágbára, èmì yóò sì dàbí àwọn ọkùnrin yóòkù.”
12Dẹ̀lílà sì mú àwọn okùn túntún, ó fi wọ́n dì í. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Fílístínì ti fi ara pamọ́ sínú yàrá, òun kígbe sí i pé, “Sámúsónì àwọn Fílístínì dé láti mú ọ,” òun sì já okùn náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀ bí òwú.
13Dẹ̀lílà sì tún sọ fún Sámúsónì pé, “títí di ìsinsìn yìí ìwọ sì ń tún tàn mí, o sì tún purọ́ fún mi. Sọ fún mi ọ̀nà tí wọ́n fi le dè ọ́,”
14ó sì fi ìhunṣọ dè wọ́n.
15Dẹ̀lílà sì sọ fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi wí pé, èmi fẹ́ràn rẹ, nígbà tí ìwọ kò fi ọkàn tán mi. Èyí ni ìgbà kẹta tí ìwọ ti tàn mí jẹ, tí ìwọ kò sì sọ àsírí ibi tí agbára ńlá rẹ gbé wà fún mi.”
16Ó sì ṣe nígbà tí ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ ọ́ ní ojoojúmọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí dé bi pé ó ṣú u dé òpin ẹ̀mí rẹ̀.
17Òun sì sọ ohun gbogbo tí ó wà ní ọkàn rẹ̀ fún un. Ó ní, “Abẹ kò tí ì kan orí mi rí, nítorí pé Násírì, ẹni ìyàṣọ́tọ̀ fún OLÚWA ni mo jẹ́ láti ìgbà ìbí mi wá. Bí a bá fá irun orí mi, agbára mi yóò fi mí sílẹ̀, èmi yóò sì di aláìlágbára bí àwọn ọkùnrin yóòkù.”
18Nígbà tí Dẹ̀lílà ríi pé ó ti sọ ohun gbogbo fún òun tan, Dẹ̀lílà ránṣẹ́ sí àwọn ìjòyè Fílístínì pé, “Ẹ wá lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ti sọ ohun gbogbo fún mi.” Torí náà àwọn olóyè Fílístínì padà, wọ́n sì mú owó ìpinnu náà lọ́wọ́.
19Òun sì mú kí Sámúsónì sùn lórí itan rẹ̀, òun sì pe ọkùnrin kan láti fá àwọn ìdì irun orí rẹ̀ méjèèje, òun sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun rẹ̀ (dá a lóró). Agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ.
20Òun pè é wí pé, “Sámúsónì àwọn Fílístínì dé láti mú ọ.”
21Nígbà náà ni àwọn Fílístínì mú un, wọ́n yọ ojú rẹ̀ méjèèjì wọ́n sì mú-un lọ sí Gásà. Wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ dè é, wọ́n sì fi sí ibi iṣẹ́ ọlọ lílọ̀ nínú ilé túbú.
22Ṣùgbọ́n irun orí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tún hù lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti fá a.
23Àwọn ìjòyè, àwọn ará Fílístínì sì péjọ pọ̀ láti ṣe ìrúbọ ńlá sí Dágónì ọlọ́run wọn àti láti ṣe ayẹyẹ wọ́n wí pé, ọlọ́run wa ti fi Sámúsónì ọ̀ta wa lé wa lọ́wọ́.
24Nígbà tí àwọn ènìyàn rí Sámúsónì wọ́n yin ọlọ́run wọn wí pé,
25Nígbà tí inú wọn dùn gidigidi tí wọ́n ń yọ ayọ̀ ńlá, wọ́n pariwo pé, ẹ mú Sámúsónì wá kí ó wá dáwa lára yá. Wọ́n sì pe Sámúsónì jáde láti ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, òun sì ń ṣeré fún wọn.
26Sámúsónì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó di ọwọ́ rẹ̀ mú pé, “Ẹ fi mí si ibi tí ọwọ́ mi yóò ti le tó àwọn òpó tí ó gbé tẹ́ḿpìlì dúró mú, kí èmi lè fẹ̀yìn tì wọ́n.”
27Ní àsìkò náà, tẹ́ḿpìlì yìí kún fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin; gbogbo àwọn ìjòyè Fílístínì wà níbẹ̀, ní ókè ilé náà, níbi tí ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) àwọ́n ọkùnrin àti obìnrin tí ń wòran Sámúsónì bí òun ti ń ṣeré.
28Nígbà náà ni Sámúsónì ké pe OLÚWA wí pé, “OLÚWA Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, rántí mi. Háà Ọlọ́run jọ̀wọ́ fi agbára fún mi lẹ́ẹ̀kan yìí sí i, kí èmi lè gbẹ̀san lára àwọn Fílístínì nítorí àwọn ojú mi méjèèjì.”
29Sámúsónì sì na ọwọ́ mú àwọn òpó méjèèjì tí ó wà láàárin gbùngbùn, orí àwọn tí tẹ́ḿpìlì náà dúró lé, ó fi ọwọ́ ọ̀tún mú ọ̀kan àti ọwọ́ òsì mú èkejì, ó fi ara tì wọ́n,
30Sámúsónì sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi kú pẹ̀lú àwọn Fílístínì!” Òun sì fi agbára ńlá tì wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni ilé náà wó lu àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn tí ó wà nínú rẹ̀. Báyìí ni ó pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nígbà ikú rẹ̀ ju ìgbà ayé rẹ̀ lọ.
31Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀ ní àpapọ̀ gòkè lọ wọ́n sì gbé e, wọ́n gbé e padà wá, wọ́n sì sin ín sí agbede-méjì Sórà àti Ésítaólì sínú ibojì Mánóà baba rẹ̀. Òun ti ṣe àkóso Ísírẹ́lì ní ogún (20) ọdún.